Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù!

Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù!

Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù!

“Kristi . . . fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 PÉT. 2:21.

1. (a) Ipa wo ni Ọmọ Ọlọ́run kó nínú dídá àwọn nǹkan? (b) Báwo lọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣe rí lára Jésù?

 NÍGBÀ tí Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé, àkọ́bí rẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ “gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.” Ọmọ náà tún fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Baba rẹ̀ nígbà tí Jèhófà dá onírúurú ẹranko àtàwọn irúgbìn tó sì ṣètò Párádísè tó máa di ibùgbé àwọn ẹ̀dá tó dá láwòrán ara rẹ̀ àti ní ìrí rẹ̀. Ọmọ Ọlọ́run, tá a wá mọ̀ sí Jésù nígbà tó yá, nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. ‘Àwọn ohun tó ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.’—Òwe 8:27-31; Jẹ́n. 1:26, 27.

2. (a) Kí ni Jèhófà pèsè láti ran àwa èèyàn aláìpé lọ́wọ́? (b) Apá wo nínú ìgbésí ayé ni Bíbélì ti pèsè ìtọ́sọ́nà?

2 Lẹ́yìn tí tọkọtaya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ ti dẹ́sẹ̀, bí aráyé ẹlẹ́sẹ̀ ṣe máa rí ìdáǹdè wá di nǹkan pàtàkì lára àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ ṣe. Èyí ló mú kí Jèhófà yọ̀ǹda pé kí Kristi kú ikú ìrúbọ láti mú kí ìdáǹdè yẹn ṣeé ṣe. (Róòmù 5:8) Jèhófà tún fún wa ní Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí tó ń tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá. (Sm. 119:105) Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe láti mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan kó sì láyọ̀. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa ìgbéyàwó pé, ọkùnrin gbọ́dọ̀ “fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”—Jẹ́n. 2:24.

3. (a) Kí ni Jésù kọ́ni nípa ìgbéyàwó? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó tẹnu mọ́ ọn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ìgbéyàwó wà títí gbére. Ó kọ́ni láwọn ìlànà tó jẹ́ pé tá a bá tẹ̀ lé e, á ran àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́wọ́ láti ṣọ́ra fún àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbéyàwó tú ká tàbí èyí tó lè mú kó máà sí ayọ̀ nínú ìdílé. (Mát. 5:27-37; 7:12) Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò báwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti àpẹẹrẹ rẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe lè ran àwọn ọkọ, aya, òbí àtàwọn ọmọ lọ́wọ́ láti láyọ̀, kí ọkàn wọn sì balẹ̀.

Bí Kristẹni Ọkọ Ṣe Lè Bọlá fún Aya Rẹ̀

4. Ọ̀nà wo ni ipò Jésù àti táwọn Kristẹni ọkọ gbà jọra?

4 Ọlọ́run ló yan ọkọ láti jẹ́ olórí ìdílé, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe jẹ́ Orí Ìjọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ, bí òun ti jẹ́ olùgbàlà ara yìí. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:23, 25) Ká sòótọ́, bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ káwọn Kristẹni ọkọ máa tẹ̀ lé nínú bí wọ́n ṣe ń bá àwọn aya wọn lò. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà bíi mélòó kan tí Jésù gbà lo ọlá àṣẹ́ tí Ọlọ́run fún un.

5. Báwo ni Jésù ṣe lo ọlá àṣẹ rẹ̀ lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

5 “Onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni” Jésù. (Mát. 11:29) Kì í sì í fi nǹkan falẹ̀. Kò ṣẹlẹ̀ rí pé kí Jésù fi ohun tó yẹ kó ṣe sílẹ̀ láìṣe. (Máàkù 6:34; Jòh. 2:14-17) Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ló máa ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nímọ̀ràn, kódà ó máa ń sọ ọ́ lásọtúnsọ tó bá pọn dandan. (Mát. 20:21-28; Máàkù 9:33-37; Lúùkù 22:24-27) Síbẹ̀, Jésù kì í wọ́ wọn nílẹ̀ tàbí kó fàbùkù kàn wọ́n, kì í sì í ṣohun tó máa mú kí wọ́n máa rò pé òun ò fẹ́ràn wọn tàbí pé wọn ò tóótun láti ṣe ohun tó ní kí wọ́n ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń yìn wọ́n, ó sì máa ń fún wọn níṣìírí. (Lúùkù 10:17-21) Abájọ táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi bọ̀wọ̀ fún un, torí pé ó fẹ́ràn wọn, ó sì máa ń fi ìyọ́nú bá wọn lò!

6. (a) Kí làwọn ọkọ lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò? (b) Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Pétérù sọ fáwọn ọkọ?

6 Ẹ̀kọ́ tí àpẹẹrẹ Jésù kọ́ àwọn ọkọ ni pé, ipò orí Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ lọ́nà lílekoko. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí wọ́n lò pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn ọkọ níyànjú láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n máa fìfẹ́ bá àwọn aya wọn “gbé lọ́nà kan náà, . . . kí [wọ́n sì] máa fi ọlá fún wọn.” (Ka 1 Pétérù 3:7.) Báwo wá ni ọkọ kan ṣe lè lo ọlá àṣẹ rẹ̀, lẹ́sẹ̀ kan náà, kó tún máa fi ọlá fún aya ẹ̀?

7. Ọ̀nà wo ni ọkọ kan lè gbà bọlá fún aya ẹ̀? Ṣàlàyé.

7 Ọ̀nà kan tí ọkọ kan lè gbà bọlá fún aya ẹ̀ ni pé kó máa fara balẹ̀ ronú lórí èrò aya ẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ kó tó ṣàwọn ìpinnu tó kan ìdílé. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ ṣèpinnu lórí bí wọ́n ṣe máa kó lọ síbòmíì tàbí bí wọ́n ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ míì, ó sì lè jẹ́ nípa ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ lo àkókò ìsinmi tàbí bí wọ́n ṣe máa dín owó tí ìdílé ń ná kù, nígbà tí ìṣòro owó bá yọjú. Torí pé ọ̀rọ̀ tó kan gbogbo ìdílé ni, ó máa dáa, ó sì máa ṣàǹfààní tí ọkọ bá ń ronú lórí èrò aya ẹ̀, torí pé ó lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu tí kò sì ní pa ìdílé lára, ó sì máa rọrùn fún aya ẹ̀ láti kọ́wọ́ tì í. (Òwe 15:22) Báwọn Kristẹni ọkọ bá ń bọlá fáwọn aya wọn, àwọn aya wọn á fẹ́ràn wọn, wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́, ohun tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé, inú Jèhófà á máa dùn sí wọn.—Éfé. 5:28, 29.

Bí Aya Ṣe Lè Bọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀ fún Ọkọ Rẹ̀

8. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn aya tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Éfà?

8 Tó bá dọ̀rọ̀ títẹríba fún ọlá àṣẹ, àpẹẹrẹ pípé ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn Kristẹni aya. Ẹ ò rí i pé èrò tí Jésù ní nípa ọlá àṣẹ yàtọ̀ pátápátá sí ti aya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́! Àpẹẹrẹ búburú ni Éfà jẹ́ fáwọn aya. Ó ní olórí kan tí Jèhófà ń tipasẹ̀ rẹ̀ pèsè ìtọ́ni fún un. Àmọ́, Éfà ò bọ̀wọ̀ fún ipò orí ọkọ ẹ̀ rárá. Kò tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ádámù fún un. (Jẹ́n. 2:16, 17; 3:3; 1 Kọ́r. 11:3) Òótọ́ ni pé ńṣe ni Èṣù tan Éfà, àmọ́ ńṣe ló yẹ kó kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ bóyá kóun gba ohun tí Èṣù sọ fún un nípa ohun tí “Ọlọ́run mọ̀” yẹn gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó hùwà ọ̀yájú nípa dídarí ọkọ ẹ̀.—Jẹ́n. 3: 5, 6; 1 Tím. 2:14.

9. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa ìtẹríba?

9 Àmọ́ ti Jésù yàtọ̀, àpẹẹrẹ pípé ló fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ títẹríba fún ẹni tó jẹ́ Orí rẹ̀. Ìwà àti ìgbé ayé ẹ̀ fi hàn pé “kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀.” (Fílí. 2:5-7) Ní báyìí tí Jésù ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó ṣì ń tẹrí ba fún Orí rẹ̀. Pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló fi ń tẹrí ba fún Bàbá rẹ̀ nínú ohun gbogbo, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ipò orí Baba rẹ̀.—Mát. 20:23; Jòh. 5:30; 1 Kọ́r. 15:28.

10. Báwo ni aya kan ṣe lè ti ipò orí ọkọ ẹ̀ lẹ́yìn?

10 Àwọn Kristẹni aya gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa títẹríba fún ipò orí ọkọ wọn. (Ka 1 Pét. 2:21; 3:1, 2.) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà kan tí aya kan lè gbà ṣe èyí. Ọmọkùnrin rẹ̀ kan sọ fún un pé òun fẹ́ ṣe nǹkan kàn, òun sì fẹ́ káwọn òbí òun fàṣẹ sí i kóun tó ṣe é. Nítorí pé àwọn òbí náà kò tíì jọ sọ̀rọ̀ yẹn tẹ́lẹ̀, ohun tó máa dáa kí ìyá yẹn ṣe ni pé kó bi ọmọ yẹn pé, “Ṣó o ti sọ fún dádì ẹ?” Bí ọmọ náà bá sọ pé òun ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀, ìyá yẹn gbọ́dọ̀ jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ kó tó ṣèpinnu èyíkéyìí. Bákan náà, Kristẹni aya kan ò gbọ́dọ̀ máa ta kò ọkọ ẹ̀ tàbí kó máa bá a jiyàn níṣojú àwọn ọmọ. Tí kò bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọkọ ẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan, ìgbà tí wọ́n bá dá wà ló yẹ kó jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀.—Éfé. 6:4.

Jésù Fàpẹẹrẹ Lélẹ̀ Fáwọn Òbí

11. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn òbí?

11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò gbéyàwó, kò sì bímọ, àpẹẹrẹ títayọ ló jẹ́ fáwọn Kristẹni òbí. Lọ́nà wo? Nípa ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ rẹ̀, ó fìfẹ́ àti sùúrù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́. (Lúùkù 8:1) Ọ̀nà tí Jésù máa ń gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lò jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe yẹ káwọn náà máa bá àwọn ẹlòmíì lò.—Ka Jòhánù 13:14-17.

12, 13. Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n bá fẹ́ káwọn ọmọ wọn dàgbà dẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run?

12 Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn òbí wọn, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú. Torí náà, ẹ̀yin òbí, ẹ bi ara yín pé: ‘Kí là ń kọ́ àwọn ọmọ wa nípasẹ̀ àpẹẹrẹ wa, tó bá dọ̀rọ̀ iye àkókò tá a fi ń wo tẹlifíṣọ̀n tá a sì fi ń ṣeré ìnàjú, àtèyí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì fi ń lọ sóde ẹ̀rí? Kí la fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìdílé wa? Ṣé à ń fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa jíjẹ́ kí ìjọsìn tòótọ́ gbapò iwájú nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe?’ Òfin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wà lọ́kàn àwọn òbí, bí wọ́n bá fẹ́ káwọn ọmọ wọn dàgbà dẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run.—Diu. 6:6.

13 Báwọn òbí bá ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe, àwọn ọmọ máa ń kíyè sí wọn. Ọ̀rọ̀ táwọn òbí bá sọ àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n bá kọ́ àwọn ọmọ wọn máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Àmọ́, báwọn ọmọ bá mọ̀ pé àwọn òbí àwọn kì í ṣàwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́ àwọn, wọ́n lè máa rò pé àwọn ìlànà Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tàbí pé kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò. Èyí ò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè lókun láti kojú ìdẹwò.

14, 15. Kí ló yẹ káwọn òbí gbìn sọ́kàn àwọn ọmọ wọn, ọ̀nà wo ni wọ́n sì lè gbà ṣe èyí?

14 Àwọn Kristẹni òbí mọ̀ pé ọmọ títọ́ ju pé kí wọ́n ṣáà ti máa pèsè àwọn nǹkan tara fáwọn ọmọ wọn lọ. Torí náà, kì í ṣohun tó bọ́gbọ́n mu pé káwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa lé àwọn nǹkan tó lè ṣàǹfààní fún wọn nípa tara nìkan. (Oníw. 7:12) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. (Mát. 6:33) Torí náà, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n sapá láti gbìn ín sọ́kàn àwọn ọmọ wọn pé nǹkan tẹ̀mí ni kí wọ́n máa lépa.

15 Ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà ṣe èyí ni pé kí wọ́n máa wá bí àwọn ọmọ wọn á ṣe máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ẹ wo bó ṣe máa fún àwọn ọ̀dọ́langba níṣìírí tó bí wọ́n bá sún mọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tàbí alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn. Àwọn míṣọ́nnárì, àwọn òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́ kárí ayé tó wá kí wọn nílé lè fi ìdánilójú sọ ayọ̀ tí wọ́n ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kò sí àní-àní pé irú àwọn àlejò bẹ́ẹ̀ á ní àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni láti sọ. Àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ gan-an láti ṣàwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wọ́n á ní àwọn àfojúsùn tó dáa, wọ́n á sì lè ka ìwọ̀nba ìwé tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

Ẹ̀yin Ọmọ, Kí Ló Máa Ràn Yín Lọ́wọ́ Láti Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù?

16. Báwo ni Jésù ṣe bọlá fáwọn òbí ẹ̀ láyé àti Baba rẹ̀ ọ̀run?

16 Ẹ̀yin ọmọ, Jésù fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ fún ẹ̀yin náà. Jósẹ́fù àti Maria ló tọ́jú Jésù dàgbà, ó sì gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. (Ka Lúùkù 2:51.) Jésù mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Jósẹ́fù àti Màríà, síbẹ̀ Ọlọ́run ló ní kí wọ́n máa bójú tó òun. Torí ìdí yìí, òun gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn. (Diu. 5:16; Mát. 15:4) Nígbà tí Jésù dàgbà, ìgbà gbogbo ló máa ń ṣohun tínú Baba ẹ̀ dùn sí. Ìyẹn sì gba pé kó má juwọ́ sílẹ̀ fún àdánwò. (Mát. 4:1-10) Ìgbà míì á wà tẹ́yin èwe á kojú ìdẹwò láti ṣàìgbọràn sáwọn òbí yín. Kí ló lè ràn yín lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

17, 18. (a) Ìṣòro wo làwọn ọ̀dọ́ máa ń dojú kọ níléèwé? (b) Kí làwọn ọ̀dọ́ lè máa rántí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àdánwò?

17 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ iléèwé ẹ ni ò fi bẹ́ẹ̀ ka ìlànà Bíbélì sí tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ kà á sí rárá. Wọ́n lè gbìyànjú láti mú kó o lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tí kò dáa, kí wọ́n sì wá máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tó o bá sọ pó ò ṣe? Ṣáwọn ọmọléèwé ẹ ti pè ẹ́ lórúkọ burúkú rí, torí pé o kọ̀ láti báwọn lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tí kò dáa? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo ṣe? O mọ̀ pé, tó o bá lọ jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú kó o dara pọ̀ mọ́ wọn, ńṣe lo máa já àwọn òbí ẹ àti Jèhófà kulẹ̀. Ipa wo ló máa ní lórí ẹ tó o bá lọ dara pọ̀ mọ́ wọn? Ó ṣeé ṣe kó o ti láwọn àfojúsùn kan, bóyá o fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, bóyá ńṣe lo sì fẹ́ lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tàbí ní Bẹ́tẹ́lì. Ṣé ọwọ́ ẹ á tẹ àwọn àfojúsùn yẹn tó o bá lọ́wọ́ nínú nǹkan táwọn ọmọléèwé ẹ fẹ́ kó o ṣe?

18 Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ wà nínú ìjọ Kristẹni, ǹjẹ́ ẹ ti bára yín nínú ipò kan rí tó dán ìgbàgbọ́ yín wò? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lẹ ṣe? Ẹ ronú nípa Jésù tó jẹ́ àwòkọ́ṣe yín. Kò juwọ́ sílẹ̀ fún àdánwò, ńṣe ló dúró gbọ́n-in láti ṣohun tó mọ̀ pé ó tọ́. Bó o bá ń rántí ohun tí Jésù ṣe yìí, ó máa fún ẹ lókun láti ṣàlàyé kedere fáwọn ọmọléèwé ẹ pé o ò ní bá wọn lọ́wọ́ nínú nǹkan tó o mọ̀ pé kò tọ́. Bíi ti Jésù, ńṣe ni kó o pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tó o ní láti máa fayọ̀ sin Jèhófà títí ayé, kó o sì máa ṣègbọràn sí i.—Heb. 12:2.

Ohun Tó Lè Mú Kí Ayọ̀ Wà Nínú Ìdílé

19. Ìgbé ayé wo ló lè fúnni láyọ̀ tòótọ́?

19 Ohun tó dáa ni Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ń fẹ́ fún àwa èèyàn. Kódà, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, a ṣì lè máa láyọ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. (Aísá. 48:17, 18; Mát. 5:3) Jésù kọ́ni ní òtítọ́ nípa ẹ̀sìn, èyí tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ayọ̀ àwa èèyàn. Àmọ́, ìyẹn nìkan kọ́ ni Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó tún kọ́ni nípa béèyàn ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ. Láfikún sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ìgbé ayé ẹ̀ àti ìwà ẹ̀ tún fi hàn pé ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Yálà a jẹ́ ọkọ, aya tàbí ọmọ nínú ìdílé, a máa jàǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Torí náà, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù! Ó dájú pé tá a bá ń fi ohun tí Jésù fi kọ́ni sílò, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ọkàn wa á balẹ̀, a ó sì máa láyọ̀ nínú ìdílé wa.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ló ṣe yẹ káwọn ọkọ máa lo ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn?

• Báwo làwọn aya ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

• Kí làwọn òbí lè kọ́ látinú bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lò?

• Kí làwọn ọ̀dọ́ lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Kí ló yẹ kí ọkọ kan tó nífẹ̀ẹ́ ṣe kó tó ṣèpinnu tó máa kan ìdílé rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ìgbà wo ni aya kan lè fi hàn pé òun tẹrí ba fún ipò orí ọkọ òun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn ọmọ máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ̀ rere àwọn òbí wọn