Ìṣẹ̀dá Ń Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Ọlọ́run Alààyè
“Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo . . . nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo.”—ÌṢÍ. 4:11.
1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí i dájú pé ìgbàgbọ́ wa kò yingin?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn máa ń sọ pé ohun tí àwọn bá lè fi ojú rí nìkan làwọn gbà pé ó wà. Àmọ́, Bíbélì sọ pé, “kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòh. 1:18) Báwo wá la ṣe lè ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà? Kí la sì lè ṣe kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà, “Ọlọ́run tí a kò lè rí,” má bàa yingin? (Kól. 1:15) Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká mọ àwọn ẹ̀kọ́ tí kì í jẹ́ kéèyàn mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Lẹ́yìn náà, a gbọ́dọ̀ máa lo Bíbélì lọ́nà jíjáfáfá láti fi hàn pé irú àwọn èrò tàbí ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ “lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.”—2 Kọ́r. 10:4, 5.
2, 3. Àwọn ẹ̀kọ́ méjì wo ni kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́?
2 Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ èké tó gbalégbòde, tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Orí èrò èèyàn ni wọ́n gbé ẹ̀kọ́ yìí kà, ó ta ko ohun tó wà nínú Bíbélì, kì í sì í jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ní kúkúrú, ohun tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n fi ń kọ́ni ni pé ńṣe ni gbogbo ohun alààyè kan ṣàdédé wà. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé kò sí ìdí tá a fi wà láyé.
3 Ohun míì tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ ni ẹ̀kọ́ tí àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì kan fi ń kọ́ni. Wọ́n ní kò tíì ju ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọ̀run, ilẹ̀ ayé wa yìí àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀. Àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni lè sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́, àmọ́ wọ́n sọ pé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni ọjọ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ọlọ́run fi dá gbogbo nǹkan ní ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Wọn ò fara mọ́ àlàyé tí kò ṣeé já ní koro táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe nípa ìṣẹ̀dá, torí pé ó ta ko èrò wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti gba Bíbélì gbọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mú kó dà bíi pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kò bọ́gbọ́n mu àti pé kò tọ̀nà. Àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni lè mú ká rántí àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, àmọ́ wọn kò sìn ín “ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Báwo la ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi hàn pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àtàwọn ẹ̀kọ́ èké míì “tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” yìí kì í ṣòótọ́? * Ká tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, àyàfi kí àwa fúnra wa ṣiṣẹ́ kára ká lè ní ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.
GBÉ ÌGBÀGBỌ́ RẸ KARÍ Ẹ̀RÍ TÓ FẸSẸ̀ MÚLẸ̀ ÀTI ÈRÒ TÓ YÈ KOORO
4. Orí kí ló yẹ ká gbé ìgbàgbọ́ wa kà?
4 Bíbélì kọ́ wa pé kí á ka ìmọ̀ sí ohun tó ṣe pàtàkì. (Òwe 10:14) Jèhófà ò fẹ́ ká gbé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú òun karí èrò èèyàn tàbí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí ìsìn fi ń kọ́ni, orí ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ àti èrò tó yè kooro ló fẹ́ ká gbé e kà. (Ka Hébérù 11:1.) Ká tó lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dá wa lójú pé Jèhófà wà. (Ka Hébérù 11:6.) Kò tó láti wulẹ̀ gbà pé Ọlọ́run wà. Ohun tó lè mú ká gbà pé ó wà ni pé kí àwa fúnra wa ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ó wà ká sì tún lo “agbára ìmọnúúrò” wa.—Róòmù 12:1.
5. Sọ ìdí kan tá a fi lè gbà pé Ọlọ́run wà.
5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀kan lára ìdí tá a fi lè gbà pé Ọlọ́run wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí i. Ó sọ nípa Jèhófà pé: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Báwo lo ṣe lè ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà kó bàa lè rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ? O lè bá ẹni náà jíròrò díẹ̀ lára ohun tí ìṣẹ̀dá jẹ́ ká mọ̀ nípa agbára àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ lábẹ́ ìsọ̀rí méjì tó kàn.
ÌṢẸ̀DÁ JẸ́ KÁ MỌ̀ NÍPA AGBÁRA ỌLỌ́RUN
6, 7. Àwọn ohun méjì tó ń ṣíji bo ayé wo ló jẹ́ ká mọ̀ nípa agbára Jèhófà?
6 Àwọn ohun méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ká mọ̀ nípa agbára Jèhófà. Àwọn ohun méjì yìí ń ṣíji bo ayé, wọ́n sì ń dáàbò bò wá. Àwọn ohun méjì náà ni òfuurufú tó yí ayé ká àti agbára òòfà ilẹ̀ ayé. Bí àpẹẹrẹ, inú òfuurufú tó yí ayé ká ni afẹ́fẹ́ tá à ń mí símú ti ń wá, òun náà ló sì tún ń gba ọ̀pọ̀ ìdọ̀tí tó ń bọ̀ láti gbalasa òfuurufú sára kó má bàa gbẹ̀mí wa. Lára wọn ni àwọn òkúta rìbìtì-rìbìtì tí wọ́n lè fa jàǹbá ńláǹlà bí wọ́n bá bọ́ lu ayé wa. Àmọ́ ohun tí kì í jẹ́ kí wọ́n pa wá lára ni pé wọ́n máa ń gbiná bí wọ́n bá ti dé inú òfuurufú tó yí ayé ká. Lọ́wọ́ alẹ́, tí wọ́n bá ń já ṣòòròṣò gba ojú ọ̀run kọjá ńṣe ni wọ́n máa ń bù yẹ̀rì tí ìmọ́lẹ̀ wọn á sì tàn yòò. Ìmọ́lẹ̀ náà sì máa ń rẹwà gan-an.
7 Agbára òòfà ilẹ̀ ayé tún máa ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu. Àárín gbùngbùn òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé ni ohun tó ń pèsè agbára òòfà yìí wà. Ibi tó wà yìí jẹ́ kìkì irin yíyọ́ tó gbóná, bó sì ṣe ń yí níbẹ̀ ló ń mú agbára òòfà jáde. Kò sí ibi tí agbára òòfà yìí kì í dé lórí ilẹ̀ ayé, ó sì tún máa ń ràn dé gbalasa òfuurufú. Agbára òòfà yìí ló ń dàábò bò wá lọ́wọ́ àwọn ìtànṣán olóró tó máa ń wá látara oòrùn tó ń gbóná janjan àti àwọn nǹkan tó máa ń bú gbàù jáde látara oòrùn. Ọpẹ́lọpẹ́ agbára òòfà yìí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn nǹkan tó ń tú jáde yìí á ti pa gbogbo èèyàn, ẹranko, igi, ewéko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ńṣe ni agbára òòfà yìí máa ń gbà wọ́n sára tàbí kó darí wọn pa dà. Ọ̀kan lára ohun tó mú ká gbà pé agbára òòfà ilẹ̀ ayé wa ń ṣiṣẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ mèremère tó máa ń kọ yẹ̀rì lójú ọ̀run nítòsí ìpẹ̀kun Àríwá ilẹ̀ ayé àti ìpẹ̀kun Gúúsù ilẹ̀ ayé. Láìsí àní-àní, Jèhófà ní “okun inú nínú agbára.”—Ka Aísáyà 40:26.
ÌṢẸ̀DÁ JẸ́ KÁ MỌ̀ NÍPA ỌGBỌ́N ỌLỌ́RUN
8, 9. Kí ló mú ká lè máa wà láàyè nìṣó? Kí nìyẹn kọ́ wa nípa ọgbọ́n Ọlọ́run?
8 A tún lè rí nǹkan kọ́ nípa ọgbọ́n Jèhófà látinú ohun tó ṣe láti fi gbé ẹ̀mí wa ró ká lè máa wà láàyè nìṣó. Àpèjúwe kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé ò ń gbé nínú ìlú kan táwọn èèyàn kún inú rẹ̀ fọ́fọ́ tí wọ́n sì mọ ògiri yí ká. Kò sí báwọn tó ń gbé ibẹ̀ á ṣe máa pọn omi tó ṣeé mu wọnú ìlú náà, kò sì sí bí wọ́n á ṣe máa kó pàǹtírí dà nù. Ó dájú pé kò ní pẹ́ tí irú ìlú bẹ́ẹ̀ á fi kún fún ẹ̀gbin tí kò sì ní ṣeé gbé. Ńṣe ni ilẹ̀ ayé wa yìí náà dà bí ìlú tí wọ́n mọ ògiri yí ká yẹn.
Ìwọ̀nba ni omi tó ṣeé mu tó wà nínú ayé, a ò sì lè kó pàǹtírí tó wà láyé lọ sí ojúde òfuurufú. Àmọ́, ilẹ̀ ayé wa ń pèsè ohun tó ń gbé ẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, ẹranko, igi, ewéko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ró, láti ìran dé ìran. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀nà àgbàyanu kan wà tí ayé gbà ń ṣe àtúnlò gbogbo àwọn nǹkan tó lè mú ká máa wà láàyè nìṣó.9 Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa afẹ́fẹ́ ọ́síjìn (oxygen). Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, ẹranko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ló ń mí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn sínú tí wọ́n sì ń mí afẹ́fẹ́ carbon dioxide síta. Síbẹ̀, afẹ́fẹ́ ọ́síjìn kò tán rí, kò sì ṣẹlẹ̀ rí pé afẹ́fẹ́ carbon dioxide di pàǹtírí sínú àyíká wa. Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé tá a bá mí afẹ́fẹ́ carbon dioxide síta, àwọn ewéko á gbà á sára, wọ́n á wá dà á pọ̀ mọ́ omi, ìmọ́lẹ̀ oòrùn àtàwọn èròjà inú erùpẹ̀ láti fi mú àwọn èròjà carbohydrate àti afẹ́fẹ́ ọ́síjìn jáde. Ìṣètò àgbàyanu yìí ló ń jẹ́ photosynthesis. Ìgbà tá a bá mí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó jáde látara ewéko yìí sínú ni abala kan nínú ìṣètò tó máa ń lọ yí po yìí tó parí. Ó wá já sí pé Jèhófà ń lo àwọn ewéko tó dá láti fún “gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí.” (Ìṣe 17:25) Ọgbọ́n tó pabanbarì mà lèyí o!
10, 11. Kí la rí kọ́ nípa ọgbọ́n Jèhófà látinú ọ̀nà tó gbà dá labalábá tó máa ń ṣí kiri àti lámilámi?
10 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n Jèhófà látinú bí àwọn ohun alààyè tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé wa kíkàmàmà yìí ṣe pọ̀ yanturu. Ìwádìí fi hàn pé ọ̀kan-ò-jọ̀kan ohun alààyè tó tó mílíọ̀nù méjì sí ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ló wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ka Sáàmù 104:24.) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá díẹ̀ lára àwọn ohun alààyè yìí ká bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.
11 Bí àpẹẹrẹ, labalábá kan wà tó máa ń ṣí kiri, ọpọlọ rẹ̀ kò sì ju orí abẹ́rẹ́ lọ. Síbẹ̀, labalábá yìí lè ṣí kúrò ní orílẹ̀-èdè Kánádà, kó sì rìnrìn àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] kìlómítà lọ sínú igbó kan ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Bó ṣe ń lọ, ó máa ń tọpasẹ̀ oòrùn kó lè mọ ibi tó yẹ kó forí lé. Báwo ló ṣe máa ń mọ ibi tó yẹ kó gbà tí oòrùn bá yí sí apá ibòmíì lójú sánmà? Jèhófà dá ọpọlọ rẹ̀ kékeré lọ́nà tó fi lè máa ṣamọ̀nà rẹ̀ tí oòrùn bá yí síbòmíì. Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa kòkòrò kan tó ń jẹ́ lámilámi. Ó ní ojú kòǹgbàkòǹgbà méjì tó fi ń ríran. Awò tí ó tó ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] ló wà nínú ojú kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, bí ọpọlọ rẹ̀ ṣe kéré jọjọ tó yẹn, gbogbo ìsọfúnni tí àwọn awò yẹn bá gbé wá sínú ọpọlọ rẹ̀ máa ń yé e, ó sì máa ń mọ̀ bí ohun kan bá ṣèèṣì mira níbi tó wà.
12, 13. Kí ló wọ̀ ẹ́ lọ́kàn nípa bí Jèhófà ṣe dá àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara rẹ?
12 Èyí tó tún wá pabanbarì jù ni bí Jèhófà ṣe dá àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara gbogbo ẹ̀dá alààyè. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ sẹ́ẹ̀lì tíntìntín ló wà nínú ara rẹ. Ohun kan wà nínú sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan tó dà bí okùn tín-ín-rín tó ń jẹ́ DNA (deoxyribonucleic acid). Ibẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìsọfúnni tí Ọlọ́run fi dá ara rẹ wà.
13 Báwo ni ìsọfúnni tó wà nínú èròjà DNA ṣe pọ̀ tó? Ẹ jẹ́ ká fi ìsọfúnni tí fọ́nrán DNA kan tí kò gùn ju ìka ìlábẹ̀ lè gbà wé iye ìsọfúnni tá a lè kó sínú àwo CD kan. Àwo CD kan lè gba
gbogbo ìsọfúnni tó wà nínú ìwé atúmọ̀ èdè kan tàbí odindi Bíbélì. Ìyàlẹ́nu nìyẹn jẹ́ torí pé ike pẹlẹbẹ kan lásán ni àwo CD. Àmọ́, fọ́nrán DNA kan tí kò gùn ju ìka ìlábẹ̀ lè gba ìsọfúnni tó máa kún inú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ àwo CD! A sì tún lè wo ọ̀rọ̀ náà báyìí. Ìsọfúnni tó wà nínú fọ́nrán DNA kan tí kò gùn ju ìka ìlábẹ̀ tó láti ṣẹ̀dá gbogbo èèyàn tó wà láyé báyìí ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ [350]!14. Èrò wo ni ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe àwárí rẹ̀ mú kó o ní nípa Jèhófà?
14 Nígbà tí Dáfídì Ọba ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìsọfúnni tí Ọlọ́run nílò láti dá ara èèyàn, ó sọ pé ó kọ wọ́n sínú ìwé ìṣàpẹẹrẹ kan. Ó wá sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn, tí ìkankan lára wọn kò sì tíì sí.” (Sm. 139:16) Ó ṣe kedere pé bí Dáfídì ṣe ronú nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá a ló mú kó yin Jèhófà. Ńṣe ni ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàwárí rẹ̀ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí tún wá ń mú kí ẹnu túbọ̀ yà wá nígbà tá a bá ń ronú nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá wa. Àwọn ohun tí wọ́n ṣàwárí yìí túbọ̀ mú ká rí ìdí tá a fi ní láti gbà pẹ̀lú onísáàmù náà, ẹni tó sọ nípa Jèhófà pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” (Sm. 139:14) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo làwọn èèyàn ṣe máa ní àwọn ò rí i pé ìṣẹ̀dá ń jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run alààyè?
RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ FI ÒGO FÚN ỌLỌ́RUN ALÀÀYÈ
15, 16. (a) Báwo ni àwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe ń mú káwọn èèyàn mọyì Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá? (b) Èwo lo gbádùn jù lọ nínú àwọn àpilẹ̀kọ “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?”
15 Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni ìwé ìròyìn Jí! ti ran àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́wọ́ láti mọrírì ohun tí ìṣẹ̀dá jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run alààyè tó dá wa. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 2006, ìwé ìròyìn Jí! èdè Gẹ̀ẹ́sì, ti oṣù September, gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tó ní àkọlé náà, “Is There a Creator?” [Ǹjẹ́ Ẹnì Kan Wà Tó Jẹ́ Ẹlẹ́dàá?] * Gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn yẹn ló tú àṣírí irọ́ tó wà nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àtàwọn ẹ̀kọ́ èké mìíràn. Arábìnrin kan kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nípa ẹ̀dà Jí! àkànṣe náà pé: “Àwọn èèyàn gba àkànṣe ìwé ìròyìn yìí gan-an ni. Obìnrin kan béèrè fún ogún lára ìwé ìròyìn náà. Olùkọ́ tó ń kọ́ni nípa ohun alààyè ni obìnrin náà, ó sì fẹ́ kí àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ ní ẹ̀dà tiwọn.” Arákùnrin kan kọ̀wé pé: “Láti nǹkan bí ọdún 1946 ni mo ti ń lọ sóde ẹ̀rí, mo sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] báyìí, àmọ́ mi ò tíì gbádùn òde ẹ̀rí tó ti oṣù tá a pín àkànṣe ìwé ìròyìn Jí! yìí.”
16 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé ìròyìn Jí! [Gẹ̀ẹ́sì] ló ní àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” lédè Yorùbá. * Àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣe ṣókí yìí ṣàlàyé bí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe jẹ́ àgbàyanu tó àti bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ohun tí Àgbà Olùṣẹ̀dá náà dá ṣe àwòkọ́ṣe. A tún rí ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi ògo fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n mú ìwé Was Life Created? jáde ní ọdún 2010. Àwọn àwòrán mèremère wà nínú ìwé náà, wọ́n sì tún fi àwọn àtẹ ìsọfúnni tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ síbẹ̀ lọ́nà tó máa mú ká mọyì Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá. Àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí apá kọ̀ọ̀kan máa mú kí ẹni tó bá ka ìwé náà ronú lórí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán. Ṣé o gbádùn lílo ìwé náà nígbà tó ò ń wàásù láti ilé dé ilé, láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí àti nígbà tó ò ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà?
17, 18. (a) Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè mú kí àwọn ọmọ yín túbọ̀ ní ìgboyà táá jẹ́ kí wọ́n lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́? (b) Ọ̀nà wo lẹ ti gbà lo àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá yìí nínú Ìjọsìn Ìdílé yín?
17 Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ ti jíròrò ìwé aláwọ̀ mèremère yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín? Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò rẹ̀, ó máa jẹ́ káwọn ọmọ yín túbọ̀ Òwe 2:10, 11) Ó jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè pinnu bóyá ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn níléèwé bọ́gbọ́n mu tàbí kò bọ́gbọ́n mu.
mọrírì Ọlọ́run alààyè. Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ní àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún tí wọ́n ń lọ sí iléèwé girama. Irú wọn gan-an ni àwọn tó ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ èké ẹfolúṣọ̀n máa ń dìídì dójú sọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn olùkọ́, tó fi mọ́ àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n fi ń ṣàlàyé nípa ìṣẹ̀dá, àtàwọn fíìmù tá a fi ń najú, ló ń kọ́ni pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Ẹ lè ran àwọn ọmọ yín tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún lọ́wọ́ láti já àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ nípa lílo ìwé mìíràn, ìyẹn The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, tá a mú òun náà jáde ní ọdún 2010. Bíi ti ìwé Was Life Created?, ìwé yìí náà gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé kí wọ́n ní “agbára láti ronú.” (18 Nígbà míì, a lè gbọ́ nínú ìròyìn tó ṣeni ní kàyéfì pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe àwárí àwọn àkẹ̀kù egungun tó fi hàn pé òtítọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Tàbí ká gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ti rí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ la ti ara ẹranko jáde. Wọ́n sì tún lè sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fi ẹ̀rí hàn níbi ìwádìí wọn pé ìwàláàyè lè ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ láìsí ẹni tó dá a. A ṣe ìwé Origin of Life kó lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, kí àwọn fúnra wọn lè pinnu bóyá òótọ́ làwọn ìròyìn yìí tàbí irọ́. Bí ẹ̀yin òbí bá fi àwọn ìwé yìí kọ́ àwọn ọmọ yín, wọ́n á lè máa fìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá.—Ka 1 Pétérù 3:15.
19. Àǹfààní wo ni gbogbo wá ní?
19 Ètò Jèhófà máa ń ṣèwádìí dáadáa kí wọ́n tó ṣe ìwé jáde. Tá a bá ń kà nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá nínú àwọn ìwé yìí, a máa rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nípa àwọn ànímọ́ tó dára tí Jèhófà ní. Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá yìí jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé òótọ́ ni Ẹlẹ́dàá wà, wọ́n sì máa ń mú kó wù wá láti fìyìn fún Ọlọ́run wa. (Sm. 19:1, 2) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa fún Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, ní ọlá àti ògo tó tọ́ sí i ní gbogbo ọ̀nà!—1 Tím. 1:17.
^ ìpínrọ̀ 3 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú ẹni tó gbà pé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni ọjọ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ọlọ́run fi dá gbogbo nǹkan, wo ojú ìwé 24 sí 28 nínú ìwé Was Life Created?
^ ìpínrọ̀ 15 Nínú Jí! Yorùbá ti oṣù October–December 2006, tó jẹ́ ìtẹ̀jáde ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù mẹ́ta, a gbé mẹ́ta jáde lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú àkànṣe ìwé ìròyìn yìí. Àwọn ni: “Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ta Ko Àkọsílẹ̀ Inú Jẹ́nẹ́sísì?,” “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?,” àti “Ṣé Ohun Tó Bá Wù Ọ́ Lo Lè Gbà Gbọ́?”
^ ìpínrọ̀ 16 A bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde lédè Yorùbá nínú Jí! ti January–February 2013, tó jẹ́ ìtẹ̀jáde ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù méjì.