1 Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?
Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run torí wọ́n gbà gbọ́ pé òun ló ń fìyà jẹ wá.
Ronú Lórí Èyí
Lọ́nà kan tàbí òmíì, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń sọ pé:
-
Àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lójijì jẹ́ ìyà tí Ọlọ́run fi ń jẹ wá.
-
Àwọn ọmọdé ń kú nítorí Ọlọ́run nílò àwọn áńgẹ́lì sí i lọ́run.
-
Ọlọ́run ń gbè sẹ́yìn àwọn kan nínú ogun, èyí sì ń fa ìyà tó pọ̀.
Àmọ́, ṣé kì í ṣe irọ́ ni ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń sọ nípa Ọlọ́run? Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run ti kẹ̀yìn sí wọn?
TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I
Wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá.
Tó bá jẹ́ òun ló ń fà á, ìyẹn ta ko àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí Bíbélì sọ. Bí àpẹẹrẹ:
“[Ọlọ́run] ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. . . . Olódodo àti adúróṣinṣin ni.”—DIUTARÓNÓMÌ 32:4.
“Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!”—JÓÒBÙ 34:10.
‘Olódùmarè kì í yí ìdájọ́ po.’—JÓÒBÙ 34:12.
Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀sìn tó ń parọ́ mọ́ ọn.
Lára irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń kọ́ni pé Ọlọ́run ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá àtàwọn ẹ̀sìn tó ń lọ́wọ́ nínú ogun àti ìwà ipá.
“Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi. Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké àti . . . ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.”—JEREMÁYÀ 14:14.
Jésù dẹ́bi fáwọn ẹ̀sìn tó ń ṣẹ̀tàn.
“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run nìkan ló máa wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀ máa sọ fún mi ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Olúwa, Olúwa, ṣebí a fi orúkọ rẹ sọ tẹ́lẹ̀, a fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì fi orúkọ rẹ ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára?’ Àmọ́, màá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin arúfin!’” —MÁTÍÙ 7:21-23.