Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹrin: Ọlọ́run Jẹ́ Mẹ́talọ́kan

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹrin: Ọlọ́run Jẹ́ Mẹ́talọ́kan

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹrin: Ọlọ́run Jẹ́ Mẹ́talọ́kan

Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? “Àwọn kan lè ronú pé ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó wọnú ìsìn Kristẹni nígbà tí ọ̀rúndún kẹrin ń parí lọ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Tá a bá ní ká wò ó lọ́nà kan, òótọ́ ni  . . Kí ọ̀rúndún kẹrin tó parí, èrò nípa ‘Ọlọ́run kan nínú Ẹni mẹ́ta’ kò fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó sì dájú pé àwọn Kristẹni kò tíì gbà á wọlé sínú ìgbé ayé wọn, kò sì sí lára ìgbàgbọ́ wọn.”—New Catholic Encyclopedia (1967), Ìdìpọ̀ 14, ojú ìwé 299.

“Àpérò kan wáyé nílùú Niséà ní May 20, ọdún 325 [Sànmánì Kristẹni]. Ọba Kọnsitatáìnì fúnra rẹ̀ ló ṣalága tó sì darí ìjíròrò tó wáyé níbẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ló sì dábàá . . . ọ̀ràn pàtàkì tó ṣàlàyé bí Kristi ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n gbé jáde níbi àpérò náà, pé ‘ọ̀kan náà ní Kristi àti Baba.’ Torí pé ẹ̀rù olú ọba náà ń ba àwọn bíṣọ́ọ̀bù, gbogbo wọn ló buwọ́ lu ìwé pé àwọn tẹ́wọ́ gba ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ náà, àyàfi àwọn méjì kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn náà kò tẹ́ ọ̀pọ̀ nínú wọn lọ́rùn.”—Encyclopædia Britannica (1970), Ìdìpọ̀ 6, ojú ìwé 386.

Kí ni Bíbélì sọ? Sítéfánù ‘kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run àti Jésù ń dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ó sì wí pé, Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀ àti Ọmọ-ènìyàn ń dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.’—Ìṣe 7:55, 56, Bibeli Mimọ.

Kí ni ìran yìí jẹ́ ká mọ̀? Nígbà tí Sítéfánù kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó rí Jésù tó ‘dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.’ Ó ṣe kedere pé kì í ṣe pé Jésù lọ di Ọlọ́run nígbà tó jíǹde tó sì pa dà sí ọ̀run, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó yàtọ̀ sí Ọlọ́run ni. Ìran tí Sítéfánù rí yìí kò sì fi hàn pé ẹnì kan wà nípò kẹta sí Ọlọ́run. Láìka ìsapá tí àwọn kan ń ṣe láti wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n máa fi ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn sí, Marie-Émile Boismard, tó jẹ àlùfáà ìjọ Dominic sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pe àkọlé rẹ̀ ní À l’aube du christianisme—La naissance des dogmes (Bí Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìsìn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Nígbà Tí Ẹ̀sìn Kristẹni Bẹ̀rẹ̀), ó ní: “Kò sí ibi tá a ti lè rí gbólóhùn náà kà nínú Májẹ̀mú Tuntun pé . . . ẹni mẹ́ta ló wà nínú Ọlọ́run kan.”

Ẹ̀kọ́ ìsìn tí Ọba Kọnsitatáìnì ṣagbátẹrù rẹ̀ yìí ni wọ́n fẹ́ fi fòpin sí àwọn àríyànjiyàn tó ń wáyé láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní ọ̀rúndún kẹrin. Àmọ́ dípò ìyẹn, ìbéèrè míì ló gbé dìde, ìbéèrè ọ̀hún ni pé: Ṣé Màríà, ìyẹn obìnrin tó bí Jésù, ni “Ìyá Ọlọ́run”?

Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Mátíù 26:39; Jòhánù 14:28; 1 Kọ́ríńtì 15:27, 28; Kólósè 1:15, 16

ÒKODORO ÒTÍTỌ́:

Ìgbà tí ọ̀rúndún kẹrin ń parí lọ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan wọnú ẹ̀sìn Kristẹni

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

Museo Bardini, Florence