Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣémù Rí Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Wà Láyé Ṣáájú àti Lẹ́yìn Ìkún-Omi

Ṣémù Rí Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Wà Láyé Ṣáájú àti Lẹ́yìn Ìkún-Omi

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ṣémù Rí Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Wà Láyé Ṣáájú àti Lẹ́yìn Ìkún-Omi

ṢÉMÙ tó jẹ́ ọmọkùnrin Nóà la ìparun tó dé bá ayé tó wà ṣáájú Ìkún-omi já, ó sì ń bá ìgbésí ayé rẹ̀ nìṣó lẹ́yìn Ìkún-omi. Ṣó o mọ ìdí tí ayé tó wà ṣáájú Ìkún-omi fi pa run, báwo sì ni Ṣémù àti ìdílé rẹ̀ ṣe là á já?— a Jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò.

Nígbà tí Ṣémù wà lọ́mọdé, Bíbélì sọ pé: “Ìwà búburú ènìyàn” pọ̀ gan-an. Nǹkan “búburú” làwọn èèyàn máa ń rò “ní gbogbo ìgbà.” Ṣó o mọ ohun tí Ọlọ́run ṣe?— Ó jẹ́ kí òjò tó pọ̀ gan-an tá à ń pè ní Ìkún-omi rọ̀ láti pa àwọn èèyàn burúkú tó wà láyé run. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5; 2 Pétérù 3:6.

Ṣó o mọ ìdí tí Ọlọ́run fi pa ayé ìgbà yẹn run?— Ìdí ni pé èèyàn búburú ni wọ́n, nǹkan “búburú” ni wọ́n sì ń rò “ní gbogbo ìgbà.” Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó ní, “ṣáájú ìkún omi,” àwọn èèyàn ń gbádùn ara wọn, “wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu,” bẹ́ẹ̀ náà ni “àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó.” Jésù fi kún un pé: “Wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:37-39.

Kí làwọn èèyàn náà kò fiyè sí?— Nígbà yẹn, “oníwàásù òdodo” ni Nóà tó jẹ́ bàbá Ṣémù, àmọ́ àwọn èèyàn náà kò fetí sí ohun tó ń sọ. Nóà fetí sí Ọlọ́run, ó sì kan ọkọ̀ áàkì kan tó lè léfòó lórí omi, ọkọ̀ yìí ni òun àti ìdílé rẹ̀ máa wọ̀ kí wọ́n lè la Ìkún-omi náà já láìsí ewu. Nóà, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn, ìyẹn Ṣémù, Hámù, Jáfẹ́tì àtàwọn ìyàwó wọn nìkan ni wọ́n fiyè sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ńṣe ni àwọn tó kù ń ṣe ìfẹ́ inú ara wọn, ìdí sì nìyẹn tí Ìkún-omi fi pa wọ́n run.—2 Pétérù 2:5; 1 Pétérù 3:20.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí Ìkún-omi náà bẹ̀rẹ̀, Ṣémù àti ìdílé rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ sórí ilẹ̀ gbígbẹ. Gbogbo èèyàn búburú ti pa run, àmọ́ kò pẹ́ tí nǹkan fi yí pa dà. Kénáánì tó jẹ́ ọmọ Hámù arákùnrin Ṣémù ṣe ohun kan tó burú débi tí Nóà fi sọ pé: “Ègún ni fún Kénáánì.” Nígbà tó yá, Nímírọ́dù tó jẹ́ ọmọ-ọmọ Hámù náà tún di èèyàn burúkú. Ó ta ko Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, ó sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n kọ́ ilé gogoro kan tí wọ́n ń pè ní Bábélì kí wọ́n lè ṣe orúkọ fún ara wọn. Báwo lo ṣe rò pé nǹkan yìí ṣe máa rí lára Ṣémù àti bàbá rẹ̀?—Jẹ́nẹ́sísì 9:25; 10:6-10; 11:4, 5.

Ó bà wọ́n nínú jẹ́, inú Jèhófà náà kò sì dùn sí i. Ṣó o mọ ohun tí Jèhófà ṣe?— Ńṣe ló da èdè àwọn èèyàn náà rú kí wọ́n má bàa lóye ara wọn. Torí náà, wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró, wọ́n sì lọ síbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń sọ èdè kan náà. (Jẹ́nẹ́sísì 11:6-9) Àmọ́ Ọlọ́run kò yí èdè Ṣémù àti ti ìdílé rẹ̀ pa dà. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún wọn láti wà pa pọ̀, kí wọ́n sì lè ran ara wọn lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run. Ṣó o mọ iye ọdún tí Ṣémù fi sin Jèhófà?—

Ẹgbẹ̀ta [600] ọdún ni Ṣémù gbé láyé. Ọmọ ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] ni Ṣémù ṣáájú Ìkún-omi, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó lé méjì [502] ló sì gbé láyé lẹ́yìn Ìkún-omi. Kò sí àní-àní pé Ṣémù ran Nóà lọ́wọ́ nígbà tó ń kan ọkọ̀ áàkì àti nígbà tó ń wàásù nípa Ìkún-omi náà. Àmọ́ kí lo rò pé Ṣémù ń ṣe fún ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún tó gbé láyé lẹ́yìn Ìkún-omi?— Nóà pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Ṣémù.” Èyí fi hàn pé, Ṣémù kò dáwọ́ dúró láti máa sin Jèhófà, ó sì tún ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun kan náà. Nígbà tó yá, àwọn tó tún wá di ọmọ Ṣémù ni Ábúráhámù, Sárà àti Ísákì.—Jẹ́nẹ́sísì 9:26; 11:10-31; 21:1-3.

Wá ronú lórí ayé tá à ń gbé lónìí, èyí tó túbọ̀ ń kún fún ìwà ibi láti ìgbà ayé Ṣémù. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí?— Bíbélì sọ pé ó “ń kọjá lọ.” Àmọ́ kíyè sí ìlérí tó tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Torí náà, tá a bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a lè wà lára àwọn tó máa là á já sínú ayé tuntun Ọlọ́run. Nígbà yẹn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a ó máa fi tayọ̀tayọ̀ gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé!—1 Jòhánù 2:17; Sáàmù 37:29; Aísáyà 65:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.

Ìbéèrè:

○ Ayé wo ni Ṣémù kọ́kọ́ gbé, kí sì nìdí méjì tí Ọlọ́run fi pa ayé náà run?

○ Ọdún mélòó ni Ṣémù gbé láyé, irú èèyàn wo ló sì jẹ́?

○ Kí ló máa tó ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí?

○ Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ la òpin ayé yìí já?