Ọgọ́rùn-ún Ọdún Ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, Báwo Ló Ṣe Kàn Ọ́?
“Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, . . . Ọba ayérayé.”—ÌṢÍ. 15:3.
1, 2. Kí ni Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe? Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Ìjọba náà máa dé?
NÍGBÀ tí Jésù Kristi wà lórí òkè kan nítòsí Kápánáúmù nígbà ìrúwé ọdún 31 Sànmánì Kristẹni, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mát. 6:10) Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Ìjọba náà máa dé. Àmọ́, ó dá àwa lójú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà tá à ń gbà tọkàntọkàn pé kí Ìjọba rẹ̀ dé.
2 Jèhófà máa lo Ìjọba náà láti mú kí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé wà ní ìṣọ̀kan. Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe yìí máa ní ìmúṣẹ. (Aísá. 55:10, 11) Kódà, Jèhófà ti di Ọba lákòókò tá à ń gbé yìí! Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alárinrin tó wáyé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó ti kọjá fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ọlọ́run ń ṣe àwọn iṣẹ́ ńláǹlà àtàwọn iṣẹ́ àgbàyanu nítorí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí wọ́n jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin. (Sek. 14:9; Ìṣí. 15:3) Síbẹ̀, ti pé Jèhófà di Ọba yàtọ̀ sí Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀, èyí tí Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún. Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú méjèèjì, báwo ni wọ́n sì ṣe kàn wá?
ỌBA TÍ JÈHÓFÀ GBÉ GORÍ ÌTẸ́ BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́
3. (a) Ìgbà wo ni Ọlọ́run gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba, ibo sì ni ìtẹ́ rẹ̀ wà? (b) Kí ni ẹ̀rí tó fi hàn pé ọdún 1914 ni Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
3 Bí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ti ń parí lọ, ìmọ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn sórí àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Dáníẹ́lì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ọdún sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.” (Dán. 2:44) Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti fi ń ṣàlàyé pé mánigbàgbé ni ọdún 1914 máa jẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà láyé nígbà yẹn ni wọ́n gbà pé nǹkan á ṣẹnuure. Òǹkọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé: “A retí pé àwọn nǹkan á dára lọ́dún 1914.” Àmọ́ nígbà tó kù díẹ̀ kí ọdún yẹn parí, Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀, èyí tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn tó tẹ̀ lé e, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì tó ní ìmúṣẹ jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Jésù Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914. * Bí Jèhófà ṣe gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba fi hàn dájúdájú pé Jèhófà ti di Ọba ní ọ̀nà mìíràn kan tó yàtọ̀!
4. Kí ni Ọba tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́ náà ṣe ní gbàrà tó di ọba? Lẹ́yìn náà, àwọn wo ló wá yí àfiyèsí rẹ̀ sí?
4 Iṣẹ́ tí Ọba tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́ yìí kọ́kọ́ ṣe ni pé ó bá Sátánì tó jẹ́ olórí Elénìní Baba rẹ̀ jagun. Jésù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lé Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Èyí mú káwọn tó wà lọ́run kún fún ayọ̀. Àmọ́, àkókò ìyọnu àjálù tí a kò rí irú rẹ̀ rí ló jẹ́ fún ilẹ̀ ayé. (Ka Ìṣípayá 12:7-9, 12.) Lẹ́yìn náà ni Ọba yìí wá yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn kó bàa lè yọ́ wọn mọ́, kó kọ́ wọn, kó sì ṣètò wọn kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀nà tí wọ́n gbà fara mọ́ àwọn ohun mẹ́ta tí ìṣàkóso Ọlọ́run ń ṣe yìí ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lónìí.
MÈSÁYÀ ỌBA YỌ́ ÀWỌN ỌMỌ ABẸ́ RẸ̀ ADÚRÓṢINṢIN MỌ́
5. Ìfọ̀mọ́ wo ló wáyé láàárín ọdún 1914 sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919?
5 Lẹ́yìn tí Ọba tí Ọlọ́run gbé gorí ìtẹ́ náà ti fọ ọ̀run mọ́ nípa lílé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, Jèhófà darí Jésù láti ṣàyẹ̀wò ipò tẹ̀mí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé kó sì yọ́ wọn mọ́. Èyí ni wòlíì Málákì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìfọ̀mọ́ tẹ̀mí. (Mál. 3:1-3) Ìtàn fi hàn pé èyí wáyé láàárín ọdún 1914 sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919. * Ká tó lè di ara ìdílé Jèhófà, a gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní tàbí ká jẹ́ mímọ́. (1 Pét. 1:15, 16) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìsìn èké tàbí òṣèlú ayé yìí kó àbààwọ́n bá wa lọ́nàkọnà.
6. Báwo la ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà? Kí nìdí tí oúnjẹ tẹ̀mí náà fi ṣe pàtàkì?
6 Jésù wá lo àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí ọba láti yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ó yan ẹrú yìí láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó gbámúṣé déédéé fún gbogbo àwọn tó para pọ̀ di “agbo kan” lábẹ́ àbójútó Jésù. (Mát. 24:45-47; Jòh. 10:16) Látọdún 1919 ni ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró ti ń bọ́ “àwọn ará ilé” Jésù láìdáwọ́ dúró. Ó dájú pé iṣẹ́ bàǹtàbanta lèyí jẹ́! Ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú yìí ń pèsè ń fún wa lókun kí ìgbàgbọ́ wa lè máa lágbára sí i. Oúnjẹ tẹ̀mí náà ń jẹ́ ká lè mú ìpinnu wa ṣẹ pé a máa jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí, nínú ìwà, nínú èrò àti nípa tara. Ó tún ń jẹ́ ka mọ bá a ṣe lè máa kópa kíkún nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí, ó sì tún ń mú ká gbára dì fún iṣẹ́ náà. Ṣé ò ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí yìí kó o lè jàǹfààní kíkún látinú rẹ̀?
ỌBA NÁÀ Ń KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ ABẸ́ RẸ̀ LÁTI WÀÁSÙ KÁRÍ AYÉ
7. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jésù bẹ̀rẹ̀ nígbà tó wà láyé? Títí dìgbà wo ni iṣẹ́ náà á fi máa bá a nìṣó?
7 Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi.” (Lúùkù 4:43) Fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀, iṣẹ́ yìí gan-an ni Jésù gbájú mọ́. Ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mát. 10:7) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa wàásù “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ó ṣèlérí fún wọn pé òun kò ní dá wọn dá iṣẹ́ náà rárá, òun máa tì wọ́n lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ pàtàkì náà títí di àkókò tiwa yìí.—Mát. 28:19, 20.
8. Kí ni Ọba náà ṣe tó fi ta àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ jí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà?
8 Nígbà tó fi máa di ọdún 1919, “ìhìn rere ìjọba” náà túbọ̀ wá ṣe kedere. (Mát. 24:14) Ọ̀run ni Ọba náà ti ń ṣàkóso, àmọ́ ó ti kó àwọn èèyàn kéréje tó ti fọ̀ mọ́ jọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fi ta wọ́n jí pé: Ẹ wàásù ìhìn rere Ìjọba tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ kárí ayé! (Ìṣe 10:42) Bí àpẹẹrẹ, ó tó ọ̀kẹ́ kan [20,000] lára àwọn tó fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run yìí tí wọ́n pé jọ sí àpéjọ àgbáyé tó wáyé nílùú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní oṣù September, ọdún 1922. Ẹ sì wo bí ara wọn ṣe yá gágá tó nígbà tí Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “Ìjọba Náà,” tó sì polongo pé: “Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn ló dáhùn sí ìpè pàtàkì yìí ní ti pé wọ́n lọ́wọ́ sí àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n pè ní “Ọjọ́ Iṣẹ́ Ìsìn.” Wọ́n wàásù títí dé àwọn ilé tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà méjìléláàádọ́rin [72] síbi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà. Ọ̀kan lára àwọn tó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ọjọ́ yẹn sọ pé: “Mi ò jẹ́ gbàgbé bí wọ́n ṣe sọ fún wa pé ká polongo Ìjọba náà àti ìtara tí ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wà ní àpéjọ náà fi hàn!” Èrò àwọn míì tó wà ní àpéjọ náà jọ ti arákùnrin yìí.
9, 10. (a) Ètò wo ni Jésù ṣe láti dá àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́? (b) Ọ̀nà wo ni ìwọ alára ti gbà jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí?
9 Nígbà tó fi máa di ọdún 1922, ó ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] èèyàn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé, wọ́n sì ti dé orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gọ́ta [58]. Àmọ́, wọ́n nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ní ọ̀rúndún kìíní, Ọba Lọ́la náà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa ohun tí wọ́n máa wàásù, ibi tí wọ́n ti máa wàásù àti bí wọ́n ṣe máa wàásù. (Mát. 10:5-7; Lúùkù 9:1-6; 10:1-11) Ohun kan náà ni Jésù ń ṣe lónìí. Ó rí i dájú pé gbogbo àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà gba àwọn ìtọ́ni tí wọ́n nílò, wọ́n sì ní àwọn ohun èlò tí wọ́n á fi máa wàásù lọ́nà tó múná dóko. (2 Tím. 3:17) Ìjọ Kristẹni ni Jésù ń lò láti máa dá àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ọ̀nà kan tó ń gbà kọ́ wọn jẹ́ nípasẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tá à ń ṣe ní àwọn ìjọ tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́fà [111,000] kárí ayé. Àwọn oníwàásù tó ju mílíọ̀nù méje lọ ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, wọ́n sì ti wá kúnjú ìwọ̀n láti wàásù kí wọ́n sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí á fi wọ “ènìyàn gbogbo” lọ́kàn.—Ka 1 Kọ́ríńtì 9:20-23.
10 Ní àfikún sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ètò Ọlọ́run ti dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì mìíràn sílẹ̀ láti pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn alàgbà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà, àwọn àpọ́n, àwọn tọkọtaya, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àtàwọn ìyàwó wọn, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn àti àwọn míṣọ́nnárì. * Nígbà tí ẹnì kan tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya ń ṣàlàyé bó ṣe mọrírì ilé ẹ̀kọ́ náà tó, ó sọ pé: “Àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a rí gbà yìí mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà jinlẹ̀ sí i, ó sì ti mú ká gbára dì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.”
11. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣenúnibíni sí àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run, kí ló mú kí wọ́n lè máa fara dà á?
11 Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá wa ń kíyè sí bí iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń gbilẹ̀. Ó ń wá bó ṣe máa dá iṣẹ́ náà dúró. Torí náà, yálà ní tààràtà tàbí lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ó ń tako ìhìn Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀, ó sì tún ń gbéjà ko àwa fúnra wa. Àmọ́, pàbó ni gbogbo ìsapá ọ̀tá yìí ń já sí. Jèhófà ti gbé ọmọ rẹ̀ ga “ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa.” (Éfé. 1:20-22) Torí pé Jésù ti di ọba, ó ń lo ọlá àṣẹ rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń tọ́ wọn sọ́nà kó lè rí i dájú pé ìfẹ́ Baba òun di ṣíṣe. * À ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, a sì ń kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó fẹ́ mọ òtítọ́ ní àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa pé à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ńlá yìí!
ỌBA NÁÀ ṢÈTÒ ÀWỌN ỌMỌ ABẸ́ ÌJỌBA RẸ̀ LÁTI ṢE IṢẸ́ BÀǸTÀBANTA
12. Sọ díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tó ti wáyé nínú bá a ṣe ń ṣètò àwọn nǹkan látìgbà tí Ọlọ́run ti gbé Ìjọba náà kalẹ̀.
12 Látìgbà tí Ọlọ́run ti gbé Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́dún 1914 ni Ọba Ìjọba náà ti ṣètò àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Ka Aísáyà 60:17.) Lọ́dún 1919, ètò Ọlọ́run yan olùdarí iṣẹ́ ìsìn sípò nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan kó lè máa múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Lọ́dún 1927, ètò Ọlọ́run tún ṣètò pé káwọn ará máa wàásù láti ilé dé ilé láwọn ọjọ́ Sunday. Gbogbo àwọn tó jẹ́ alátìlẹyìn Ìjọba náà gba orúkọ tó bá Ìwé Mímọ́ mu náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọ́dún 1931, ìyẹn sì mú kí wọ́n fẹ́ láti fi kún ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Aísá. 43:10-12) Nígbà tó di ọdún 1938, a ò dìbò yan àwọn ọkùnrin tó tóótun nínú ìjọ sípò mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe là ń yàn wọ́n sípò lọ́nà tó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Lọ́dún 1972, wọ́n ní kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa bójú tó ìjọ dípò ẹnì kan ṣoṣo tó ń bójú tó ìjọ tẹ́lẹ̀. Gbogbo àwọn tó tóótun la rọ̀ láti fi kún ìsapá wọ́n, kí wọ́n lè máa ṣe ‘olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà lábẹ́ àbójútó wọn.’ (1 Pét. 5:2) Lọ́dún 1976, a ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí sí ìgbìmọ̀ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó ń lọ kárí ayé. Ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà pé, Ọba tí Jèhófà yàn sípò ti ṣètò àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lọ́nà tó bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run mu.
13. Ipa wo ni ohun tí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún yìí ti ní lórí ìgbésí ayé rẹ?
13 Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Mèsáyà Ọba ti ṣe àṣeyọrí rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún àkọ́kọ́ tó ti ń ṣàkóso yẹ̀ wò. Ó ti sọ àwọn èèyàn kan di mímọ́ fún orúkọ Jèhófà. Ó ti darí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní igba ilẹ̀ ó lé mọ́kàndínlógójì [239], ó sì ti kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn láti máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó ti mú kí àwọn adúróṣinṣin tó jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù méje wà ní ìṣọ̀kan. Gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló sì ń fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Sm. 110:3) Ó dájú pé ohun ńlá àtohun àgbàyanu ni Jèhófà ń ṣe nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì ń bọ̀ wá ṣe lọ́jọ́ iwájú!
ÀWỌN ÌBÙKÚN TÁ A MÁA GBÁDÙN LÁBẸ́ ÌJỌBA MÈSÁYÀ
14. (a) Kí là ń sọ pé kí Ọlọ́run ṣe tá a bá gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé”? (b) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2014, kí sì nìdí tó fi bá a mu?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gbé Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba lọ́dún 1914, èyí kì í ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn sí àdúrà tá à ń gbà sí Ọlọ́run pé, “kí ìjọba rẹ dé.” (Mát. 6:10) Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Jésù yóò “máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá [rẹ̀].” (Sm. 110:2) Àwọn ìjọba èèyàn tí Sátánì ń ṣàkóso lé lórí ṣì ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, tá a bá ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ńṣe là ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí Mèsáyà Ọba àtàwọn tó ń ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ wá fi òpin sí ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn kí wọ́n sì mú àwọn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ìgbà yẹn ni ọ̀rọ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì 2:44 máa ṣẹ, èyí tó sọ pé Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” Ó máa rẹ́yìn àwọn olóṣèlú tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ìjọba náà. (Ìṣí. 6:1, 2; 13:1-18; 19:11-21) Àkókò tí èyí máa ṣẹlẹ̀ ti sún mọ́lé. Ẹ wo bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2014 ṣe bá a mu wẹ́kú tó! A mú un látinú Mátíù 6:10 tó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé”! Ọdún yìí ló sì pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀run!
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2014: “Kí Ìjọba rẹ dé.”—Mátíù 6:10
15, 16. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá wo ló máa wáyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi? (b) Kí ni Jésù máa ṣe gbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba, báwo sì nìyẹn ṣe máa mú ète Jèhófà fún gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ ṣẹ?
15 Lẹ́yìn tí Mèsáyà Ọba bá ti pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run, ó máa ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Ìṣí. 20:1-3) Bí àwọn aṣebi náà bá ti kúrò, Ìjọba Ọlọ́run á wá mú ká jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù, á sì mú ká bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ti fà. Lẹ́yìn náà, Mèsáyà Ọba máa jí àwọn èèyàn tí kò lóǹkà tí wọ́n ń sùn nínú ibojì dìde, ó sì máa ṣètò iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tó kárí ayé, kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Ìṣí. 20:12, 13) Gbogbo ilẹ̀ ayé pátá á wá di Párádísè bíi ti ọgbà Édẹ́nì. Gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin la ó sọ di pípé.
16 Ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Ìjọba Mèsáyà á ti ṣe ohun tí Ọlọ́run torí rẹ̀ gbé e kalẹ̀ láṣeyọrí. Lẹ́yìn yẹn ni Jésù á wá dá Ìjọba náà pa dà fún Baba rẹ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:24-28.) Kò wá ní sí ìdí fún alárinà láàárín Jèhófà àtàwọn ọmọ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ará ìdílé rẹ̀ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, á wá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba wọn ọ̀run.
17. Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti gbọ́ nípa Ìjọba náà, kí lo pinnu láti ṣe?
17 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá tó ti wáyé láti ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso mú kó dá wa lójú pé ọwọ́ Jèhófà ṣì ni agbára ìṣàkóso wà àti pé ète rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé máa ṣẹ. Ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run láìyẹsẹ̀, ká sì máa polongo Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀. À ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ó dá wa lójú pé Jèhófà kò ní pẹ́ dáhùn àdúrà àtọkànwá tá à ń gbà pé: “Kí ìjọba rẹ dé”!
^ ìpínrọ̀ 5 Wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013, ojú ìwé 22 àti 23, ìpínrọ̀ 12.
^ ìpínrọ̀ 10 Wo Ilé Ìṣọ́ September 15, 2012, ojú ìwé 13 sí 17, tó ní àkọlé náà, “Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa.”
^ ìpínrọ̀ 11 Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ẹjọ́ tí wọ́n ti dá wa láre ní onírúurú orílẹ̀-èdè, wo Ilé Ìṣọ́ December 1, 1998, ojú ìwé 19 sí 22.