Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Mẹ́síkò

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Mẹ́síkò

INÚ wa ń dùn gan-an pé àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tó ń jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Mát. 6:22) Àwọn ìyípadà wo ni wọ́n ń ṣe? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n ń dojú kọ? Ká lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó ń sìn ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

“A NÍ LÁTI ṢE ÌYÍPADÀ”

Dustin àti Jassa

Oṣù January ọdún 2007 ni Arákùnrin Dustin àti ìyàwó rẹ̀ Jassa tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣègbéyàwó. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ọwọ́ wọn tẹ ohun kan tó ti ń wù wọ́n tipẹ́, ìyẹn ọkọ̀ ojú omi ìgbafẹ́. Inú rẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé. Ìlú Astoria, tó wà ní ìpínlẹ̀ Oregon, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n wa ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sí. Ó jẹ́ àgbègbè kan tó fani mọ́ra nítorí pé ibi yòówù kéèyàn yíjú sí, èèyàn á rí àwọn òkè kéékèèké tí igi pọ̀ lórí wọn àti àwọn òkè ńlá tí yìnyín bò, ó tún wá sún mọ́ Òkun Pàsífíìkì. Dustin sọ pé: “Àrímáleèlọ ni gbogbo ohun tó wà níbí!” Àwọn méjèèjì gbà pé àwọn ò ṣe ju ara àwọn lọ, àwọn sì gbára lé Jèhófà. Ó ṣe tán, inú ọkọ̀ ojú omi tí kò ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínlógún lọ ni wọ́n ń gbé, iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ ni wọ́n ń ṣe, ìjọ tí wọ́n ti lè máa ran àwọn tó ń sọ èdè àjèjì lọ́wọ́ ni wọ́n ń dara pọ̀ mọ́, àti pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n máa ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n wá rí i pé ńṣe ni àwọn ń tan ara àwọn jẹ. Dustin sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àkókò tó yẹ ká lò láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọ la máa fí ń tún ọkọ̀ wa ṣe. A mọ̀ pé tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, a ní láti ṣe ìyípadà.”

Jassa náà sọ pé: “Kí n tó ṣe ìgbéyàwó, orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni mò ń gbé, mo sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mó fẹ́ràn ìjọ tí mo wà tẹ́lẹ̀ yẹn gan-an ni, ó sì wù mí pé kí n pa dà lọ sí ìjọ náà.” Nígbà tí Dustin àti Jassa bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé, wọ́n máa ń ka ìtàn ìgbésí ayé àwọn ará wa tí wọ́n ń sìn ní ilẹ̀ òkèèrè níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. (Jòh. 4:35) Dustin sọ pé: “Ó wu àwa náà ká máa láyọ̀ bíi tiwọn.” Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ wọn kan láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò fi tó wọn létí pé wọ́n nílò àwọn àkéde tó lè yọ̀ǹda ara wọn ní àwùjọ tuntun kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ níbẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n gbé ìgbésẹ̀. Wọ́n fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, wọ́n tún ta ọkọ̀ ojú omi wọn, wọ́n sì lọ sí orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

“OHUN TÓ DARA JÙ TÁ A ṢE”

Ìlú Tecomán tó fi ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin kìlómítà jìnnà síbi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ ni Dustin àti Jassa gbalé sí. Ibẹ̀ pẹ̀lú sì sún mọ́ Òkun Pàsífíìkì. Dustin sọ pé: “Àyíká ibẹ̀ yàtọ̀ sí ibi tá à ń gbé tẹ́lẹ̀ gan-an, ní ti pé ooru pọ̀ gan-an níbẹ̀, igi ọsàn wẹ́wẹ́ sì pọ̀ lọ salalu.” Nígbà tí wọ́n tiẹ̀ kọ́kọ́ dé ibẹ̀, wọn kò rí iṣẹ́ tí wọ́n máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìrẹsì àti ẹ̀wà ṣáá ni wọ́n máa ń jẹ torí pé ohun tí ìwọ̀nba owó tó wà lọ́wọ́ wọn lè ká nìyẹn. Jassa sọ pé: “Àmọ́ nígbà tó fi máa di pé ohun tá à ń jẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í yọ wá lẹ́nu, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í fún wa ní àwọn èso bíi máńgòrò, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àti ìbẹ́pẹ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tí àìmọye ọsàn wẹ́wẹ́ tí wọ́n kó fún wa.” Nígbà tó yá, wọ́n rí iṣẹ́ ní iléèwé kan tó wà lórílẹ̀-èdè Taiwan àmọ́ tó máa ń kọ́ni lédè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Owó tó ń wọlé fún wọn sì tó gbọ́ bùkátà wọn dáadáa.

Ǹjẹ́ Dustin àti Jassa kábàámọ̀ àwọn àyípadà tí wọ́n ṣe yìí? Àwọn méjèèjì sọ pé: “Bá a ṣe lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù lohun tó dara jù lọ́ tá a ṣe nígbèésí ayé wa. Ó mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó mú káwa méjèèjì túbọ̀ sún mọ́ra, à ń lọ́ sí òde ẹ̀rí papọ̀, a jọ ń jíròrò bá a ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́, a tún jọ máa ń múra ìpàdé sílẹ̀. Ọkàn wa ti wá bálẹ̀ gan-an báyìí. A ti wá rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ, pé ‘Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’”

OHUN TÓ MÚ KÍ Ọ̀PỌ̀ YỌ̀ǸDA ARA WỌN

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àpọ́n àtàwọn tọkọtaya tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogún ọdún sí ogójì ọdún ni wọ́n ti ṣí lọ́ sí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Kí nìdí tí àwọn ará yìí fi yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ńlá yìí? Nígbà tí wọ́n bi àwọn kan lára wọn ní ìbéèrè yìí, ohun mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sọ pé ó mú káwọn ṣe bẹ́ẹ̀. Kí làwọn ohun náà?

Leticia àti Hermilo

Kí wọ́n bàa lè fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Leticia nígbà tó ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo mọ̀ pé ohun tí mo ṣe yẹn ń béèrè pé kí n máa sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Kí n lè fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́, mo fẹ́ láti lo àkókò mi àti okun mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.” (Máàkù 12:30) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Hermilo ti lé díẹ̀ ní ogún ọdún nígbà tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Òun sì ló fẹ́ arábìnrin Leticia. Ó sọ pé: “Ohun tó dáa jù lọ tá a lè ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Máàkù 12:31) Torí náà, ó fi iṣẹ́ báǹkì tó ń ṣe ní ìlú Monterrey sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan rọ̀ṣọ̀mù ní ìlú náà, ìgbésí ayé tó sì dẹrùn ló ń gbé, àmọ́ ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ́ sí ìlú kékeré kan.

Essly

Kí wọ́n lè ní ojúlówó ayọ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Leticia ṣèrìbọmi, ó tẹ̀ lé arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ lọ́ sí ìlú àdádó kan láti lọ wàásù. Wọ́n sì lo oṣù kan níbẹ̀. Leticia sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an bí mo ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ń tẹ́tí sí ìhìnrere náà, inú mi sì dùn gan-an. Lẹ́yìn tá a ti lo oṣù kan níbẹ̀, mo sọ fún ara mi pé, ‘Iṣẹ́ tí mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe nìyí! ‘” Arábìnrin Essly tó ti lé díẹ̀ lógún ọdún tó ṣì wà láìlọ́kọ náà pinnu láti lọ wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Kí nìdí? Látìgbà tó ti wà ní iléèwé ló ti máa ń rí àwọn ará tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ó sọ pé: “Ó máa ń wù mí gan-an bí mo ṣe ń rí i tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin yẹn ń láyọ̀, èmi náà sì fẹ́ máa láyọ̀ bíi ti wọn.” Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin náà ló ti ṣe irú ìpinnu tí Essly ṣe yìí. Ní Mẹ́síkò àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ tó lé ní ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta [680] ló ń wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún tọmọdé tàgbà wa!

Kí ìgbé ayé wọn lè nítumọ̀ kí wọ́n má sì kábàámọ̀. Nígbà tí Essly ṣe tán ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, wọ́n fún un láǹfààní láti lọ kàwé ní yunifásítì lọ́fẹ̀ẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ lèyí jẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ sọ àǹfààní náà nù. Wọ́n ní ayé dùn-ún jẹ ju ìyà lọ, kó kàwé gboyè rẹpẹtẹ, kó níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́, kó máa lo mọ́tò àsìkò, kó sì máa rìnrìn àjò káàkiri ayé. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe rọ Essly tó, kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un yẹn. Ó sọ pé: “Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ mi kan bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn nǹkan táyé ń fẹ́ yìí, wọn ò wá ka àwọn nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì mọ́. Ńṣe ni nǹkan sì túbọ̀ ń dojú rú fún wọn bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ara lé àwọn nǹkan ti ayé. Àmọ́, ní tèmi, ó wù mí láti fi ìgbà ọ̀dọ́ mi sin Jèhófà ní kíkún.”

Racquel àti Phillip

Essly wá lọ gba àwọn àfikún ẹ̀kọ́ kan sí i, kó bàa lè rí iṣẹ́ tó lè fi máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, ó kó lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ó sì kọ́ èdè ìbílẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà kan tí wọ́n ń pè ní Otomi àti Tlapaneco ń sọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè náà kò rọrùn. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tó ti wà níbẹ̀, ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ nítumọ̀, mo sì ń láyọ̀. Lékè gbogbo rẹ̀, mo ti wá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa.” Arákùnrin Phillip àti Racquel ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n lé díẹ̀ lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún sọ pé: “Ọkàn àwọn èèyàn ò balẹ̀ mọ́ torí bí nǹkan ṣe ń yí pa dà nínú ayé. Ṣùgbọ́n bá a ṣe yọ̀ǹda ara wa láti wàásù níbí, tá a sì ń rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń tẹ́tí sí ìhìnrere, ọkàn wa balẹ̀, ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ ÌṢÒRO BÁ DÉ

Verónica

Ká sòótọ́, ó ṣeé ṣe káwọn ìṣòro kan yọjú tó o bá lọ wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ohun tó sábà máa ń jẹ́ olórí ìṣòro ni ọ̀rọ̀ àtigbọ́ bùkátà. Kó o lè borí ìṣòro yìí, o ní láti mú ara rẹ bá ipò èyíkéyìí tó o bá bá ara rẹ mu. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Verónica sọ pé: “Ní àgbègbè kan tí mo ti lọ wàásù, mo máa ń ṣe àwọn ìpápánu tí kò wọ́nwó, mo sì máa ń tà á. Ní ibòmíì tí mo tún lọ, aṣọ ni mò ń tà níbẹ̀, mo sì tún máa ń gé irun fáwọn èèyàn. Níbi tí mo wà báyìí, mo máa ń bá àwọn èèyàn tọ́jú ilé wọn, mo sì máa ń ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́mọ nípa bí wọ́n ṣe lè máa bá ọmọ wọn sọ̀rọ̀.”

Ìṣòro míì ni pé, àṣà àti ìṣe àwọn tó ń gbé níbi àdádó máa ń yàtọ̀ pátápátá sí èyí tó ti mọ́ èèyàn lára tẹ́lẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Phillip àti Racquel gan-an nìyẹn nígbà tí wọ́n lọ wàásù níbi tí àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl wà. Phillip sọ pé: “Ìṣe àti àṣà ibi tá a ti lọ sìn yàtọ̀ gan-an sí tiwa.” Àmọ́, kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi fara dà á? Phillip sọ pé: “Ńṣe la kúkú pọkàn pọ̀ sórí àwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní, ìyẹn bí àwọn ìdílé tó wà níbẹ̀ ṣe wà ní ìrẹ́pọ̀, bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, àti bí wọ́n ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́.” Racquel náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la kọ́ lára àwọn ará ìlú yẹn, a tún mọyì àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ tá a jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀.”

BÓ O ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀

Ǹjẹ́ ó wù ọ́ láti lọ́ ṣèrànwọ́ níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè máa ṣe láti múra sílẹ̀? Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti ń sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: Kó o tó lọ, kọ́ béèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó o sì ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun díẹ̀. (Fílí. 4:11, 12) Kí lo tún lè ṣe? Leticia sọ pé: “Mo ti pinnu pé mi ò ní ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí kò ní rọrùn láti fi sílẹ̀. Iṣẹ́ tí màá lè fi sílẹ̀ nígbàkigbà tí àǹfààní bá yọ láti lọ sìn ní ibikíbi ni mo máa ṣe.” Hermilo náà sọ pé: “Mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ, bí wọ́n ṣe ń fọ aṣọ àti bí wọ́n ṣe ń lọ̀ ọ́.” Verónica sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú àwọn òbí mi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi, mo máa ń tún ilé ṣe, mo sì kọ́ béèyàn ṣe lè fi owó díẹ̀ se oúnjẹ aṣaralóore. Bákan náà, mi ò kì í fọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹun.”

Amelia àti Levi

Arákùnrin Levi àti ìyàwó rẹ̀ Amelia tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́jọ. Nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sìn lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, wọ́n gbàdúrà fún ohun pàtó kan tí wọ́n fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún wọn, èyí sì ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ni. Levi sọ pé: “A ṣírò iye tó máa ná wa láti lọ sìn ní ìlú òkèèrè fún ọdún kan, lẹ́yìn náà a wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jọ̀wọ́ jẹ́ kí iye yẹn wọlé fún wa.” Láàárín oṣù mélòó kan, iye owó tí wọ́n béèrè fún nínú àdúrà gan-an ló wọlé fún wọn. Bíṣẹ́ ò bá pẹ́ni, a kì í pẹ́ṣẹ́, ni wọ́n bá gbéra lọ síbẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Levi sọ pé: “Ohun tá a béèrè lọ́wọ́ Jèhófà gẹ́lẹ́ ló ṣe fún wa, ó wá kù sọ́wọ́ tiwa báyìí láti ṣe ipa tiwa.” Amelia fi kún un pé: “Ọdún kan péré la ní lọ́kàn láti lò, àmọ́ ọdún keje là ń lò lọ báyìí, a ò sì ronú rárá láti kúrò! Bá a ṣe wà níbí yìí, à ń rí ọwọ́ Jèhófà lára wa gan-an. Ojoojúmọ́ la máa ń rí i pé ẹni rere ni Jèhófà lóòótọ́.”

Adam àti Jennifer

Arákùnrin Adam àti ìyàwó rẹ̀ Jennifer kúrò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sí àgbègbè kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àwọn náà gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì dáhùn àdúrà wọn. Wọ́n fún àwọn tó bá fẹ́ lọ wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i nímọ̀ràn pé: “Má ṣe ronú pé ó dìgbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ geere o. Sọ fún Jèhófà pé ó wù ẹ́ láti lọ wàásù níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, kó o sì gbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ. Ní báyìí ná, jẹ́ kí ìgbé ayé rẹ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó o sì jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn. Lẹ́yìn náà, kó o kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè tó wù ọ́ láti lọ wàásù. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe ìyẹn, kó o wá ṣírò ohun tó máa ná ẹ. Tó o bá ti gbé àwọn nǹkan pàtàkì yìí yẹ̀ wò, tó o sì rí i pé o ti múra tán. Má fàkókò ṣòfò rárá, ńṣe ni kó o gbéra!” * Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, ìgbésí ayé tó ládùn tó sì kún fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí ń dúró dè ọ́.

^ ìpínrọ̀ 21 Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Ǹjẹ́ O Lè ‘Ré Kọjá Lọ Sí Makedóníà’?” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2011.