Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ẹnì Kejì Rẹ

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ẹnì Kejì Rẹ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Táwọn tọkọtaya bá ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé wọ́n mọyì ara wọn, ó máa jẹ́ kí ìdílé wọn tòrò. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọkọ àti ìyàwó ni kì í rí ibi tí ẹnì kejì wọn dáa sí, ká má ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n fi ìmọrírì hàn sí wọn. Nínú ìwé Emotional Infidelity, agbaninímọ̀ràn kan sọ ohun tó kíyè sí nípa ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó máa ń wá sọdọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ohun tí kì í ṣẹlẹ̀ [nínú ìdílé wọn] ló máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn, wọ́n kì í ronú nípa ohun tó dáa tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Kí nǹkan lè yí pa dà nínú idílé wọn ni wọ́n ṣe máa ń wá, wọn kì í sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan tó ń lọ dáadáa nínú ilé, á ṣe máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Àṣìṣe tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tọkọtaya yìí ń ṣe ni pé, wọn kì í mọ rírì ohun tí ẹnì kejì wọn ń ṣe, èyí ni kò jẹ́ kí ìfẹ́ wà láàárín wọn.”

Báwo ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ṣe lè yẹra fún àṣìṣe yìí?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ilé máa ń tura tí ẹ bá ń fi hàn pé ẹ mọyì ara yín. Tí ọkọ àti ìyàwó bá ń sapá láti kíyè sí àwọn ànímọ́ tó dáa lára ẹnì kejì rẹ̀, tí wọ́n sì ń fi hàn pé wọ́n mọyì ara wọn, àjọṣe wọn máa túbọ̀ dáa sí. Kódà, ilé máa tura tí àwọn méjèèjì bá ń nímọ̀lára pé ẹnì kejì àwọn mọyì àwọn gan-an.

Fún àwọn ìyàwó. Ìwé Emotional Infidelity tá a mẹ́nu kàn lókè sọ pé: “Ọ̀pọ̀ obìnrin máa ń gbójú fo ìdààmú tó lékenkà táwọn ọkọ máa ń kojú kí wọ́n lè pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò.” Kódà, ìdààmú ṣì máa ń wà nínú ìdílé tó jẹ́ pé tọkọtaya ló ń ṣiṣẹ́ tó ń mówó wọlé.

Fún àwọn ọkọ. Àwọn ọkùnrin sábà máa ń fojú kéré iṣẹ́ ribiribi tí ìyàwó wọn ń ṣe láti bójú tó ilé, bí ọmọ títọ́, iṣẹ́ ilé tàbí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Fiona, * tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́ta sọ pé: “Gbogbo wa lá máa ń ṣàṣìṣe, tó bá sì ṣẹlẹ̀ sí mi, ó máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́. Àmọ́ tọ́kọ mi bá kí mi pé mó kú iṣẹ́, bóyá nígbà tí mo ṣe iṣẹ́ ilé, èyí máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ mi láìka àwọn àṣìṣe mi sí. Inú mi sì máa ń dùn pé ọkọ mi mọyì mi!”

Ní ìdàkejì, tí ọkọ tàbí ìyàwó bá ń ní ìmọ̀lára pé ẹnì kejì kò mọyì akitiyan òun, ó lè ṣàkóbá fún àjọgbé wọn. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Valerie sọ pé: “Tí o bá nímọ̀lára pé ẹnì kejì rẹ kò mọyì rẹ, ó lè mú kí ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹlòmíì tó ń fi hàn pé òun mọyì rẹ.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ní àkíyèsí. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, gbìyànjú láti wo àwọn ìwà rere tí ẹnì kejì rẹ ní. Kó o sì kíyè sí àwọn nǹkan tó ń ṣe kí nǹkan lè máa lọ dáadáa nínú ilé, ìyẹn àwọn nǹkan tí o kò kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀. Tí ọ̀sẹ̀ bá ti parí, kó o wá ṣe àkọsílẹ̀ (1) àwọn ìwà rere tó o mọyì lára ẹnì kejì rẹ àti (2) àwọn ohun tó ṣe fún àǹfààní ìdílé yín.Ìlànà Bíbélì: Fílípì 4:8.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o lákìíyèsí? Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Erika sọ pé: “Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó, èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ka ẹnì kejì sí mọ́. Oò ní rí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe, àwọn nǹkan tí kò ṣe ni wàá máa gbájú mọ́.”

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í fojú kéré iṣẹ́ ribiribi tí ẹnì kejì mi ń ṣe?’ Bí àpẹẹrẹ, tí ọkọ rẹ bá ń tún nǹkan ṣe nínú ilé, ǹjẹ́ o máa ń lọ́ra láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ torí o ronú pé ojúṣe rẹ̀ ni láti tún nǹkan tó bà jẹ́ ṣe? Tó o bá jẹ́ ọkọ, ǹjẹ́ o máa ń ronú pé kò pọn dandan pé kó o dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó rẹ fún ipa tó ń kó láti tọ́ àwọn ọmọ yín, torí pé ohun tó yẹ kó ṣe náà ló ń ṣe? Fi ṣe àfojúsùn rẹ láti kíyè sí ohun tí ẹnì kejì rẹ ń ṣe, kó o sì fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún gbogbo ìsapá rẹ̀ láti mú kí nǹkan máa lọ dáadáa nínú ìdílé yín, yálà nǹkan ńlá ni tàbí kékeré.Ìlànà Bíbélì: Róòmù 12:10.

Máa gbóríyìn fúnni ní fàlàlà. Bíbélì ò kàn sọ pé máa dúpẹ́, kàkà bẹ́è ó sọ pé: “Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Torí náà, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kejì rẹ. Ọkọ kan tó ń jẹ́ James sọ pé: “Tí ìyàwó mi bá fi ìmoore hàn fún àwọn nǹkan tí mò ń ṣe, ó máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ sapá láti ṣe ojúṣe mi bí ọkọ rere, kí n sì túbọ̀ mú kí ìdílé wa wà níṣọ̀kan.”Ìlànà Bíbélì: Kólósè 4:6.

Tí tọkọtaya bá ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí ara wọn, ó máa jẹ́ kí àjọṣe wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Ó dá mi lójú pé tí tọkọtaya bá gbájú mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ràn nípa ẹnì kejì wọn, ìdílé tí yóò máa túká kò ní pọ̀. Tí ìṣòro bá sì dé, kò ní wá sí wọn lọ́kàn pé kí wọ́n fòpin sí àjọṣe wọn, torí pé wọ́n á máa rántí ìwà rere tí ẹnì kejì wọn ní, wọn ò sí ní fẹ́ pàdánù rẹ̀.”

^ ìpínrọ̀ 9 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.