Ǹjẹ́ O Ti Ya Àkókò Kan Sọ́tọ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Ǹjẹ́ O Ti Ya Àkókò Kan Sọ́tọ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
LỌ́DÚN tó kọjá, Ìgbìmọ̀ Olùdarí kéde pé àtúnṣe ti dé bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ìjọ, èyí tí yóò jẹ́ kí àkókò túbọ̀ wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìjíròrò ìdílé. Tó o bá jẹ́ olórí ìdílé máa rí i dájú pé ò ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé pẹ̀lú aya àtàwọn ọmọ rẹ, kó o sì ṣe é lọ́nà táá ṣe wọ́n láǹfààní. Tọkọtaya tí kò tíì lọ́mọ yóò lo àkókò yìí fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. Àwọn arákùnrin tí kò láya tàbí àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ, tí kò ní ìdílé tí wọ́n ń bójú tó yóò lè lo àkókò yìí fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi ìmọrírì wọn hàn fún ètò ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé nírọ̀lẹ́. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Kevin, tó jẹ́ alàgbà sọ pé: “A ò tiẹ̀ mọ bá ò bá ṣe dúpẹ́ lórí bí ọ̀rọ̀ náà ti rí lára àwa ará ìjọ. Àwa alàgbà ti jíròrò bí a ṣe máa lo àkókò tó yọ ní ìrọ̀lẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ní ká lò ó láti fi bá àwọn ìdílé wa kẹ́kọ̀ọ́.”
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jodi, tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ alàgbà sọ pé: “A ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta, èyí àgbà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, èyí tó tẹ̀ lé e jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, èyí tó gbẹ̀yìn sì jẹ́ ọmọ ọdún méjì. A ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè adití ni. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti àkókò láti múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀. Nísinsìnyí tí àtúnṣe yìí ti wáyé, àyè ọjọ́ kan ti yọ sílẹ̀ fún wa láti fi ṣe Ìjọsìn Ìdílé!”
Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ John àti JoAnn jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, wọ́n sọ pé: “A kì í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa déédéé, torí pé ńṣe la máa ń fi há àárín àwọn onírúurú ìgbòkègbodò ìjọ. Ìṣètò tuntun yìí jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì ń tù wá lára nípa tẹ̀mí, ìyẹn bí a bá lo àkókò náà bí wọ́n ṣe ní ká lò ó.”
Arákùnrin àpọ́n kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tony ti lé ní ogún ọdún dáadáa, ó ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Tuesday sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrọ̀lẹ́ tó fi ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó máa ń lo àwọn àkókò yòókù nínú ọ̀sẹ̀ fún mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀. Àmọ́ Tony sọ pé: “Ńṣe ló máa ń dà bíi pé kí ọjọ́ Tuesday ti dé.” Kí nìdí rẹ̀? Ó sọ pé: “Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn jẹ́ àkókò pàtàkì témi àti Jèhófà fi máa ń wà pa pọ̀.” Tony tún ṣàlàyé pé: “Ó máa ń gba nǹkan bíi wákàtí méjì tí mo fi máa ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn kókó tó ń jẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i. Bí mo ṣe ń ní àkókò tó pọ̀ sí i láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń jẹ́ kí n ronú dáadáa lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo bá kà.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó ní: “Ìmọ̀ràn Jèhófà ń wọnú ọkàn mi jinlẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Àpẹẹrẹ wo ló mú wá? Ó sọ pé: “Nínú ìwé Insight, mo kà nípa Dáfídì àti Jónátánì tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́. Mo kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ látinú bí Jónátánì ṣe ní ẹ̀mí àìmọtara ẹni nìkan. Àpẹẹrẹ rẹ̀ ti ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ rí béèyàn ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́. Mò ń fojú sọ́nà gan-an láti rí ọ̀pọ̀ sí i lára irú àwọn ohun iyebíye bẹ́ẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Tuesday!”
Láìsí àní-àní, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò jàǹfààní gan-an látinú lílo àkókò tó yọ sílẹ̀ yìí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìjọsìn ìdílé.