Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

K Í NI ìdáhùn ẹ sí ìbéèrè yẹn? Àwọn kan máa ń rò pé àwọn mọ Ọlọ́run dáadáa, wọ́n ní ọ̀rẹ́ àwọn tímọ́tímọ́ ni. Àwọn míì sì máa ń wo Ọlọ́run bíi mọ̀lẹ́bí kan tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra. Wọ́n gbà pó wà lóòótọ́, àmọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Tó o bá gbà pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, kí ni ìdáhùn ẹ sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí?

1. Ṣẹ́ni gidi kan ni Ọlọ́run?

2. Ṣé Ọlọ́run lórúkọ?

3. Ṣé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè?

4. Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa mi?

5. Ṣé gbogbo ẹ̀sìn ni inú Ọlọ́run dùn sí?

Tó o bá bi àwọn èèyàn láwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí, oríṣiríṣi ìdáhùn ni wọ́n máa fún ẹ. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé oríṣiríṣi ìtàn àròsọ àti èrò òdì làwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run.

Ìdí Tí Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Wọ̀nyẹn Fi Ṣe Pàtàkì

Nígbà tí Jésù Kristi ń bá obìnrin kan tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run sọ̀rọ̀ létí kànga, ó tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an. Bí obìnrin yìí tiẹ̀ jẹ́ ará Samáríà, ó gbà pé wòlíì kan ni Jésù. Àmọ́, ohun kan wà tó ń da ọkàn rẹ̀ láàmú. Ẹ̀sìn Jésù yàtọ̀ sí tiẹ̀. Nígbà tó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, Jésù sọ fún un láì fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé: “Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀.” (Jòhánù 4:19-22) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó sọ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run ló mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an.

Ṣóhun tí Jésù ń sọ ni pé kò sẹ́ni tó lè mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an? Rárá o. Jésù sọ fún obìnrin yìí pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Ṣéwọ náà wà lára àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́”?

Ó yẹ kí ìdáhùn ẹ sí ìbéèrè yìí dá ẹ lójú. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú? Jésù ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ́ ká ní ìmọ̀ pípéye nígbà tó gbàdúrà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Èyí fi hàn pé tó o bá fẹ́ wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun, ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an!

Ṣó ṣeé ṣe kéèyàn mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe! Báwo wá lo ṣe lè mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run? Gbọ́ ohun tí Jésù sọ nípa ara rẹ̀, ó ní: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Ó tún sọ pé: “Ẹni tí Baba sì jẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe Ọmọ, àti ẹni tí Ọmọ bá fẹ́ láti ṣí i payá fún.”—Lúùkù 10:22.

Nítorí náà, tá a bá fẹ́ mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, a ní láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn nígbà tó wà láyé. Kódà, Jésù ṣèlérí fún wa pé: “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀hìn mi ni yín nítòótọ́; ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sọ yín di òmìnira.”—Jòhánù 8:31, 32, Ìròhìn Ayọ̀.

Báwo wá ni Jésù ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè márùn-ún tá a béèrè níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣé kì í ṣe Ọlọ́run tó ò mọ̀ dáadáa lò ń jọ́sìn báyìí?