Nípa Ìrètí Tó Wà Fáwọn Òkú
Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Nípa Ìrètí Tó Wà Fáwọn Òkú
Ó kéré tán, Jésù jí àwọn mẹ́ta dìde, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ìrètí wà fáwọn òkú. (Lúùkù 7:11-17; 8:49-56; Jòhánù 11:1-45) Ká tó lè mọ ìrètí tó wà fáwọn òkú, a ní láti kọ́kọ́ mọ ohun tó fa ikú àti ibi tó ti bẹ̀rẹ̀.
Kí Nìdí Tá A Fi Ń Ṣàìsàn Tá A sì Ń Kú?
Nígbà tí Jésù dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, ara wọn yá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n gbé ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà kan wá sọ́dọ̀ Jésù, Jésù sọ pé: “‘Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì, tàbí láti sọ pé, Dìde kí o sì máa rìn? Bí ó ti wù kí ó rí, kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ ènìyàn ní ọlá àṣẹ ní ilẹ̀ ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—’ nígbà náà ni ó sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé rẹ.’” (Mátíù 9:2-6) Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fa àìsàn àti ikú. Ọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ la sì ti jogún ẹ̀ṣẹ̀.—Lúùkù 3:38; Róòmù 5:12.
Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?
Jésù ò dẹ́ṣẹ̀ rí. Torí náà, kò yẹ kó kú. Àmọ́ ó kú kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe pàṣípààrọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó sọ pé ẹ̀jẹ̀ òun “tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn [máa jẹ́] fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Mátíù 26:28.
Jésù tún sọ pé: “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Jésù pe ẹ̀mí rẹ̀ tó fi lélẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní “ìràpadà,” torí ó ra àwọn èèyàn pa dà kúrò nínú òkú. Jésù tún sọ pé: “Èmi ti wá kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ yanturu.” (Jòhánù 10:10) Àmọ́ kí ìrètí tó wà fáwọn òkú tó lè yé wa dáadáa, a ní láti mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá kú.
Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Nígbà Tí Wọ́n Bá Kú?
Nígbà tí Lásárù, ọ̀rẹ́ Jésù kú, Jésù ṣàpèjúwe ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá kú fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “‘Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí [Bẹ́tánì] láti jí i kúrò lójú oorun.‘ . . . Ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun. Nítorí náà, ní àkókò yẹn, Jésù wí fún wọn láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ pé: ‘Lásárù ti kú.’” Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń sùn.—Jòhánù 11:1-14.
Ọ̀rẹ́ Jésù tó ń jẹ́ Lásárù ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin kó tó jí i dìde. Síbẹ̀, Bíbélì ò sọ pé Lásárù sọ ohunkóhun nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó kú. Nígbà tí Lásárù kú, kò mọ ohunkóhun.—Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 11:17-44.
Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Òkú?
Àwọn òkú máa pa dà wà láàyè, wọ́n sì máa gbé láyé títí láé. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.
Ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni. Jésù sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16; Ìṣípayá 21:4, 5.
Fún àlàyé síwájú sí i, wo orí 6 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.