Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Láti Ìgbà Èwa Wa ni A ti Rántí Ẹlẹ̀dàá Wa

Láti Ìgbà Èwa Wa ni A ti Rántí Ẹlẹ̀dàá Wa

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Láti Ìgbà Èwa Wa ni A ti Rántí Ẹlẹ̀dàá Wa

GẸ́GẸ́ BÍ DAVID Z. HIBSHMAN ṢE SỌ Ọ́

“Bó bá jẹ́ pé òpin ìwàláàyè mi rèé, tóò, ó dá mi lójú pé, mo ti ṣe olóòótọ́ sí Jèhófà. Mo bẹ̀ ẹ́ pé kó jọ̀wọ́ máa bá mi tọ́jú David mi ọ̀wọ́n. Jèhófà, mo mà dúpẹ́ tóo fún mi ní David o. Mo tún dúpẹ́ fún àjọgbé wa bíi tọkọtaya. Àjọgbé wa ọ̀hún dùn púpọ̀, ó lárinrin!”

ÌWỌ náà ro bó ṣe máa rí lára mi lẹ́yìn tí mo sìnkú aya mi tán ní March 1992, tí mo wá rí ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí nínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀. Oṣù márùn-ún péré sẹ́yìn la ṣayẹyẹ ọgọ́ta ọdún tí Helen bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Mo ṣì rántí ọjọ́ náà dáadáa ní 1931 nígbà tí èmi àti Helen jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wa ní àpéjọpọ̀ Columbus, Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lóòótọ́ Helen ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá nígbà yẹn, àmọ́ ó mọrírì ohun tó ń lọ lọ́wọ́ ju èmi pàápàá lọ. Ìtara tí Helen ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ fara hàn kété lẹ́yìn náà, nígbà tí òun àti màmá rẹ̀ tó jẹ́ opó di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń pe àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún. Wọ́n fi ilé wọn tó ní gbogbo ohun amáyédẹrùn sílẹ̀, wọ́n lọ wàásù ní ìgbèríko tó wà ní gúúsù Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Ogún Kristẹni Tí Mo Jẹ

Ọdún 1910 làwọn òbí mi pẹ̀lú ọmọ wọn méjì kéékèèké ṣí kúrò ní ìlà oòrùn Pennsylvania, tí wọ́n lọ sí Grove City, ní ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ náà. Wọ́n san àsansílẹ̀ fún ilé kékeré kan, wọ́n sì di ògbóṣáṣá mẹ́ńbà Ìjọ Alátùn-únṣe. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni William Evans, ọ̀kan lára àwọn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, bẹ̀ wọ́n wò. Baba mi, tó ṣì wà ní nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n péré nígbà yẹn àti màmá mi tó jẹ́ ẹni ogún ọdún, tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ọkùnrin ará Wales, tó yá mọ́ni yìí, wọ́n sì pè é kó wá bá wọn jẹun nílé. Kò pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n fi tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́.

Ká má bàá jìnnà sí ìjọ, baba mi kó ìdílé wa lọ sí ibi tó tó nǹkan bí ogójì kìlómítà sí ìlú kan tó ń jẹ́ Sharon. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, lọ́dún 1911 tàbí 1912, Baba àti Màmá ṣèrìbọmi. Charles Taze Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society ló sọ àsọyé ìrìbọmi náà. A bí mi ní December 4, 1916, lẹ́yìn tí àwọn òbí mi ti ní ọmọ mẹ́rin. Nígbà tí wọ́n bí mi, wọ́n kéde pé: “Ẹni-a-fẹ́ mìíràn ti dé o.” Ibi tí orúkọ mi ti jáde nìyẹn, ìyẹn ni David, tó túmọ̀ sí “Olùfẹ́.”

Ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́rin ni mí, nígbà tí wọ́n gbé mi lọ sí àpéjọpọ̀ tí màá kọ́kọ́ lọ láyé mi. Láyé ọjọ́ yẹn, ẹsẹ̀ ni baba mi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin fi ń rìn lọ sípàdé ìjọ, àmọ́ Màmá á mú èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ́wọ́ wọkọ̀. Àárọ̀ àti ọ̀sán la máa ń ṣe ìpàdé. Táa bá délé, ìjíròrò wa sábà máa ń dá lórí àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ àti The Golden Age, orúkọ tí à ń pe ìwé ìròyìn Jí! tẹ́lẹ̀.

Jíjàǹfààní Látinú Àwọn Àpẹẹrẹ Rere

Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn àjò síbi ìjọsìn ló ń bẹ ìjọ wa wò, orúkọ yìí là ń pe àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tí ń rìnrìn àjò kiri tẹ́lẹ̀. Wọ́n sábà máa ń lo ọjọ́ kan tàbí méjì pẹ̀lú wa. Olùbánisọ̀rọ̀ kan tí mi ò lè tètè gbàgbé ni Walter J. Thorn, ẹni tó ti rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ tí [ó] wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníwàásù 12:1) Nígbà ti mo wà lọ́mọdé, mo máa ń bá baba mi lọ síbi tó bá ti fẹ́ fi sinimá “Photo-Drama of Creation” han àwọn èèyàn, sinimá alápá mẹ́rin tó tún ní ìtàn ìran ènìyàn nínú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Evans àti Miriam, aya rẹ̀, kò bímọ, wọ́n di òbí nípa tẹ̀mí àti òbí àgbà nípa tẹ̀mí fún ìdílé wa. “Ọmọ mi” ni William sábà máa ń pe Baba, òun àti Miriam sì gbin ẹ̀mí ajíhìnrere sínú ìdílé wa. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, Arákùnrin Evans padà sí Wales láti lọ sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn tó wà lágbègbè Swansea. Ibẹ̀ ni wọ́n ti wá mọ̀ ọ́n sí oníwàásù tó wá láti Amẹ́ríkà.

Lọ́dún 1928, Arákùnrin Evans fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní àwọn òkè Ìwọ̀ Oòrùn Virginia. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjèèjì, Clarence ọmọ ọdún mọ́kànlélógún àti Carl ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún bá a lọ. Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin táa jẹ́ ọkùnrin la lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Kódà, gbogbo wa la sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn àjò nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà táa wà lọ́dọ̀ọ́. Láìpẹ́ yìí, àbúrò màmá mi tó jẹ́ obìnrin, ìyẹn Mary, ẹni tó ti lé ní àádọ́rùn-ún ọdún báyìí, kọ̀wé sí mi, ó ní: “Gbogbo wa la dúpẹ́ pé Arákùnrin Evans ní ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí ó sì wá ṣèbẹ̀wò sí Grove City!” Àǹtí Mary pẹ̀lú jẹ́ ẹnì kan tó rántí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.

Lílọ sí Àpéjọpọ̀

Baba àti Clarence nìkan ló lè lọ sí àpéjọpọ̀ mánigbàgbé tó wáyé ní Cedar Point, Ohio, ní 1922. Ṣùgbọ́n nígbà tó fi máa di 1924, a ti ní mọ́tò kan, èyí ni gbogbo ìdílé wa wọ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ ní Columbus, Ohio. Owó tí àwa ọmọ tọ́jú la fi jẹun ní àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́jọ náà. Ohun tó jẹ́ èrò àwọn òbí mi lórí ọ̀ràn náà ni pé gbogbo mẹ́ńbà ìdílé ló gbọ́dọ̀ kọ́ bí yóò ṣe gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ìdí nìyẹn táa fi ń sin adìyẹ àti ehoro, táa sì tún ní ilé oyin, àwa táa jẹ́ ọmọkùnrin sì ní àwọn tí a ń ta ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ fún.

Nígbà tí àpéjọpọ̀ táa ṣe ní Toronto, Kánádà, lọ́dún 1927 dé, a ti ní àbúrò kékeré kan, ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́fà, Paul lorúkọ rẹ̀. Wọ́n ní kí n dúró sílé kí n máa tọ́jú Paul, kí àǹtí mi kan tó wà nílé ọkọ sì ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n àwọn òbí mi àti àwọn ọmọ yòókù lọ sí Toronto. Dọ́là mẹ́wàá ni wọ́n fún mi nítorí pé n kò láǹfààní àtilọ, mo sì fi owó yìí ra kóòtù tuntun. Wọ́n ti kọ́ wa pé ká máa múra dáadáa táa bá ń lọ sí ìpàdé, kí ẹ̀wù wa sì bójú mú.

Nígbà tó fi máa di ìgbà àpéjọpọ̀ mánigbàgbé tó wáyé ní 1931 ní Columbus, Ohio, Clarence àti Carl ti ṣègbéyàwó, àwọn àti ìyàwó wọn sì ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ilé alágbèérìn ni wọ́n ń gbé. Carl fẹ́ Claire Houston, ti Wheeling, ní West Virginia, ìdí nìyẹn tí mo fi jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ àbúrò Claire, ìyẹn Helen, nígbà àpéjọpọ̀ Columbus.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Mo jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga ní 1932, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo sì lọ gbé ọkọ̀ àlòkù kan fún ẹ̀gbọ́n mi, Clarence, ẹni tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Gúúsù Carolina. Mo fọwọ́ síwèé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Clarence àti aya rẹ̀ jáde. Nígbà yẹn, Helen ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Hopkinsville, Kentucky, àkókò yẹn ni mo wá kọ lẹ́tà sí i fún ìgbà àkọ́kọ́. Nínú èsì rẹ̀, ó béèrè pé: “Ṣé aṣáájú ọ̀nà ni ẹ́?”

Nínú lẹ́tà mi—èyí tí Helen tọ́jú títí tó fi kú ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn náà—mo fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo sì nírètí pé n kò ní fiṣẹ́ náà sílẹ̀.” Nínú lẹ́tà yẹn, mo sọ fún Helen nípa bí mo ṣe pín ìwé kékeré náà, The Kingdom, the Hope of the World fún àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù mi.

Lọ́dún 1933, Baba ṣe àgọ́ onítáyà fún mi—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó mítà méjì ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mítà méjì, ó ní ilé táa fi aṣọ bo inú rẹ̀ látòkèdélẹ̀, ó sì ní fèrèsé níwájú àti lẹ́yìn. Inú ilé kóńkó yìí ni mo gbé fún odindi ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e tí mo fi ṣe aṣáájú ọ̀nà.

Nígbà tó di March 1934, Clarence àti Carl, aya wọn, Helen àti màmá rẹ̀, àna Clarence àti èmi náà—àwa mẹ́jọ—forí lé ìwọ̀ oòrùn láti lọ sí àpéjọpọ̀ Los Angeles, California. Àwọn kan wọnú ọkọ̀ àfiṣelé mi, wọ́n sì sùn síbẹ̀. Èmi lọ sùn sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn yòókù sì lọ sùn sílé tí wọ́n háyà. Torí pé ọkọ̀ wa yọnu, ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́fà náà la tó dé Los Angeles. Nígbà táa débẹ̀, ní March 26, ó ṣeé ṣe fún èmi àti Helen láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa hàn sí Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi.

Ní àpéjọpọ̀ náà, Joseph F. Rutherford, ẹni tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aṣáájú ọ̀nà. Ó fún wa níṣìírí, ó ní, àwa ni akíkanjú tí ń jà fún òtítọ́ Bíbélì. Inú ìpàdé yìí ni wọ́n ti fi tó wa létí pé wọn yóò máa fi owó ran àwọn aṣáájú ọ̀nà lọ́wọ́, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ.

Ẹ̀kọ́ Tó Wúlò Jálẹ̀ Gbogbo Ìgbésí Ayé

Nígbà táa ti àpéjọpọ̀ Los Angeles dé, gbogbo wa la sọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà fún àwọn ènìyàn tó wà ní gbogbo ìgbèríko Gúúsù Carolina, Virginia, Ìwọ̀ Oòrùn Virginia, àti Kentucky. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Helen kọ̀wé nípa àkókò yẹn pé: “Kò sí ìjọ táa ti lè máa fara roni, kò sí àwọn ọ̀rẹ́ tó lè ranni lọ́wọ́, nítorí àjèjì pátápátá la jẹ́ ní ilẹ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n mo wá mọ̀ báyìí pé ẹ̀kọ́ ni mò ń gbà nígbà yẹn. Mò ń di ọlọ́rọ̀.”

Ó béèrè pé: “Kí ló yẹ kí ọ̀dọ́mọbìnrin kan fi àkókò rẹ̀ ṣe nígbà tí kò bá sí lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí kò sì sí nítòsí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀? Tóò, kò burú jù. N kò tiẹ̀ lè rántí pé ó sú mi rí. Mo ǹ kàwé gan-an. A kò sì dẹ́kun kíka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn. N kì í fi màmá mi sílẹ̀, mo máa ń kọ́ báa ṣe lè fọgbọ́n lo owó táa ní, báa ṣe lè rajà, báa ṣe lè pààrọ̀ táyà, báa ṣe ń se oúnjẹ, báa ṣe ń ránṣọ, àti báa ṣe ń wàásù. N kò kábàámọ̀ rárá, tayọ̀tayọ̀ ni màá sì máa fi ṣe bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ó tẹ́ Helen àti màmá rẹ̀ lọ́rùn láti gbé nínú ilé kótópó alágbèérìn fún gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé màmá rẹ̀ nílé tó dáa. Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ ti Columbus, ní Ohio, ní 1937, ìlera màmá Helen kò dáa mọ́ rárá, wọ́n sì gbà á sílé ìwòsàn. Ó kú lẹ́nu iṣẹ́ tí a yàn án sí ní Philippi, Ìwọ̀ Oòrùn Virginia, ní November 1937.

Ìgbéyàwó àti Iṣẹ́ Ìsìn Tí Ń Bá A Nìṣó

Ní June 10, 1938, èmi àti Helen ṣègbéyàwó tí ayẹyẹ rẹ̀ kò lariwo lọ nínú ilé táa bí i sí ní Elm Grove, nítòsí Wheeling, ní Ìwọ̀ Oòrùn Virginia. Arákùnrin wa ọ̀wọ́n, Evans, tó fojú ìdílé mi mọ òtítọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kí wọ́n tó bí mi, ló sọ àsọyé ìgbéyàwó náà. Lẹ́yìn ìgbéyàwó náà, èmi àti Helen ṣètò láti padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ìlà oòrùn Kentucky, àmọ́ ó yà wá lẹ́nu gan-an pé wọ́n pè wá láti wá máa ṣe ìbẹ̀wò ẹlẹ́kùnjẹkùn. Iṣẹ́ yìí wé mọ́ bíbẹ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Kentucky àti àwọn apá Tennessee wò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Nígbà yẹn, ènìyàn márùndínlọ́gọ́rin péré ló jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba ní gbogbo ibi táa bẹ̀ wò.

Ní àkókò yẹn, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti kó sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí débi pé, wọ́n fẹ́ sọ mí sẹ́wọ̀n nítorí pé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, n kò dá sí tọ̀tún-tòsì. (Aísáyà 2:4) Ṣùgbọ́n, ọpẹ́lọpẹ́ àkọsílẹ̀ tí mo ti ní nínú iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn ló mú kí àjọ tí ń fọwọ́ sí àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ ológun sọ pé kí n lọ máa ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Nígbà táa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn àjò, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ènìyàn ló ń sọ̀rọ̀ nípa báa ṣe kéré tó. Ní Hopkinsville, Kentucky, Kristẹni arábìnrin kan gbá Helen mọ́ra, ó kí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ó wá béèrè pé: “Ṣóo mọ̀ mí?” Ní 1933, Helen jẹ́rìí fún un nínú ilé ìtajà ọkọ rẹ̀ ní àrọko kan. Olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi lobìnrin yìí, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ka ìwé tí Helen fi sílẹ̀ fún un, ó dìde dúró níwájú kíláàsì rẹ̀, ó sì tọrọ àforíjì fún kíkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu. Lẹ́yìn tó ti kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì, ó bẹ̀rẹ̀ sí polongo òtítọ́ Bíbélì lágbègbè rẹ̀. Ní odindi ọdún mẹ́ta tí èmi àti Helen fi sìn ní ìwọ̀ oòrùn Kentucky, ilé arábìnrin yẹn àti ọkọ rẹ̀ la sábà máa ń dé sí.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a máa ń ṣe àpéjọ kéékèèké, A. H. Macmillan sì ti wá darí irú ẹ̀ kan rí. Ó ti dé sílé àwọn òbí Helen rí nígbà tí Helen ṣì wà lọ́mọdé, nítorí náà ní àkókò àpéjọpọ̀ yìí, ó yàn láti wà pẹ̀lú wa nínú ilé alágbèérìn wa tí kò gùn ju mítà márùn-ún lọ, a kúkú ní ibùsùn mìíràn níbẹ̀ fún àlejò. Òun pẹ̀lú ti rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ nígbà tó ti wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà lọ́dún 1900, nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún.

Ní November 1941, wọ́n dá iṣẹ́ àwọn arákùnrin arìnrìn àjò dúró fúngbà díẹ̀, wọ́n sì rán mi lọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní Hazard, Kentucky. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a bá arákùnrin mi Carl àti aya rẹ̀, Claire, ṣiṣẹ́. Ibi ni Joseph Houston ti wá bá wa, ìyẹn ọmọ ẹ̀gbọ́n Helen, ó dara pọ̀ mọ́ wa, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ó ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lọ fún nǹkan bí àádọ́ta ọdún, kó tó di pé àrùn ọkàn pa á lójijì ní 1922 nígbà tó ń fi òtítọ́ ọkàn sìn ní oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York.

Ní 1943, a rán wa lọ sí Rockville, Connecticut. Ayé mìíràn pátápátá ni ibí yìí jẹ́ fún èmi àti Helen nítorí pé wíwàásù ní ìhà gúúsù ti mọ́ wa lára. Ní Rockville, Helen ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lé ni ogún déédéé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a gba yàrá kan tí a ó máa lò gẹ́gẹ́ bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba, a sì ṣètò ìbẹ̀rẹ̀ ìjọ kékeré kan.

Nígbà tí à ń sìn ní Rockville, a pè wá láti wá sí kíláàsì karùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead ní Gúúsù Lansing, New York. Inú wa dùn pé, Aubrey àti Bertha Bivens, àwọn ọ̀rẹ́ wa nígbà tí à ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Kentucky, yóò tún wà lára àwọn tí a ó jọ wà ní kíláàsì.

A Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́, A sì Gba Iṣẹ́ Tuntun

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ṣì ni wá, àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ kíláàsì wa ni kò tó wa lọ́jọ́ orí. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wọn ní ìgbà ọ̀dọ́ wọn. July 1945 la kẹ́kọ̀ọ́ yege, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń kógbá sílé. Nígbà tí à ń retí ibi tí a óò rán wa lọ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, a ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìjọ Flatbush tó wà ní Brooklyn, New York. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní October 21, 1946, àwa àti àwọn mẹ́fà mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọmọ kíláàsì wa, títí kan àwọn Bivens, wọkọ̀ òfuurufú lọ sí ibùgbé wa tuntun ní Guatemala City, ní ilẹ̀ Guatemala. Nígbà yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní Àárín Gbùngbùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà yìí kò tó àádọ́ta.

Nígbà tó di April 1949, díẹ̀ lára àwa táa jẹ́ míṣọ́nnárì ṣí lọ sí Quetzaltenango, ìlú tó tóbi ṣìkejì, tó sì tún lórúkọ ṣìkejì ní orílẹ̀-èdè náà. Ó tó nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún lé ní ẹgbàá mítà tí ibi tí ìlú yìí wà fi ga ju ìtẹ́jú òkun lọ, ńṣe ni orí òkè náà tutù nini. Bí Helen ṣe ṣàkópọ̀ ìgbòkègbodò wà níhìn-ín nìyí, ó kọ̀wé pé: “Àǹfààní ńlá la ní láti wàásù ní ọ̀pọ̀ ìlú àti ìletò. Nǹkan bí aago mẹ́rin ìdájí la ti máa ń jí, tí a ó sì wọ bọ́ọ̀sì lọ sí ìlú tó bá jìnnà (aṣọ títa ló máa ń wà lójú fèrèsé bọ́ọ̀sì náà. Ibẹ̀ la ó ti wàásù fún nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ ká tó padà sílé nírọ̀lẹ́.” Lónìí, ìjọ wà ní ọ̀pọ̀ ibi wọ̀nyí, títí kan mẹ́fà tó wà ní Quetzaltenango.

Kò pẹ́ púpọ̀ ni ìpè jáde pé kí àwọn míṣọ́nnárì wá sìn ní Puerto Barrios ní Etíkun Caribbean, ìlú tó tóbi ṣèkẹta ní Guatemala. Àwọn ọ̀rẹ́ wa olùfẹ́, ìyẹn tọkọtaya Bivense, táa ti jọ sìn fún ọdún márùn-ún ní Guatemala, wà lára àwọn tó lọ sí àgbègbè tuntun yìí. Nígbà tí wọ́n fẹ́ máa lọ, ó ká wa lára púpọ̀, ó sì gbò wá gidigidi. Nígbà tó jẹ́ pé èmi àti Helen nìkan ló kù nínú ilé míṣọ́nnárì, la bá kúkú kó lọ sílé kékeré kan. Ní 1955, èmi àti Helen gbà láti lọ sìn níbòmíràn, ìyẹn ní ìlú kan tó wà nílẹ̀ olóoru, ní Mazatenango. Àbúrò mi tó kéré jù lọ, Paul àti ìyàwó rẹ̀, Dolores, tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead lọ́dún 1953, ti sìn níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí a tó débẹ̀.

Nígbà tó fi máa di ọdún 1958, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin Ẹlẹ́rìí ló ti wà níbẹ̀, a ti ní ìjọ ogún, àti àyíká mẹ́ta ní Guatemala. Èmi àti Helen jọ ṣiṣẹ́ arìnrìn àjò, à ń bẹ àwọn àwùjọ kéékèèké ti àwọn Ẹlẹ́rìí wò àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìjọ wọn, títí kan ọ̀kan tó wà ní Quetzaltenango. Lẹ́yìn náà, ní August 1959, a ké sí wa láti padà wá sí Guatemala City, níbi táa ti wáá gbé nínú ẹ̀ka ọ́fíìsì. Wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka náà, nígbà tí Helen ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ fún ọdún mẹ́rìndínlógún tó tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.

Òjò Ìbùkún Mìíràn Tó Rọ̀

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó jọ pé èmi ló kéré jù lọ lára àwọn tí ń sin Jèhófà. Àmọ́ lójú tó mọ́ lónìí, mo wà lára àwọn tó dàgbà jù lọ, gẹ́gẹ́ bó ti rí nígbà tí mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ní Patterson, New York, ní 1996. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbàlagbà ti ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ lèmi náà ṣe ní àǹfààní lẹ́nu àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí láti rán ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ láti rántí Ẹlẹ́dàá wọn nígbà èwe wọn lọ́wọ́.

Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ níhìn-ín ní Guatemala. Lọ́dún 1999, iye ìjọ tó wà ní Guatemala City ti lé ní ọgọ́ta. Ní àríwá, gúúsù, ìlà oòrùn, àti ìwọ̀ oòrùn, ìjọ pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ló sì ń pòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn àádọ́ta ènìyàn tó ń pòkìkí Ìjọba náà nígbà táa débí ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta sẹ́yìn mà ti lé ní ọ̀kẹ́ kan dín ní ẹgbẹ̀rún báyìí o!

Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ló Yẹ Ká Ṣọpẹ́ Fún

Èèyàn ò lè gbọ́n láyé kí tiẹ̀ má bá a, àmọ́ ṣá o, gbogbo ìgbà ni a lè máa ju “ẹrù ìnira [wa] sọ́dọ̀ Jèhófà.” (Sáàmù 55:22) Ìgbà gbogbo ló ń mú wa dúró nípa ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ wa, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún díẹ̀ kí Helen tó kú, ó fún mi ní ẹ̀bùn kan tó kọ àkọlé sí, ọ̀rọ̀ náà wá láti inú ẹsẹ Bíbélì yìí, Hébérù 6:10: “Ọlọ́run kì í ṣe alábòsí, tí yóò fi wá gbàgbé làálàá rẹ àti ìfẹ́ tí o ti fi hàn sí Òun alára, ní ti pé ò ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, tí o sì ń bá a nìṣó láti máa ṣe é.”—Weymouth.

Ọ̀rọ̀ tó kọ sísàlẹ̀ rẹ̀ kà pé: “Onítèmi ọ̀wọ́n, ohun tí mo ní tí mo lè fún ẹ kò tó nǹkan, òun ni mo ṣe kúkú fún ẹ ní GBOGBO ÌFẸ́ MI . . . Ẹsẹ Bíbélì yìí mà bá ẹ mu o, jọ̀wọ́ gbé ẹ̀bùn yìí sórí tábìlì rẹ, kì í ṣe torí pé èmi ló fún ẹ o, àmọ́ torí pé ó ti bá ẹ mu jù nítorí ọ̀pọ̀ ọdún tóo ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn.” Títí dòní olónìí, ẹ̀bùn yẹn wà lórí tábìlì ọ́fíìsì mi ní ẹ̀ka Guatemala.

Láti ìgbà èwe mi wá ni mo ti ń sin Jèhófà, nísinsìnyí tí mo si ti dàgbà, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìlera tó jí pépé tó fún mi láǹfààní láti máa bá iṣẹ́ táa yàn fún mi lọ. Bí mo ti ń bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà mi lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó dá mi lójú pé Helen mi ọ̀wọ́n ì bá fàlà sí nínú Bíbélì rẹ̀. Èyí sọ sí mi lọ́kàn nígbà tí mo tún Sáàmù 48:14 kà, tó sọ pé: “Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa títí a ó fi kú.”

Ó máa ń dùn mọ́ mi púpọ̀ láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn bí ọjọ́ àjíǹde yóò ti rí, nígbà tí àwọn ènìyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tó ti wà tẹ́lẹ̀ rí yóò máa kí àwọn olólùfẹ́ wọn káàbọ̀ láti inú ipò òkú sínú ayé tuntun. Ìrètí yìí mà ga o! Áà, omijé ayọ̀ yóò ṣàn lójú wá lọ́jọ́ náà, nígbà táa bá rántí pé, lóòótọ́, Jèhófà ni Ọlọ́run “tí ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú”!—2 Kọ́ríńtì 7:6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Láti ọwọ́ òsì sí ọ̀tún: Màmá, Dádì, Àǹtí Eva, àti Arákùnrin Carl àti Clarence, 1910

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Helen ní 1947 àti ní 1992