Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Jẹ́ Kí N máa Láyọ̀ Láìka Àìlera Mi Sí

Ohun Tó Jẹ́ Kí N máa Láyọ̀ Láìka Àìlera Mi Sí

Ohun Tó Jẹ́ Kí N máa Láyọ̀ Láìka Àìlera Mi Sí

Gẹ́gẹ́ bí Paulette Gaspar ṣe sọ ọ́

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wọ̀n tó nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́ta nígbà tí wọ́n bí mi, dókítà tó gbẹ̀bí mi mọ̀ pé àìsàn ńlá kan ń ṣe mí. Nígbà tí wọ́n ń gbẹ̀bí mi lọ́wọ́, àwọn egungun kan lára mi sán. Ṣẹ́ ẹ rí i, mo láìsàn kan tí wọ́n ń pè ní ‘osteogenesis imperfecta,’ àìsàn yìí ni ò jẹ́ kí egungun mi lágbára, ìgbàkigbà ni egungun mi sì lè sán tàbí kó yẹ̀. Wọ́n sáré gbé mi wọnú yàrá tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ abẹ, àmọ́ àwọn dókítà ò rò pé màá yè é. Wọ́n retí pé màá kú kí wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] tó pé.

ÌLÚ Canberra tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni wọ́n ti bí mi ní June 14, ọdún 1972. Ọ̀rọ̀ ò rí báwọn dókítà ṣe rò nígbà tí wọ́n bí mi, èmi àti wọn la jọ lo ọjọ́ yẹn ṣúlẹ̀. Àmọ́, àìsàn òtútù àyà tún kún nǹkan tó ń ṣe mí. Torí pé àwọn dókítà rò pé mi ò lè yè é, wọn ò ṣòpò fún mi lóògùn kankan mọ́, wọ́n gbà pé kóhun tó bá máa ṣẹlẹ̀ kúkú ṣẹlẹ̀. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀, mo yè é.

Mo kàn ń ronú bọ́kàn àwọn òbí mi ò ṣe ní balẹ̀ ní gbogbo àkókò yẹn. Torí pé kò dájú pé màá yè é, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tí wọ́n fẹ́ràn àwọn òbí mi gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n máà tíì fọkàn sí pé màá wà láàyè. Kódà, fún odindi oṣù mẹ́tà àkọ́kọ́ tí mo fi wà nílé ìwòsàn, wọn ò gba àwọn òbí mi láàyè kí wọ́n fọwọ́ kàn mí lásán. Ẹ̀rù ń bà wọ́n pé tẹ́nikẹ́ni bá fọwọ́ kàn mí lásán, ó lè ṣe mí léṣe. Nígbà táwọn dókítà wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé màá yè é, wọ́n ní káwọn òbí mi gbé mi lọ síbi tí wọ́n ti máa ń tọ́jú àwọn abirùn ọmọ.

Àmọ́, àwọn òbí mi pinnu pé àwọn máa gbé mi lọ sílé. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ìgbà yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ màmá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan tí màmá mi ń kọ́ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn tọ́jú mi. Àmọ́, mo mọ̀ pé ó máa ṣòro fún wọn gan-an láti sún mọ́ mi bó ṣe máa ń rí láàárín ọmọ sí ìyá torí ìtọ́jú tí wọ́n ń fún mi ń gba gbogbo okun àti ìrònú wọn. Àwọn òbí mi máa ń gbé mi lọ sílé ìwòsàn lọ́pọ̀ ìgbà. Ó fẹ́ẹ̀ máà sóhun tí wọ́n ń ṣe fún mi tí kì í kán mi léegun, kódà tí mo bá rọra sín, egungun mi máa ń sán, àgàgà tí wọ́n bá ń wẹ̀ fún mi ńṣe leegun mi máa ń kán.

Gbogbo Nǹkan Tojú Sún Mi

Orí àga àwọn arọ ni mo dàgbà sí. Kò ṣeé ṣe fún mi láti rìn. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, àwọn òbí mi ń tọ́jú mi gan-an ni.

Yàtọ̀ síyẹn, màmá mi sapá láti máa fi àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì kọ́ mi. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ́ mi pé lọ́jọ́ iwájú, Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè níbi tí gbogbo èèyàn á ti ní ìlera pípé, téèyàn ò ní banú jẹ́ mọ́, tí gbogbo èèyàn á sì máa jọ́sìn Ọlọ́run. (Sáàmù 37:10, 11; Aísáyà 33:24) Àmọ́, màmá mi sòótọ́ ibẹ̀ fún mi pé àwọn ò rò pé màá lè gbé ìgbésí ayé tó rọrùn títí dìgbà tí Ọlọ́run á fi sọ ayé di Párádísè.

Àwọn òbí mi kọ́kọ́ fi mí síléèwé àwọn abirùn. Àmọ́, àwọn olùkọ́ mi ò bá mi gbèrò bí nǹkan á ṣe sàn fún mi, èmi náà ò sì láfojúsùn kankan. Kódà, lílọ síléèwé pàápàá dìṣòro fún mi. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ iléèwé mi ni wọ́n máa ń ṣèkà fún mi. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síléèwé àwọn ọmọ tí kì í ṣe abirùn. Kò rọrùn fún mi láti wà láàárín àwọn ọmọléèwé tó kù torí pé ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣe bíi tiwọn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí gbogbo nǹkan tojú sún mi. Síbẹ̀, mo pinnu pé màá parí iléèwé girama.

Nígbà tí mo wà níléèwé girama, mo máa ń ronú lórí báwọn ọmọ iléèwé mi ṣe ń gbé ìgbésí ayé tó dà bíi pé kò nítumọ̀. Mo tún máa ń ronú lórí àwọn ohun tí màmá mi ti kọ́ mi látinú Bíbélì. Lọ́kàn mi, mo mọ̀ pé òótọ́ làwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ. Àmọ́, àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ̀nyẹn ò wọ̀ mí lọ́kàn nígbà yẹn. Nígbà tó yá, mo pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí í jayé orí mi, láìronú nípa ọ̀la.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] mo kúrò nílé àwọn òbí mi, èmi àtàwọn abirùn bíi tèmi sì jọ gbalé tiwa. Inú mi dùn lóòótọ́ pé mo kúrò nílé, àmọ́ ṣe ló tún dá kún ìṣòro mi. Mo túbọ̀ lómìnira, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ń gbádùn ara wa, a sì máa ń jayé orí wa. Ọ̀pọ̀ nínu àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ṣègbéyàwó. Ó sì wu èmi náà kí n rẹ́ni táá nífẹ̀ẹ́ mi táá sì fi mi ṣaya. Àmọ́, torí àìlera tí mo ní, mi ò rò pé màá rẹ́ni táá fi mí ṣaya. Èyí sì bà mí lọ́kàn jẹ́ gidigidi.

Àmọ́, mi ò dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí àìlera mi. Torí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run débi tí mo fi mọ̀ pé kò lè ṣojúsàájú. (Jóòbù 34:10) Mò ń gbìyànjú láti máa fara dà á. Bí gbogbo nǹkan tiẹ̀ ń tojú sún mi.

Bí Nǹkan Ṣe Ń Yí Pa Dà Díẹ̀díẹ̀

Mo dúpẹ́ pé màmá mi kíyè sí pé nǹkan ti tojú sún mi, wọ́n sì sọ fún alàgbà kan tílé ẹ̀ ò jìnnà síbi tí mò ń gbé. Alàgbà náà bá mi sọ̀rọ̀ lórí fóònù, ó sì rọ̀ mí pé kí n wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò mi. Yàtọ̀ síyẹn, arábìnrin kan nínú ìjọ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Bí arábìnrin yẹn tún ṣe ń rán mi létí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí màmá mi ti kọ́ mi lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn ni ojú tí mo fi ń wo ìgbésí ayé bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Mo wá ń gbádùn bíbá àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni kẹ́gbẹ́. Mo ti kọ́ láti má máa sọ bó ṣe ń ṣe mí fáwọn èèyàn torí mi ò fẹ́ kí wọ́n dá kún ìṣòro mi. Àmọ́, ó dà bíi pé èyí jẹ́ kó ṣòro fún mi láti nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé ó yẹ kí n ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Torí náà lóṣù December ọdún 1991, mo ṣèrìbọmi káwọn èèyàn lè mọ̀ pé mo ti yara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.

Mo kúrò nílé témi àtàwọn tá a jọ jẹ́ abirùn ń gbé mo sì kó lọ sílé tí mo gbà fúnra mi. Àyípadà yìí ṣe mí láǹfààní, ó sì tún dá kún ìṣòro mi. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń dánìkan wà lọ́pọ̀ ìgbà. Ẹ̀rù sì ń bà mí káwọn èèyàn kéèyàn má lọ jálẹ̀kùn mọ́ mi lórí. Ìyẹn sì jẹ́ kí gbogbo nǹkan tún bẹ̀rẹ̀ sí í tojú sú mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń rẹ́rìn, tí mo sì máa ń ṣe bí ẹni pé inú mi ń dùn, nǹkan ò rọrùn fún mi rárá. Mo nílò ọ̀rẹ́ kan tó máa dúró tì mí, tí ò sì ní jìnnà sí mi.

Inú mi dùn pé Jèhófà Ọlọ́run fún mi nírú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwọn alàgbà ìjọ ṣètò pé kí arábìnrin Suzie, abilékọ kan, tún wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin Suzie ò kàn máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan. Àmọ́, ó tún di ọ̀rẹ́ mi àtàtà, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.

Arábìnrin Suzie kọ́ mi pé kí n máa sọ nǹkan tí mo ti kọ́ fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé àti láwọn ibòmíì. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì àwọn ànímọ̀ Ọlọ́run díẹ̀díẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ láìkà pé mo ti ṣèrìbọmi sí, mi ò tíì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. Kódà nígbà kan, mò ń rò ó pé bóyá kí n tiẹ̀ pa ìjọsìn Jèhófà tì. Mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún arábìnrin Suzie, ó sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè borí ìṣòro yìí.

Arábìnrin Suzie tún jẹ́ kí n mọ̀ pé ohun tó ń dá kún ẹ̀dùn ọkàn mi ni àwọn ọ̀rẹ́ tí wọn ò fẹ́ràn Jèhófà tí mò ń bá rìn. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọn ò fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣeré, pàápàá àwọn tó dàgbà jù mi lọ. Bákàn náà, àárín èmi àti màmá mi ò fi bẹ́ẹ̀ gún, torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí èmi, màmá mi àti ẹ̀gbọ́n mi ṣe máa dọ̀rẹ́ pa dà. Ó yà mí lẹ́nu pé mo lè láyọ̀ tó pọ̀ tó báyìí torí mi ò nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rí ayọ̀ àti okun nìyẹn látọ̀dọ̀ àwọn ará nínú ìjọ, àwọn ìdílé mi pàápàá jù lọ látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Sáàmù 28:7.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà

Lẹ́yìn tí mo dé láti àpéjọ àgbègbè kan níbi tí mo ti gbọ́ àsọyé tó dá lórí ayọ̀ tọ́pọ̀ èèyàn ń rí nídìí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo wá ronú pé, ‘Èmi náà lè ṣe é kẹ̀!’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé ó máa ṣòro fún mi gan-an ni. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo gbàdúrà nípa ẹ̀, mo pinnu láti gba fọ́ọ̀mù tó máa jẹ́ kí n máa lo àkókò tó pọ̀ láti máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì di oṣù April ọdún 1998, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Báwo lèmi tí mo jẹ́ aláìlera á ṣe máa lọ káàkiri láti wàásù? Ó máa ń wù mí láti dá ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fúnra mi, kò wù mí kí n máa da àwọn ẹlòmíì láàmú, kó jẹ́ pé àwọn láá máa gbé mi káàkiri tàbí kí wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan míì fún mi. Torí náà, arábìnrin Suzie àti Michael, ọkọ ẹ̀, dábàá pé kí n ra kẹ̀kẹ́ tó ń lo ẹ́ńjìnnì bíi ti mọ́tò tí màá máa gùn káàkiri. Àmọ́ báwo ni màá ṣe máa gun kẹ̀kẹ́ yìí? Tẹ́ ẹ bá kíyè sí àwòrán tó wà lójú ìwé yìí, ẹ máa rí i pé wọ́n dìídì ṣe kẹ̀kẹ́ yìí fún mi ni. Kò sí pé mò ń gbé ara mi jáńjálá, tí ò ju kìlógíráàmù mọ́kàndínlógún [19], dìde lórí kẹ̀kẹ́ yìí.

Kẹ̀kẹ́ mi tuntun yìí túbọ̀ jẹ́ kó rọrùn fún mi láti lọ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákòókò tó bá rọrùn fún àwọn àti èmi. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń gun kẹ̀kẹ́ yìí, mo sì máa ń gbádùn bí atẹ́gùn ṣe máa ń fẹ́ sí mi lójú nígbà tí mo bá ń gùn ún.

Mo máa ń gbádùn bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní òpópónà, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì máa ń ṣe dáadáa tí wọ́n sì tún máa ń bọ̀wọ̀ fún mi. Inú mi máa ń dùn gan-an láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀rín máa ń dá pa mí tí mo bá rántí ọjọ́ kan báyìí témi àti arákùnrin kan tó jẹ́ èèyàn gíga jọ ń wàásù láti ilé dé ilé. Arákùnrin náà kí onílé, onílé náà sì wá ń wò mí tìyanutìyanu, ló bá bi ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ pé, “Ṣẹ́ni tẹ́ ẹ jọ wá yìí lè sọ̀rọ̀?” Báwa méjèèjì ṣe bú sẹ́rìn-ín nìyẹn. Lẹ́yìn tí mo wàásù fún un tán, obìnrin yẹn wá mọ̀ pé mo lè sọ̀rọ̀ dáadáa!

Mò ń gbádùn ìgbésí ayé mi báyìí, mo sì ti kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá mi pé wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọkàn mi sì wá balẹ̀ báyìí bí mo ṣe ń retí ọjọ́ iwájú tí Ọlọ́run máa sọ “ohun gbogbo di tuntun,” títí kan ara mi tó rí jáńjálá yìí náà.—Ìṣípayá 21:4, 5.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

“Mò ń gbìyànjú láti máa fara dà á. Bí gbogbo nǹkan tiẹ̀ ń tojú sún mi”