Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù

A “máyàle . . . láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín.”—1 TẸS. 2:2.

1. Kí ló mú kí ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fani lọ́kàn mọ́ra tó bẹ́ẹ̀?

 OHUN ayọ̀ mà ló jẹ́ o láti gbọ́ ìhìn rere! Àmọ́, ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lọ. Ìhìn rere yìí fi dá wa lójú pé òpin máa dé bá ìjìyà, àìsàn, ìnira, ìdààmú àti ikú. Ó jẹ́ ká nírètí ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe àti bá a ṣe lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. O lè máa rò ó pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó láyọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere tí Jésù ń kéde fáráyé yìí. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.

2. Ṣàlàyé ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù náà: “Mo wá láti fa ìpínyà” túmọ̀ sí.

2 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀, bí kò ṣe idà. Nítorí mo wá láti fa ìpínyà, láti pín ọkùnrin níyà sí baba rẹ̀, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, àti ọ̀dọ́ aya sí ìyá ọkọ rẹ̀. Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mát. 10:34-36) Dípò káwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba ìhìn rere yìí, ńṣe lọ́pọ̀ kọ̀ ọ́. Àwọn kan tiẹ̀ sọ ara wọn di ọ̀tá àwọn tó ń polongo ìhìn náà, kódà wọn ì bá à jẹ́ ara ìdílé wọn pàápàá.

3. Kí la nílò ká bàa lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù tá a gbélé wa lọ́wọ́ nìṣó?

3 Àwa náà ń kéde òtítọ́ kan náà tí Jésù wàásù, nígbà táwọn èèyàn bá sì gbọ́, ìṣesí wọn ò yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà ayé Jésù. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòh. 15:20) Lọ́pọ̀ ilẹ̀, àwọn èèyàn kì í gbéjà kò wá lójúkojú, àmọ́ wọ́n máa ń pẹ̀gàn wa, wọ́n kì í sì í fetí sí wa. Torí náà, a nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ká bàa lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà nìṣó láìṣojo.—Ka 2 Pétérù 1:5-8.

4. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ní láti “máyàle” kó lè wàásù?

4 Nígbà míì, ó lè má rọrùn fún ẹ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí kẹ́rù máa bà ẹ́ láti lọ́wọ́ nínú apá kan lára rẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lọ̀rọ̀ ẹ rí bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ẹni tó máa ń fìgboyà àti àìṣojo wàásù tó, tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú ẹ̀, síbẹ̀, àwọn ìgbà kan wà tí kò rọrùn fún un láti wàásù. Ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà, tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi (gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀) ní ìlú Fílípì, ti máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.” (1 Tẹs. 2:2) Nílùú Fílípì, àwọn aláṣẹ fi ọ̀pá na Pọ́ọ̀lù àti Sílà alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì de ẹsẹ̀ wọn mọ́ àbà. (Ìṣe 16:16-24) Síbẹ̀ náà, Pọ́ọ̀lù àti Sílà “máyàle” kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì fìgboyà sọ òtítọ́ nípa Jèhófà, ká sì kọ́ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.

A Nílò Ìgboyà Ká Lè Fara Da Ìṣọ̀tá

5. Kí nìdí tí ìgboyà fi ṣe pàtàkì fáwọn tó ń fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà?

5 Jésù Kristi làpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ìgboyà àti àìṣojo. Síbẹ̀ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn ni ìgboyà ti jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì fún gbogbo àwọn tó ń fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà. Kí nìdí? Lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà Édẹ́nì, Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìṣọ̀tá máa wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tó ń sin Sátánì. (Jẹ́n. 3:15) Kò sì pẹ́ tí ìṣọ̀tá yìí fi hàn nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ébẹ́lì ọkùnrin olóòótọ́ náà nígbà tí ẹ̀gbọ́n ẹ̀ pa á. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn tún di ọ̀tá Énọ́kù, ọkùnrin olóòótọ́ tó gbáyé ṣáájú Ìkún-omi. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́ láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. (Júúdà 14, 15) Ó dájú pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sóhun tó sọ yìí. Àwọn èèyàn kórìíra Énọ́kù, kò sì sí àní-àní pé ńṣe ni wọn ò bá ṣìkà pa á ká ní Jèhófà ò fúnra ẹ̀ gba ẹ̀mí Énọ́kù. Ìgboyà Énọ́kù mà lágbára o!—Jẹ́n. 5:21-24.

6. Kí nìdí tí Mósè fi nílò ìgboyà láti bá Fáráò sọ̀rọ̀?

6 Tún ronú nípa ìgboyà tí Mósè fi hàn láti bá Fáráò sọ̀rọ̀, ojú táwọn èèyàn fi ń wo aláṣẹ yìí ju pé ó ń ṣojú fún ọlọ́run wọn lọ, ọlọ́run kan ni wọ́n kà á sí, ìyẹn ọmọkùnrin ọlọ́run oòrùn tí wọ́n ń pè ní Ráà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Fáráò yìí náà jọ́sìn ère ara ẹ̀ bíi tàwọn Fáráò tó kù. Òfin làwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀, torí pé apàṣẹwàá ni. Fáráò alágbára, tó ń ṣakọ, tó sì jẹ́ olóríkunkun yìí kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun tó máa ṣe fún un. Níwájú ọkùnrin yìí ni Mósè, olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ onínútútù ti fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà láìjẹ́ pé ó ránṣẹ́ sí i, tí ò sì ṣe tán láti gbà á lálejò. Àsọtẹ́lẹ̀ wo sì ni Mósè sọ? Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìyọnu apanirun. Kí ni Mósè béèrè? Ó ní kó fi àwọn ẹrú ẹ̀ tí wọ́n tó mílíọ̀nù bíi mélòó kan sílẹ̀, kí wọ́n sì kúrò nílùú náà! Ǹjẹ́ Mósè nílò ìgboyà? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni!—Núm. 12:3; Héb. 11:27.

7, 8. (a) Àwọn ìṣòro wo làwọn olóòótọ́ ìgbàanì dojú kọ? (b) Kí ló ran àwọn olóòótọ́ yẹn lọ́wọ́ láti fìgboyà ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn?

7 Ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni làwọn wòlíì àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà míì ti ń bá a nìṣó láti máa fìgboyà ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Ayé Sátánì ò nífẹ̀ẹ́ wọn rárá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A sọ wọ́n ní òkúta, a dán wọn wò, a fi ayùn rẹ́ wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kú nípa fífi idà pa wọ́n, wọ́n lọ káàkiri nínú awọ àgùntàn, nínú awọ ewúrẹ́, nígbà tí wọ́n wà nínú àìní, nínú ìpọ́njú, lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́.” (Héb. 11:37) Kí ló ran àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí lọ́wọ́ láti dúró gbọin-in? Ní ẹsẹ bíi mélòó kan tó ṣáájú ẹsẹ yẹn, àpọ́sítélì yìí sọ ohun tó fún Ébẹ́lì, Ábúráhámù, Sárà àtàwọn tó kù lókun láti fara dà á. Ó ní: “Bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n [pẹ̀lú ìgbàgbọ́] wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n.” (Héb. 11:13) Kò sí àní-àní pé ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn wòlíì bíi Èlíjà, Jeremáyà àtàwọn olóòótọ́ yòókù tó gbáyé ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà ló jẹ́ kí wọ́n fìgboyà gbèjà ìjọsìn tòótọ́.—Títù 1:2.

8 Tìdùnnú-tìdùnnú làwọn olóòótọ́ tó wà ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni fi fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Tí wọ́n bá jíǹde, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n á dẹni pípé, wọ́n á sì dẹni tá a “dá . . . sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́” nípasẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà Kristi Jésù àti tàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) táwọn náà jẹ́ àlùfáà lábẹ́ ìdarí Kristi. (Róòmù 8:21) Síwájú sí i, Jeremáyà àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ nígboyà torí ìdánilójú tí Jèhófà fún wọn, èyí hàn nínú ìlérí tó ṣe fún Jeremáyà pé: “Ó . . . dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’” (Jer. 1:19) Lóde òní, tá a bá ronú lórí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa nípa ọjọ́ ọ̀la àti bí Jèhófà ò ṣe ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú òun jẹ́, ìyẹn máa ń fún àwa náà lókun.—Òwe 2:7; ka 2 Kọ́ríńtì 4:17, 18.

Ìfẹ́ Ló Mú Kí Jésù Fìgboyà Wàásù

9, 10. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà lo ìgboyà níwájú (a) àwọn aṣáájú ìsìn, (b) àwọn ọmọ ogun, (d) àlùfáà àgbà, (e) Pílátù?

9 Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jésù tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa gbà fìgboyà hàn. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó láṣẹ tí wọ́n sì yọrí ọlá kórìíra ẹ̀, Jésù ò fomi la ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Pẹ̀lú ìgboyà, ó tú àṣírí ìwà ìbàjẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn fún bí wọ́n ṣe ka ara wọn sí olódodo, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni. Ẹni ègbé làwọn ọkùnrin yẹn, Jésù ò sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n nígbà tó ń báwọn sọ̀rọ̀. Lákòókò kan, ó ní: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ jọ àwọn sàréè tí a kùn lẹ́fun, tí wọ́n fara hàn lóde bí ẹlẹ́wà ní tòótọ́ ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún egungun òkú ènìyàn àti gbogbo onírúurú ohun àìmọ́. Ní ọ̀nà yẹn, ẹ̀yin pẹ̀lú, ní tòótọ́, fara hàn lóde bí olódodo sí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ní inú, ẹ kún fún àgàbàgebè àti ìwà-àìlófin.”—Mát. 23:27, 28.

10 Nígbà tí wọ́n kógun dé láti wá mú Jésù lọ́gbà Gẹtisémánì, pẹ̀lú ìgboyà ló fi fara ẹ̀ hàn wọ́n. (Jòh. 18:3-8) Nígbà tó yá, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, àlùfáà àgbà sì bi í ní ìbéèrè. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé ńṣe ni àlùfáà àgbà ń wá ọ̀nà láti pa òun, síbẹ̀ pẹ̀lú ìgboyà ni Jésù fi jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi àti Ọmọ Ọlọ́run. Ó tún sọ síwájú sí i pé wọ́n máa rí i tóun á ‘jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tóun á sì máa bọ̀ nínú àwọsánmà ọ̀run.’ (Máàkù 14:53, 57-65) Lẹ́yìn ìyẹn wọ́n de Jésù, wọ́n sì mú un lọ síwájú Pílátù tó yẹ kó tú u sílẹ̀. Àmọ́ Jésù ò sọ nǹkan kan láti dáhùn àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. (Máàkù 15:1-5) Gbogbo ohun tó ṣe yìí ló gba ìgboyà.

11. Báwo ni ìgboyà ṣe tan mọ́ ìfẹ́?

11 Jésù sọ fún Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòh. 18:37) Jèhófà ti gbé iṣẹ́ ìwàásù lé Jésù lọ́wọ́, inú Jésù sì dùn láti ṣe iṣẹ́ náà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run. (Lúùkù 4:18, 19) Jésù tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó mọ̀ pé ìgbésí ayé ò rọrùn fún wọn. Bákan náà, torí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa la ṣe ń fìgboyà wàásù.—Mát. 22:36-40.

Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Jẹ́ Ká Lè Máa Fìgboyà Wàásù

12. Kí ló fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní láyọ̀?

12 Láwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ikú Jésù, inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn dùn bí Jèhófà ṣe ń fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun kún wọn. Tó fi jẹ́ pé lọ́jọ́ kan ṣoṣo, àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tó tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] tó wá láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù fún ayẹyẹ Pẹ́ńtíkọ́sì ló ṣe batisí! Ẹ wo bí wọ́n á ṣe máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí káàkiri ìlú Jerúsálẹ́mù! Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba olúkúlùkù ọkàn, ọ̀pọ̀ àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.”—Ìṣe 2:41, 43.

13. Kí nìdí táwọn ará fi gbàdúrà fún ìgboyà, kí sì ni àbájáde ẹ̀?

13 Àwọn aṣáájú ìsìn tínú ń bí mú Pétérù àti Jòhánù, wọ́n tì wọ́n mọ́lé lóru mọ́jú, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́. Nígbà tí wọ́n fi wọ́n sílẹ̀, àwọn méjèèjì lọ sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn ará tó kù, gbogbo wọn jù mọ̀ gbàdúrà, wọ́n sì bẹ Jèhófà nípa inúnibíni tí wọ́n dojú kọ yìí pé: “Jèhófà, . . . yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—Ìṣe 4:24-31.

14. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

14 Kíyè sí i pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìgboyà. Ìgboyà láti sọ òtítọ́ fáwọn èèyàn, pàápàá fáwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa ju agbára wa lọ. Jèhófà á fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ tá a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa náà lè fi hàn pé a nígboyà tá a bá dojú kọ àtakò, a ó sì borí.—Ka Sáàmù 138:3.

Àwọn Kristẹni Lóde Òní Ń Fìgboyà Wàásù

15. Báwo ni òtítọ́ ṣe ń pín àwọn èèyàn níyà lóde òní?

15 Lóde òní bíi ti àkókò tó ti kọjá, òtítọ́ ṣì ń pín àwọn èèyàn níyà sí ara wọn. Àwọn kan ń fetí sí wa dáadáa, nígbà táwọn kan ò sì ka ìjọsìn wa sí. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn kan máa ń ṣàríwísí nípa wa, wọ́n máa ń fiwá ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kórìíra wa pàápàá. (Mát. 10:22) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde máa ń parọ́ mọ́ wa láti bà wá lórúkọ jẹ́. (Sm. 109:1-3) Síbẹ̀, kárí ayé làwa èèyàn Jèhófà ń fìgboyà kéde ìhìn rere.

16. Ìrírí wo ló fi hàn pé ìgboyà lè mú káwọn tá a ń wàásù fún tún èrò wọn ṣe?

16 Ìgboyà tá a ní lè mú káwọn èèyàn tún èrò wọn ṣe lórí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Arábìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan sọ pé: “Nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan sọ fún mi pé: ‘Mo gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ kì í ṣe Ọlọ́run àwọn Kristẹni. Torí náà tó o bá tún wá síbí yìí, màá dẹ ajá sí ẹ!’ Ajá ńlá kan tó dè mọ́lẹ̀ sì wà lẹ́yìn ẹ̀ lóòótọ́. Àmọ́, lákòókò tá a pin Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 37, ìyẹn ‘Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!,’ mo pinnu láti lọ sílé yẹn pẹ̀lú èrò pé màá rí ẹlòmíì tó jẹ́ ara ìdílé ọkùnrin yẹn. Àmọ́, ọkùnrin yẹn náà ló tún ṣílẹ̀kùn. Mo tètè gbàdúrà sí Jèhófà, mo wá sọ pé: ‘Ẹ ǹlẹ́ sà, mo rántí ìjíròrò wa lọ́jọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, mo sì tún rántí ajá yín. Àmọ́ mi ò kàn lè gba ibí kọjá kí n má kàn sí yín, torí pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo lèmi náà gbà gbọ́ bíi tiyín. Ọlọ́run máa tó fìyà jẹ gbogbo ìsìn tí ò bọ̀wọ̀ fún un. Ẹ lè kọ́ ohun tó pọ̀ sí i nípa èyí tẹ́ ẹ bá ka ìwé yìí.’ Sí ìyàlẹ́nu mi, ọkùnrin yìí gba Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run náà lọ́wọ́ mi. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ilé míì. Ní ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn náà, lọkùnrin yìí bá ń sáré bọ̀ wá bá mi pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run náà lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ní: ‘Mo ti kà á. Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n má bàa rí ìbínú Ọlọ́run?’” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọkùnrin yẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé.

17. Báwo nígboyà arábìnrin kan ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń bẹ̀rù nígboyà?

17 Ìgboyà wa tún lè fún àwọn èèyàn níṣìírí láti nígboyà. Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, arábìnrin kan tó wọkọ̀ èrò fẹ́ fún obìnrin kan tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ ní ìwé ìròyìn. Lójú ẹsẹ̀, ọkùnrin kan dìde lórí àga ẹ̀, ó já ìwé ìròyìn náà gbà lọ́wọ́ arábìnrin yẹn, ó rún un, ó sì jù ú sílẹ̀. Ó jágbe mọ́ arábìnrin náà, ó bú u, ó ní kó fún òun ní àdírẹ́sì ibi tó ń gbé, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọ́dọ̀ wàásù lábúlé náà. Arábìnrin náà gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́, lẹ́yìn náà ó rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹ má . . . bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara.” (Mát. 10:28) Ó dìde tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì sọ fún ọkùnrin náà pé, “Mi ò ní fún ẹ ní àdírẹ́sì mi, màá sì máa wàásù ní abúlé náà.” Lẹ́yìn náà, ó bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà. Arábìnrin yìí ò mọ̀ pé ẹnì kan tóun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà nínú ọkọ̀ náà. Ìbẹ̀rù èèyàn ti mú kí obìnrin náà pa ìpàdé tì. Nígbà tó rí ìgboyà arábìnrin wa yìí, ló bá pinnu pé òun á tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé.

18. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fìgboyà wàásù bíi ti Jésù?

18 Nínú ayé táwọn èèyàn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run yìí, ó gba ìgboyà láti wàásù bí Jésù ti ṣe. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Máa wo ọjọ́ iwájú. Mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò ẹ lágbára. Gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ nígboyà. Má gbàgbé pé ìwọ nìkan kọ́, Jésù wà pẹ̀lú ẹ. (Mát. 28:20) Ẹ̀mí mímọ́ á fún ẹ lókun. Jèhófà á bù kún ẹ, á sì tì ẹ́ lẹ́yìn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fìgboyà sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?”—Héb. 13:6.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi nílò ìgboyà?

• Tó bá dọ̀rọ̀ ìgboyà, kí la rí kọ́ lára . . .

àwọn olóòótọ́ tó gbáyé ṣáájú Kristi?

Jésù Kristi?

àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?

àwọn Kristẹni lóde òní?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Jésù fìgboyà tú àṣírí àwọn aṣáájú ìsìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Jèhófà ń fún wa nígboyà láti wàásù