Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Fi Tọ̀yàyàtọ̀yàyà Pè Ẹ́

A Fi Tọ̀yàyàtọ̀yàyà Pè Ẹ́

A Fi Tọ̀yàyàtọ̀yàyà Pè Ẹ́

Ó ṢEÉ ṢE kó o ti gbawájú Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò ẹ kọjá rí, kó o sì máa ronú pé kí là ń ṣe níbẹ̀. Ṣó o tiẹ̀ mọ̀ pé kò sẹ́ni tí kò lè wá sáwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Tọ̀yàyàtọ̀yàyà la fi pe gbogbo àwọn àlejò tó bá fẹ́ wá.

Àmọ́, ó ṣeé ṣe káwọn ìbéèrè kan ti máa jà gùdù lọ́kàn ẹ. O lè máa ronú pé kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń ṣèpàdé? Kí la máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa? Kí sì làwọn àlejò tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sọ nípa àwọn ìpàdé wọ̀nyí?

“Pe Àwọn Ènìyàn Náà Jọpọ̀”

Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń pé jọ pọ̀ láti jọ́sìn kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn, Mósè sọ fáwọn àgbààgbà ní Ísírẹ́lì pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àtìpó tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ, kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe.” (Diutarónómì 31:12) Torí náà ní Ísírẹ́lì, tọmọdé tàgbà ló kọ́ bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run àti bí wọ́n á ṣe máa ṣègbọràn sí i.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, nígbà táwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni dá ìjọ sílẹ̀, pípàdé pọ̀ jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn tòótọ́ tí wọ́n ń ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe iṣẹ́ rere. Ẹ má jẹ́ kí a máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn miran, ṣùgbọ́n kí a máa gba ara wa níyànjú.” (Hébérù 10:24, 25, Ìròhìn Ayọ̀) Bó ṣe jẹ́ pé bí Bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ bá ń ṣe nǹkan pa pọ̀, wọ́n lè túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan,bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Kristẹni ṣe máa lágbára sí i tí wọ́n bá ń pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run.

Níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèpàdé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Àwọn ìpàdé wọ̀nyí máa ń ran àwọn tó bá wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n lóye báwọn ìlànà náà ti ṣe pàtàkì tó, kí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi wọ́n ṣèwà hù. Kárí ayé, ohun kan náà la máa ń ṣe láwọn ìpàdé wọ̀nyí, àyàfi láwọn ibi tí kò bá ti ṣeé ṣe. Ìpàdé kọ̀ọ̀kan ló sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọsìn Ọlọ́run. Ká tó bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àti lẹ́yìn típàdé bá parí, àwọn tó wá sípàdé sábà máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró kí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” lè wà. (Róòmù 1:12) Kí la máa ń ṣe ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpàdé wọ̀nyí?

Àsọyé Bíbélì

Ìpàdé tọ́pọ̀ èèyàn kọ́kọ́ máa ń wá ni àsọyé Bíbélì fún gbogbo ènìyàn, tá a sábà máa ń ṣe lópin ọ̀sẹ̀. Jésù Kristi sábà máa ń sọ àsọyé fáwọn èèyàn, ọ̀kan lára àwọn àsọyé ọ̀hún lèyí tó sọ lórí òkè, tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Orí Òkè. (Mátíù 5:1; 7:28, 29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà bá àwọn ará Áténì sọ̀rọ̀. (Ìṣe 17: 22-34) Bíi tàwọn àsọyé tí Jésù àti Pọ́ọ̀lù sọ, àsọyé fún gbogbo èèyàn wà lára àwọn ìpàdé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìpàdé yìí làwọn kan máa kọ́kọ́ wá.

Orin tó wà nínú ìwé Kọrin Ìyìn sí Jehofah a la máa fi ń bẹ̀rẹ̀ àsọyé Bíbélì. Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ dìde dúró láti kọ orin yìí ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tá a bá kọrin tán, a máa ń gbàdúrà ṣókí, olùbánisọ̀rọ̀ tó lóye Bíbélì dáadáa á sì wá sọ àsọyé fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. (Wo àpótí tá a pé àkọlé ẹ̀ ní  “Àwọn Àsọyé Tó Wúlò fún Gbogbo Èèyàn.”) Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì ni àsọyé yìí máa ń dá lé. Lóòrèkóòrè ni olùbánisọ̀rọ̀ náà á máa rọ àwọn olùgbọ́ pé kí wọ́n ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ mu, á sì ní kí wọ́n máa fojú bá a lọ nínú Bíbélì tiwọn bóun ṣe ń kà á. Torí náà, o lè gbé Bíbélì tiẹ̀ náà dání, o sì lè ní kí ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ẹ ní Bíbélì kan kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́

Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn lẹ́yìn tá a bá gbọ́ àsọyé Bíbélì tán. Wákàtí kan la fi máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, ìjíròrò náà sì máa ń dá lórí àkòrí ọ̀rọ̀ kan látinú Bíbélì. Ìpàdé yìí máa ń ran àwọn tó bá wá lọ́wọ́ láti ṣe bíi tàwọn ará Bèróà, nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n [sì] ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́.”—Ìṣe 17:11.

Orin la máa fi ń bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àwọn ìsọfúnni àtàwọn ìbéèrè tẹ́ni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa bi àwùjọ sì ti wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. O lè gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lára àwọn àkòrí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn ni: “Ẹ̀yin Òbí Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́,” “Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi Fún Ẹnì Kankan” àti “Ìdí Tí Kò fi Ní Pẹ́ Tí Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe lẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á máa béèrè àwọn ìbéèrè táwọn tó jókòó á sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè náà, kò sẹ́ni tí kò lè nawọ́ láti dáhùn ìbéèrè, tónítọ̀hún bá ṣáà ti ka àpilẹ̀kọ náà àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ẹ̀ tẹ́lẹ̀, tó sì ti ronú lórí àwọn ohun tó kà dáadáa. Orin àti àdúrà la fi máa ń parí ìpàdé yìí.—Mátíù 26:30; Éfésù 5:19.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lọ́sẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ṣe ìpàdé alápá mẹ́ta kan tá a máa ń ṣe fún wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45]. Apá àkọ́kọ́ ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, tá a máa ń ṣe fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Ìpàdé yìí máa ń jẹ́ káwọn tó bá wá túbọ̀ mọ Bíbélì dunjú, kí wọ́n mú ìrònú àti ìwà wọn bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu, kí wọ́n sì túbọ̀ máa ṣe dáadáa sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi. (2 Tímótì 3:16, 17) Bíi ti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá a sọ lẹ́ẹ̀kan, a máa ń jíròrò àkòrí kan tó dá lórí Bíbélì nínú ìpàdé yìí lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. A kì í fipá mú àwọn èèyàn láti dáhùn ìbéèrè. Àwọn ìwé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tó dá lórí Bíbélì la sábà máa ń jíròrò nínú ìpàdé náà.

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì la máa ń jíròrò nípàdé yìí? Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ò tó. “Wọ́n [máa] ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.” (Nehemáyà 8:8) Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ìwé tó ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà, Dáníẹ́lì àti Ìṣípayá ti ran àwọn tó ń wá sípàdé yìí lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìwé inú Bíbélì yìí dáadáa.

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Lẹ́yìn tá a bá parí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ la máa ń ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìpàdé tá a máa ń ṣe fún ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú yìí máa ń ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti ní “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” (2 Tímótì 4:2) Bí àpẹẹrẹ, ṣé ọmọ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ ti bi ẹ́ ní ìbéèrè kan nípa Ọlọ́run tàbí Bíbélì àmọ́ tó ò mọ ìdáhùn tó tọ̀nà sí ìbéèrè yẹn? Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó díjú lọ́nà tó bá Bíbélì mu tí wàá sì gba onítọ̀hún níyànjú. Torí náà, àwa náà lè sọ bíi ti wòlíì Aísáyà pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.”—Aísáyà 50:4.

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọyé tó dá lórí àwọn orí mélòó kan nínú Bíbélì tí wọ́n ti sọ lọ́sẹ̀ tó ṣáájú pé káwọn èèyàn kà wá. Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ tá a yan iṣẹ́ yẹn fún bá ti sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mélòó kan, ó máa wá ní káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn kókó tó ṣe wọ́n láǹfààní nínú àwọn orí Bíbélì wọ̀nyẹn. Lẹ́yìn ìjíròrò yìí làwọn tó ti forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí tá a sì ti yanṣẹ́ fún máa wa ṣe iṣẹ́ tá a ti yàn fún wọn.

Lára àwọn iṣẹ́ tá a máa ń yàn fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí ni kíka àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan látorí pèpéle tàbí ṣíṣe àṣefihàn béèyàn ṣe lè kọ́ ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, agbaninímọ̀ràn tó dáńgájíá máa ń gbóríyìn fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó bá sọ̀rọ̀ lórí pèpéle, inú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ló sì ti máa mú ìmọ̀ràn tó máa fún wọn. Lẹ́yìn ìpàdé náà, ó lè gbà wọ́n nímọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe lè ṣe dáadáa sí i lọ́jọ́ iwájú.

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run kì í gba àkókò, ó sì máa ń ran àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn tó wà nípàdé náà lọ́wọ́ láti mọ̀wé kà dáadáa, kí wọ́n di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáǹtọ́ àti olùkọ́ tó dáńgájíá. Lẹ́yìn tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá ti parí, a máa ń kọrin kan tó dá lórí Bíbélì láti fi ṣí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ni ìpàdé tó kẹ́yìn tá a máa ń ṣe lọ́jọ́ kan náà. Àsọyé, àṣefihàn, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti báwọn tó wà nípàdé yìí ṣe máa ń dáhùn ìbéèrè máa ń ran àwọn tó bá wá lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè fi òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó gbéṣẹ́. Kí Jésù tó rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jáde láti lọ wàásù, ó pè wọ́n pa pọ̀, ó sì fún wọn láwọn ìtọ́ni. (Lúùkù 10:1-16) Àwọn ìtọ́ni wọ̀nyẹn mú kí wọ́n gbára dì láti wàásù, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n láwọn ìrírí tó múnú wọn dùn. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, wọ́n ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù. (Lúùkù 10:17) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyí tún máa ń sọ àwọn ìrírí yìí fún ara wọn.—Ìṣe 4:23; 15:4.

Àwọn nǹkan tá a máa ń ṣé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ìṣẹ́jú márùndínlógójì [35] ti máa ń wà nínú ìwé ìléwọ́ tá à ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, oṣooṣù la sì máa ń tẹ̀ ẹ́. Díẹ̀ lára àwọn àkòrí tá a jíròrò láìpẹ́ yìí ni: “Bí Ìdílé Ṣe Lè Jọ Máa Sin Jèhófà,” “Ìdí Tá A Fi Ń Padà Lọ Léraléra” àti “Máa Tẹ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Rẹ.” Orin la fi máa ń parí ìpàdé náà, a sì máa ń yan ẹnì kan nínú ìjọ láti gbàdúrà ìparí.

Ohun Táwọn Àlejò Sọ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti jẹ́ kára àwọn àlejò silé. Bí àpẹẹrẹ, Andrew ti gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, lọ́jọ́ tó kọ́kọ́ wá sípàdé wa, báwọn ará wa ṣe yẹ́ ẹ sí yà á lẹ́nu gan-an. Andrew sọ pé: “Ọ̀kan lára ibi tó túùyàn lára tó yẹ́ kéèyàn máa lọ ni. Báwọn èèyàn wọ̀nyẹn ṣe yẹ́ mi sí, tí wọ́n kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà tí wọ́n sì jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn fẹ́ràn mi, jọ mí lójú gan-an.” Ashel, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé kò sírọ́ ńbẹ̀, ó ní: “Ìpàdé wọn ti lọ wà jù! Ó rọrùn láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ.”

Àwọn èèyàn ti mọ José tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sí oníwà ìpáǹle. Síbẹ̀, àwọn ará wa pè é pé kó wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò ẹ̀. Ó ní: “Tọ̀yàyàtọ̀yàyà làwọn tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba fi kí mi káàbọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ irú èèyàn tí mo jẹ́.” Atsushi tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan, sọ pé: “Kí n má parọ́, ara mi ò balẹ̀ lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ìgbà tó yá ni mo wá rí i pé èèyàn dáadáa ni wọ́n. Wọ́n gbìyànjú gan-an láti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.”

A Fi Tọ̀yàyàtọ̀yàyà Pè Ẹ́

Àwọn ọ̀rọ̀ táwọn tó ti wá sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa sọ jẹ́ ká mọ̀ pé wàá jàǹfààní gidi gan-an tó o bá wá sáwọn ìpàdé wọ̀nyí. Wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, Jèhófà Ọlọ́run sì máa kọ́ ẹ láwọn nǹkan tó o lè ṣe láti ṣe “ara rẹ láǹfààní” nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì.—Aísáyà 48:17.

Ọ̀fẹ́ nìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a kì í gbégbá owó níbẹ̀. Ṣé wàá fẹ́ lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò ẹ? A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà pè ẹ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe gbogbo ìwé tá a dárúkọ nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

 Àwọn Àsọyé Tó Wúlò fún Gbogbo Èèyàn

Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan àti àádọ́rin [170] àwọn àkòrí Ìwé Mímọ́ la máa fi ń sọ àsọyé Bíbélì fún gbogbo ènìyàn. Díẹ̀ lára àwọn àkòrí náà nìyí:

◼ Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ènìyàn—Ṣé Ohun Tó Bá Wù Ọ Lo Lè Gbà Gbọ́ Nípa Rẹ̀?

◼ Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ìbálòpọ̀ àti Ìgbéyàwó

◼ Pípa Ilẹ̀ Ayé Run Ń Mú Ẹ̀san Àtọ̀runwá Wá

◼ Kíkojú Àníyàn Ìgbésí Ayé

◼ Ìgbésí Ayé Yìí Ha Ni Gbogbo Ohun Tí Ó Wà Bí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àsọyé Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn