Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Wọ́n Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Wọ́n Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

ÀWỌN èèyàn sábà máa ń túmọ̀ àwọn ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì sí onírúurú èdè kí ọ̀pọ̀ èèyàn, tó bá ti lè ṣeé ṣe tó, lè lóye rẹ̀. Ìsọfúnni pàtàkì ló wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti wà lákọọ́lẹ̀, àwọn ohun tó wà níbẹ̀ “ni a kọ fún ìtọ́ni wa” àti láti tù wá nínú kó sì lè jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.—Róòmù 15:4.

Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè torí pé àwọn ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì jù lọ fáwa èèyàn ni wọ́n kọ síbẹ̀. Onírúurú èèyàn nínú ìtàn ló ti gbìyànjú láti túmọ̀ Bíbélì láìka àìsàn lílekoko, ìfòfindè látọ̀dọ̀ ìjọba tàbí bí wọ́n ṣe fi ikú halẹ̀ mọ́ wọn sí. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe tán láti fẹ̀mí wọn wewu? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ti wáyé nínú ìtàn, tó sì ní í ṣe pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe túmọ̀ Bíbélì.

‘Èdè Gẹ̀ẹ́sì Ló Rọ̀ Wọ́n Lọ́rùn Jù Lọ’

Èdè Látìn ni wọ́n fi ń ṣèjọsìn nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí wọ́n bí John Wycliffe ní nǹkan bí ọdún 1330. Àmọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì làwọn èèyàn sábà máa ń sọ nínú ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n máa fi ń bá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀, èdè yẹn náà sì ni wọ́n máa fi ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.

Ọ̀gbẹ́ni Wycliffe, tó jẹ́ àlùfáà nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, mọ èdè Látìn sọ dáadáa. Àmọ́, ó gbà pé kò bójú mu láti máa fi èdè Látìn, tó kà sí èdè táwọn kan tó gbà páwọn lajú fi ń yara wọn sọ́tọ̀, kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Ó kọ̀wé pé: “Èdè tó rọrùn jù lọ láti lóye ló yẹ kí wọ́n máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin Ọlọ́run torí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà ńbẹ̀.” Ìdí nìyẹn tí Ọ̀gbẹ́ni Wycliffe àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fi kó àwùjọ àwọn èèyàn kan jọ láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìyẹn sì gbà wọ́n tó nǹkan bí ogún [20] ọdún.

Àmọ́ àwọn aláṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí èdè míì. Ìwé Mysteries of the Vatican, ṣàlàyé ìdí táwọn aláṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ò fi fara mọ́ ọn, ó ní: “Ó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ ìjọ wọn láti fi bí ìgbésí ayé àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni ṣe rọrùn tó wéra pẹ̀lú ìlànà ìsìn Kátólíìkì . . . Ohun tí wọ́n á kọ́kọ́ rí ni ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ tó wà láàárín ohun tí Olùdásílẹ̀ Ìsìn Kristẹni fi kọ́ni àtohun tí ẹni tó fara ẹ̀ ṣe igbákejì Olùdásílẹ̀ Ìsìn Kristẹni [ìyẹn póòpù] fi ń kọ́ni.”

Póòpù Gregory Kọkànlá ṣe ìkéde márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fi bẹnu àtẹ́ lu ọ̀gbẹ́ni Wycliffe. Àmọ́ ọ̀gbẹ́ni yìí ò torí ìyẹn dá iṣẹ́ ìtúmọ̀ tó ń ṣe dúró. Ó fèsì pé: “Èdè Gẹ̀ẹ́sì ló rọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́rùn jù lọ láti fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin Kristi. Èdè ìbílẹ̀ ìlú Mósè ni Mósè fi gbọ́ òfin Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà sì làwọn àpọ́sítélì Kristi.” Ṣáájú kí Wycliffe tó kú ní nǹkan bí ọdún 1382, àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè tí Wycliffe kó jọ ti parí títúmọ̀ odindi Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn sì ni odindi Bíbélì tó kọ́kọ́ wà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀kan lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Wycliffe ṣe àtúnṣe sí ìtúmọ̀ Bíbélì yẹn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ẹ̀dà míì tó túbọ̀ rọrùn láti ka.

Torí pé kò tíì sáwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé nígbà yẹn, ṣe ni wọ́n ní láti fara balẹ̀ ṣàdàkọ àwọn ìwé Bíbélì yẹn, ìyẹn sì máa gbà wọ́n tó nǹkan bí oṣù mẹ́wàá gbáko! Síbẹ̀ inú àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì ò dùn sí pé kí gbogbo ọmọ ìjọ ní Bíbélì lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ náà le débi pé bíṣọ́ọ̀bù àgbà kan sọ pé àwọn máa yọ ẹnikẹ́ni tó bá ka Bíbélì náà kúrò nínú ìjọ àwọn. Lẹ́yìn tó ti lé ní ogójì [40] ọdún tí Wycliffe ti kú, àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ hú òkú ẹ̀, kí wọ́n fi iná sun egungun ẹ̀, kí wọ́n sì da eérú ẹ̀ sínú odò Swift. Àmọ́ ìyẹn ò dí àwọn tí wọ́n dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ lọ́wọ́ láti ka Bíbélì tí Wycliffe túmọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n William M. Blackburn ròyìn pé: “Ẹ̀dà Bíbélì tí Wycliffe túmọ̀ táwọn èèyàn sì ṣàdàkọ ẹ̀ ò lóǹkà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní in lọ́wọ́, tí wọ́n sì tún fi lé àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́.”

Bíbélì Tó Wà fún Gbogbo Èèyàn

Nígbà tó fi máa pé igba [200] ọdún, èdè Gẹ̀ẹ́sì tí Wycliffe fi túmọ̀ Bíbélì nígbà yẹn ti di èdè àtijọ́. Inú ọ̀dọ́mọdé kan tó ń wàásù nítòsí ìlú Bristol ò dùn rárá pé àwọn èèyàn díẹ̀ péré ló lè lóye Bíbélì. Lọ́jọ́ kan, ọ̀dọ́mọdé náà, ìyẹn William Tyndale, gbọ́ tí ọkùnrin kan tó mọ̀wé dáadáa sọ pé ó máa sàn kó máà sí òfin Ọlọ́run ju kó máà sí òfin póòpù lọ. Ọ̀gbẹ́ni Tyndale wá fèsì pé tí Ọlọ́run bá gba òun láyè, kò ní pẹ́ tóun fi máa rí dájú pé kò sẹ́ni tí ò ní lè lóye Bíbélì, kódà àgbẹ̀ tó wà lóko pàápàá máa lè lóye Bíbélì ju àwọn tó kàwé lọ.

Ẹ̀dà Bíbélì Vulgate tí wọ́n kọ lédè Látìn ni Wycliffe fi túmọ̀ Ìwé Mímọ́, ọwọ́ ló sì fi ṣàdàkọ ẹ̀. Àmọ́, lọ́dún 1524, Ọ̀gbẹ́ni Tyndale bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì ní tààràtà látinú ojúlówó èdè Hébérù àti Gíríìkì, lẹ́yìn tó ti kúrò nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ sí orílẹ̀-èdè Jámánì, ó sì wá fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ̀ ẹ́ nílùú Cologne. Kò pẹ́ rárá táwọn ọ̀tá Tyndale fi mọ̀ nípa ìtúmọ̀ Bíbélì tó ṣe yìí, wọ́n sì rọ àwọn aláṣẹ ìlú Cologne pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ẹ̀dà Bíbélì náà.

Ọ̀gbẹ́ni Tyndale bá sá lọ sílùú Worms, lórílẹ̀-èdè Jámánì kó lè máa báṣẹ́ ìtúmọ̀ náà nìṣó. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n dọ́gbọ́n kó àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí Ọ̀gbẹ́ni Tyndale tú sí èdè Gẹ̀ẹ́sì wọ ilẹ̀ England. Láàárín oṣù mẹ́fà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ra àwọn ẹ̀dà Bíbélì yẹn, làwọn bíṣọ́ọ̀bù bá yára pe ìpàdé pàjáwìrì, wọ́n sì pàṣẹ pé káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sun Bíbélì.

Kí wọ́n bàa lè dáwọ́ báwọn èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì dúró, káwọn èèyàn má sì lè fetí sáwọn ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Tyndale tó ta ko tàwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì, bíṣọ́ọ̀bù ìlú London fún Alàgbà Thomas More láṣẹ láti kọ̀wé tó máa fi ṣàtakò sáwọn ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Tyndale. Àwọn ohun tí Alàgbà More gbájú mọ́ ni bí Ọ̀gbẹ́ni Tyndale ṣe lo “ìjọ” dípò “ṣọ́ọ̀ṣì” àti bó ṣe lo “àgbà” tàbí “alàgbà” dípò “àlùfáà” nínú àwọn ìtúmọ̀ tó ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Tyndale lò yìí ò pọ́n póòpù lé, kò sì fìyàtọ̀ sáàárín àwọn olórí ìsìn àtàwọn ọmọ ìjọ. Alàgbà Thomas More tún bẹnu àtẹ́ lu bí ọ̀gbẹ́ni Tyndale ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·gaʹpe sí “ìfẹ́” dípò “ìtọrẹ àánú.” Ìwé If God Spare My Life, sọ pé: “Ìtúmọ̀ yìí lè ṣàkóbá fún Ṣọ́ọ̀ṣì, torí pé táwọn èèyàn ò bá ka ìtọrẹ àánú sí pàtàkì mọ́, wọn ò ní fi bẹ́ẹ̀ dá owó mọ́, owó yẹn sì ni póòpù fi ń ṣàdúrà fún wọn kí wọ́n máa bàa pẹ́ nínú pọ́gátórì torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àwọn olóòótọ́ èèyàn yìí ò sì ní lè gba ẹ̀tọ́ wọn láti lọ sọ́run.”

Thomas More ló ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dáná sun ẹnikẹ́ni tó bá ti ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n fún ọ̀gbẹ́ni Tyndale lọ́rùn pa tí wọ́n sì dáná sun ún lórí òpó igi lóṣù October ọdún 1536. Ṣe ni wọ́n bẹ́ Thomas More pàápàá lórí nígbà tó yá torí pé ó ṣe nǹkan kan tó bí ọba nínú. Àmọ́, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ ọ́ di ẹni mímọ́ lọ́dún 1935, nígbà tó sì fi máa di ọdún 2000, Póòpù John Paul Kejì sọ More di àgbà ọ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ tó ń ṣètìlẹyìn fáwọn olóṣèlú.

Wọn ò firú ọ̀wọ̀ yìí wọ ọ̀gbẹ́ni Tyndale. Àmọ́ ṣáájú kí wọ́n tó pa ọ̀gbẹ́ni Tyndale, Miles Coverdale, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Tyndale ṣe àdìpọ̀ àwọn ìwé inú Bíbélì tí ọ̀gbẹ́ni Tyndale ti túmọ̀, ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe odindi Bíbélì jáde, ìyẹn sì ni ìtúmọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì látinú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì! Ó ti wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn tó fi mọ́ àwọn àgbẹ̀ tó wà lóko pàápàá láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Báwo ni wọ́n ṣe wá bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè míì tó yàtọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì?

“Ó Dà Bíi Pé Kò Lè Ṣeé Ṣe”

Láìka àtakò gbígbóná janjan táwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ Robert Morrison, tó jẹ́ míṣọ́nnárì kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe sí, kò jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹ̀ níyà lórí ìpinnu tó ṣe láti túmọ̀ odindi Bíbélì sí èdè àwọn ará Ṣáínà, torí náà, ó rìnrìn àjò lọ sórílẹ̀-èdè Ṣáínà lọ́dún 1807. Iṣẹ́ ìtumọ̀ tó dáwọ́ lé yẹn ò rọrùn rárá. Ọ̀gbẹ́ni Charles Grant, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà níléeṣẹ́ kan tíjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dá sílẹ̀ láti máa fi dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn ará Íńdíà sọ pé: “Ó dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe.”

Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Morrison dé ilẹ̀ Ṣáínà ló wá rí i pé òfin kan ti wà níbẹ̀ pé pípa ni wọ́n máa pa ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà èyíkéyìí tó bá kọ́ àwọn àjèjì ní èdè àwọn ará Ṣáínà. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Morrison fi tilẹ̀kùn mọ́rí tí kò sì jáde nílé, torí kó lè dáàbò bo ẹ̀mí ara ẹ̀ àti tàwọn tó gbà láti kọ́ ọ ní èdè yẹn. Ìwádìí kan fi hàn pé ‘lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ fún odindi ọdún méjì, ó ti lè sọ èdè ìbílẹ̀ Mandarin àtàwọn èdè ìbílẹ̀ míì, ó ti lè ka èdè Ṣáínà, ó sì ti lè kọ ọ́ sílẹ̀.’ Àmọ́, ní gbogbo ìgbà tá à ń wí yìí, Olú Ọba ilẹ̀ Ṣáínà ti ṣòfin tó de títẹ àwọn ìwé ìsìn Kristẹni, ṣe ló tiẹ̀ ní kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tó bá tẹ ìwé èyíkéyìí tó bá jẹ́ ti ìsìn Kristẹni. Láìka gbogbo ìhalẹ̀mọ́ni yìí sí, Ọ̀gbẹ́ni Morrison parí títúmọ̀ odindi Bíbélì sí èdè àwọn ará Ṣáínà ní November 25, ọdún 1819.

Nígbà tó fi máa di ọdún 1836, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] odindi Bíbélì, ẹgbẹ̀rún-ún mẹ́wàá [10,000] Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì àti ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31,000] ìwé inú Bíbélì ni wọ́n ti tẹ̀ jáde lédè àwọn ará Ṣáínà. Ẹ ò rí i pé ohun tó “dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe” ti wá di ṣíṣe báyìí torí pé àwọn èèyàn fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

Wọ́n Fi Bíbélì Sínú Ìrọ̀rí

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí Ọ̀gbẹ́ni Adoniram Judson, tó jẹ́ míṣọ́nnárì ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ṣègbéyàwó lóṣù February ọdún 1812, òun àtìyàwó ẹ̀, ìyẹn Ann, rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn kan, wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé lórílẹ̀-èdè Burma lọ́dún 1813. a Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè àwọn ará Burma, èdè yẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tó ṣòroó kọ́ jù lọ lágbàáyé. Lẹ́yìn ọdún bíi mélòó kan tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè yẹn, Ọ̀gbẹ́ni Judson kọ̀wé pé: “Èdè àwọn èèyàn tó yàtọ̀ pátápátá sí wa là ń kọ́, bí wọ́n ṣe ń ronú ò bá tiwa mu rárá . . . A ò ní ìwé atúmọ̀ èdè, kò sì sí ẹnì kankan láti ṣàlàyé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ fún wa.”

Ọ̀gbẹ́ni Judson ò torí ìṣòro tó ní pẹ̀lú èdè tuntun tó ń kọ́ yìí juwọ́ sílẹ̀. Ó parí títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí èdè àwọn ará Burma lóṣù June ọdún 1823. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn logun kan jà lórílẹ̀-èdè Burma. Bí wọ́n ṣe ju Ọ̀gbẹ́ni Judson sẹ́wọ̀n nìyẹn torí pé wọ́n fura sí i pé amí ló wá ṣe, wọ́n de irin mọ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ẹ̀, wọ́n sì wá dè é mọ́ òpó igi kó má bàa kúrò lójú kan. Nínú ìwé kan tí ọ̀gbẹ́ni Francis Wayland kọ lọ́dún 1853 nípa ìgbésí ayé Judson, ó ní: “Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Ọ̀gbẹ́ni Judson kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ìyàwó ẹ̀ nígbà tó láǹfààní láti bá a sọ̀rọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ni ìwé àfọwọ́kọ tó tú Májẹ̀mú Tuntun sí.” Torí kí omi má bàa ba ìwé náà jẹ́ níbi tí wọ́n rì í mọ́lẹ̀ sí nínú ilé, Ann fi ìwé náà sínú ìrọ̀rí kan, ó rán an pa, ó sì gbé ìrọ̀rí náà wá fún ọkọ ẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ohunkóhun ò ṣe ìwé yẹn, láìka àwọn ìṣòro tí Judson ní yìí sí.

Wọ́n tú Judson sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù. Àmọ́ ayọ̀ tó ní ò tọ́jọ́, torí pé kí ọdún yẹn tó jálẹ̀, ibà líle kan kọ lu Ann, ìyàwó ẹ̀, ó sì kú láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan. Kò ju oṣù mẹ́fà péré lọ lẹ́yìn ìgbà yẹn tí àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan tún kọ lu Maria, ọmọbìnrin ẹ̀ tí kò ju ọmọ ọdún méjì lọ. Judson pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìtumọ̀ tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ láìka gbogbo ìbànújẹ́ tó dé bá a yìí sí. Ó sì parí títúmọ̀ odindi Bíbélì lọ́dún 1835.

Ṣéwọ Náà Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Àwọn atúmọ̀ èdè tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí kọ́ ló máa kọ́kọ́ fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó báyìí. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù nílùú Ísírẹ́lì àtijọ́ kọrin sí Jèhófà Ọlọ́run pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:97) Bíbélì kì í ṣe ìwé ìtàn dídùn kan lásán. Àwọn ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì ló wà ńbẹ̀. Ṣó o máa ń fi hàn pó o fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa kíkà á déédéé? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fàwọn nǹkan tó ò ń kà nínú ẹ̀ sílò, wàá “láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:25.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orílẹ̀-èdè Myanmar ni wọ́n wá ń pe Burma báyìí. Èdè Burmese sì ni èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Èdè Gẹ̀ẹ́sì ló rọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́rùn jù lọ láti fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin Kristi.”—JOHN WYCLIFFE

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọ̀gbẹ́ni William Tyndale rèé àti ojú ìwé kan látinú Bíbélì tó túmọ̀

[Credit Line]

Ọ̀gbẹ́ni Tyndale: Látinú ìwé The Evolution of the English Bible

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀gbẹ́ni Robert Morrison rèé pẹ̀lú odindi Bíbélì tó tú sí èdè àwọn ará Ṣáínà

[Àwọn Credit Line]

Látọwọ́ Asian Division of the Library of Congress

Ọ̀gbẹ́ni Robert Morrison, látọwọ́ W. Holl, nínú ìwé The National Portrait Gallery Volume IV, tí wọ́n tẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1820 (látorí ohun èlò ìtẹ̀wé), Chinnery, George (1774-1852) (lẹ́yìn náà)/Private Collection/Ken Welsh/The Bridgeman Art Library International

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ọ̀gbẹ́ni Adoniram Judson àti Bíbélì tó tú sí èdè àwọn ará Burma

[Credit Line]

Ọ̀gbẹ́ni Judson: Látọwọ́ John C. Buttre/Dictionary of American Portraits/Dover

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọ̀gbẹ́ni Wycliffe: Látinú ìwé The History of Protestantism (Vol. I); Bíbélì: Látọwọ́ American Bible Society Library, ìpínlẹ̀ New York