Ẹ̀kọ́ Èké Kejì: Àwọn Èèyàn Burúkú Ń Joró Ní Ọ̀run Àpáàdì
Ẹ̀kọ́ Èké Kejì: Àwọn Èèyàn Burúkú Ń Joró Ní Ọ̀run Àpáàdì
Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? “Nínú gbogbo àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ayé àtijọ́, Plato ni èrò rẹ̀ nípa Ọ̀run Àpáàdì ní ipa tó pọ̀ jù lọ lórí àwọn èèyàn.”—Histoire des enfers (Ìtàn Nípa Ọ̀run Àpáàdì), látọwọ́ Georges Minois, ojú ìwé 50.
“Láti ìdajì ọ̀rúndún kejì Ọdún Olúwa Wa ni àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó yẹ kí àwọn lè fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí yìí ṣàlàyé ohun tí àwọn gbà gbọ́ . . . Ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn jù lọ ni ti Plato [ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tí Plato fi kọ́ni].”—Ìwé The New Encyclopædia Britannica (1988), Ìdìpọ̀ 25, ojú ìwé 890.
“Ẹ̀kọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀run àpáàdì wà, ó sì máa wà títí ayérayé. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ọkàn àwọn tó bá kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ tó lè fa ìparun máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì, níbi tí wọ́n á ti máa jìyà nínú ‘iná ayérayé.’ Ìyà tó tóbi jù lọ ní ọ̀run àpáàdì ni bí wọn kò ṣe ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ títí ayérayé.”—Ìwé Catechism of the Catholic Church, ẹ̀dà ti ọdún 1994, ojú ìwé 270.
Kí ni Bíbélì sọ? ‘Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, . . . nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n ní isà-òkú níbi tí ìwọ́ ń rè.”—Oníwàásù 9:5, 10, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, Sheol, tó túmọ̀ sí “ibi tí àwọn òkú wà,” ni wọ́n tú sí “ọ̀run àpáàdì” nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan. Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú? Ṣé wọ́n ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn nínú Ṣìọ́ọ̀lù ni? Rárá o, torí pé wọn “kò mọ ohun kan.” Ìdí nìyẹn tí Jóòbù, tó jẹ́ bàbá ńlá ìgbàanì, fi bẹ Ọlọ́run nígbà tó ń jẹ ìrora àìsàn lílekoko pé: ‘Fi mí pa mọ́ ní isà-òkú [ìyẹn Sheol, lédè Hébérù].’ (Jóòbù 14:13; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kí ni ohun tí Jóòbù béèrè yìí ì bá túmọ̀ sí tí Ṣìọ́ọ̀lù bá jẹ́ ibi ìdálóró ayérayé? Ohun tí ọ̀run àpáàdì wulẹ̀ túmọ̀ sí nínú Bíbélì ni isà-òkú, ìyẹn ibi tí èèyàn kò ti ní lè ṣe ohunkóhun mọ́.
O ò rí i pé ohun tí ọ̀run àpáàdì túmọ̀ sí yìí bọ́gbọ́n mu, ó sì bá Ìwé Mímọ́ pàápàá mu. Ẹ̀ṣẹ̀ búburú wo ni èèyàn lè dá tó máa mú kí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ dá onítọ̀hún lóró títí ayérayé? (1 Jòhánù 4:8) Àmọ́ ṣá o, tí ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì bá jẹ́ ẹ̀kọ́ èké, ẹ̀kọ́ pé gbogbo èèyàn rere máa lọ sí ọ̀run wá ń kọ́?
Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Sáàmù 146:3, 4; Ìṣe 2:25-27; Róòmù 6:7, 23
ÒKODORO ÒTÍTỌ́:
Ọlọ́run kì í dá èèyàn lóró ní ọ̀run àpáàdì
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Barrators—Giampolo/The Doré Illustrations For Dante’s Divine Comedy/Dover Publications Inc.