Bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Nílò Àbójútó Àrà Ọ̀tọ̀
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Nílò Àbójútó Àrà Ọ̀tọ̀
Ọkọ mi ló ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tá a fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé wa látìgbà tí àyẹ̀wò ti fi hàn pé mo ní àrùn tó máa ń jẹ́ kó rẹni. Àmọ́ kò fìgbà kankan jẹ́ kí n gbọ́ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ nípa ìnáwó. Kí ló dé tí kò fẹ́ jẹ́ kí n gbọ́ nǹkan kan? Ó ní láti jẹ́ pé ipò ìṣúnná owó wa burú gan-an débi pé ó mọ̀ pé àyà mi lè já tóun bá sọ fún mi.—Nancy. a
ÈÈYÀN lè níṣòro nínú ìgbéyàwó, àmọ́ ìṣòro tún lè légbá kan nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣe àìsàn tí ara ẹnì kejì sì le. b Ṣé ò ń ṣètọ́jú ọkọ tàbí aya rẹ tí ara rẹ̀ kò le? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ àwọn ìbéèrè yìí kò máa kó ìdààmú ọkàn bá ẹ: ‘Báwo ni màá ṣe ṣeé bí ìlera ẹnì kejì mi bá tún burú ju báyìí lọ? Ọjọ́ wo ni mo máa ṣe gbogbo èyí dà, kí n tó se oúnjẹ, kí n tó tún ilé ṣe, kí n tó ṣe iṣẹ́ tí mo máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé? Kí nìdí tó fi máa ń sú mi pé èmi ni ara mi le tí mo sì ní láti máa fìgbà gbogbo tọ́jú aláìsàn?’
Tó bá sì jẹ́ pé ìwọ ni ara rẹ kò le, o lè máa ṣàníyàn pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lẹ́nu ọ̀rọ̀ nígbà tí kò ṣeé ṣe fún mi láti máa ṣe ojúṣe mi? Ṣé ẹnì kejì mi máa ń kanra mọ́ mi torí pé mò ń ṣàìsàn? Ṣé ayọ̀ tá a ní gẹ́gẹ́ bi tọkọtaya ti dópin nìyẹn ni?’
Ó ṣeni láàánú pé àwọn tọkọtaya kan ti kọ ara wọn sílẹ̀ torí ìṣòro tí àìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀ dá sílẹ̀. Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó tìẹ náà máa tú ká.
Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kò kọra wọn sílẹ̀ láìka àìsàn tó lágbára sí, kódà wọ́n ń ṣàṣeyọrí. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Yoshiaki àti Kazuko. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pá ẹ̀yín Yoshiaki kò jẹ́ kó lè ṣe ohunkóhun láìsí ìrànlọ́wọ́ ẹlòmíì. Kazuko ṣàlàyé pé: “Ọkọ mi kò lè dá ṣe nǹkan kan. Torí pé èmi ni mò ń tọ́jú rẹ̀, ọrùn, èjìká àti apá máa ń ro mí, bí èmi náà ṣe di ẹni tó lọ ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn tí wọ́n ti máa ń to eegun nìyẹn. Mo máa ń nímọ̀lára pé ṣíṣe ìtọ́jú ẹni tí ara rẹ̀ kò le máa ń tánni lókun.” Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, Kazuko sọ pé: “Ìfẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya tún ti wá lágbára sí i.”
Kí wá ni ohun tó lè fúnni láyọ̀ tí èèyàn bá wà nírú ipò yìí? Òótọ́ kan ni pé, àwọn tí wọ́n bá jẹ́ kí ìgbéyàwó wọn tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì máa ń ṣe ara wọn lọ́kan máa ń gbà pé àwọn méjèèjì ni ìṣòro tí àìsàn náà fà kó bá, kì í ṣe ẹnì kejì wọn tí ara rẹ̀ kò le. Ó ṣe tán, tí ọkọ tàbí aya ẹnì kan bá Jẹ́nẹ́sísì 2:24 ṣàpèjúwe àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín tọkọtaya báyìí pé: “Ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” Torí náà, tí ọkọ tàbí aya bá ní àìsàn kan tí kò lọ bọ̀rọ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn méjèèjì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti bójú tó ìṣòro náà.
ń ṣàìsàn, àwọn méjèèjì ló máa ṣe àkóbá fún, ì bá à jẹ́ lọ́nà tó yàtọ̀ síra. ÌwéBákan náà, ìwádìí fi hàn pé ipò tí kò rọrùn máa ń ṣeé fara dà fún àwọn tọkọtaya tí kò bá jẹ́ kí àìlera tí kò lọ bọ̀rọ̀ mú kí wọ́n fi ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì máa ń kọ́ onírúurú ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí wọ́n lè gbà bójú tó ìṣòro náà. Ọ̀pọ̀ ọgbọ́n tí wọ́n lè máa dá tí wọ́n á fi máa fara dà á bá àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó wúlò títí lọ gbére mu. Ṣàyẹ̀wò àwọn àbá mẹ́ta tó tẹ̀ lé e yìí:
Ẹ Máa Gba Ti Ara Yín Rò
Ìwé Oníwàásù 4:9 sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan.” Kí nìdí? Ẹsẹ 10 ṣàlàyé pé: “Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.” Ṣé o máa ń ‘gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ dìde’ nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé o mọyì rẹ̀?
Ṣé ẹ máa ń wá onírúurú ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà ran ara yín lọ́wọ́? Yong, tí apá kan ara ìyàwó rẹ̀ ti rọ sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti máa gba ti aya mi rò ní gbogbo ìgbà. Ìgbàkigbà tí òǹgbẹ bá ń gbẹ mí, mo máa ń rò ó pé ó ṣeé ṣe kí òun náà fẹ́ láti mu omi. Tí mo bá fẹ́ lọ gbatẹ́gùn níta, mo máa ń bi í bóyá òun náà á fẹ́ láti bá mi lọ. A jọ ń jẹ ìrora, a sì jọ ń fara da àìsàn náà.”
Tó bá sì jẹ́ pé ìwọ ni ẹnì kejì rẹ ń tọ́jú, ṣé àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe fúnra rẹ tí kò sì ní pa ìlera rẹ lára? Èyí lè jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà wúlò, ó sì tún lè fún ẹnì kejì rẹ níṣìírí láti máa tọ́jú rẹ.
Dípò tí wàá fi rò pé o mọ ohun tó o lè ṣe tó máa fi hàn pé ò ń gba ti ẹnì kejì rẹ rò, o ò ṣe béèrè ohun tó o lè ṣe lọ́wọ́ rẹ̀ tó lè múnú rẹ̀ dùn? Nígbà tó yá, Nancy tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ fún ọkọ rẹ̀ torí bí òun kò ṣe mọ ipò tí ìṣúnná owó ìdílé àwọn wà. Ní báyìí, ọkọ rẹ̀ ti wá ń ṣàlàyé bí nǹkan ṣe ń lọ sí lórí ọ̀rọ̀ náà fún un.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kọ àwọn ọ̀nà tó o rò pé ẹnì kejì rẹ lè gbà mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún ẹ ní ipò tó o wà yìí, kó o sì ní kí ẹnì kejì rẹ náà ṣe bákan náà. Lẹ́yìn náà, gba ohun tí ẹnì kejì rẹ kọ, kó o sì fún un ní tìẹ. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín wá mú ọ̀kan tàbí méjì tẹ́ ẹ ronú pé ẹ̀yin méjèèjì lè ṣiṣẹ́ lé lórí nínú àwọn ohun tẹ́ ẹ ti kọ náà.
Ẹ Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” (Oníwàásù 3:1) Àmọ́, ó lè má rọrùn láti máa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì torí ìṣòro tí àìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀ lè ní lórí àwọn ohun tí ìdílé máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Kí lo lè ṣe kó o lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì dé ìwọ̀n àyè kan?
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ lè máa gbé ọ̀ràn àìlera tí kò lọ bọ̀rọ̀ kúrò lọ́kàn. Ṣé ẹ ṣì lè ṣe àwọn nǹkan tí ẹ jọ máa ń ṣe kó tó di pé àìsàn bẹ̀rẹ̀? Tí kò bá ṣeé ṣe mọ́, ṣé ohun míì wà tẹ́ ẹ lè gbìyànjú rẹ̀ wò? Ó lè jẹ́ nǹkan tó rọrùn bíi kẹ́ ẹ máa kàwé síra yín létí tàbí èyí tó gba iṣẹ́ díẹ̀ bíi kẹ́ ẹ kọ́ èdè tuntun. Tẹ́ ẹ bá jọ ń ṣe àwọn ohun tí àìlera kò dí yín lọ́wọ́ láti ṣe pa pọ̀, ìyẹn máa fún un yín lókun gẹ́gẹ́ bí ẹran ara kan náà, ó sì máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ láyọ̀.
Ohun míì tó lè jẹ́ kẹ́ ẹ gbé ìṣòro náà kúrò lọ́kàn ni pé kẹ́ ẹ máa wà láàárín àwọn èèyàn. Bíbélì sọ nínú ìwé Òwe 18:1 pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” Ṣé ẹ kíyè sí pé ẹsẹ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé yíya ara ẹni sọ́tọ̀ lè ní ipa tí kò dáa lórí ọkàn wa? Àmọ́ bíbá àwọn èèyàn kẹ́gbẹ́ lè mú kí ara yín yá gágá, ó sì lè jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ máa ronú lọ́nà tó já geere. Ẹ ò ṣe dìídì pe ẹnì kan pé kó wá kí yín nílé?
Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún ẹni tó ń tọ́jú ẹnì kejì láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn kan máa ń wa iṣẹ́ tó pọ̀ mọ́ àyà, ìyẹn máa ń jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀ wọ́n, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣàkóbá fún ìlera wọn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó lè má ṣeé ṣe fún wọn láti máa tọ́jú olólùfẹ́ wọn mọ́. Torí náà, tó o bá ń tọ́jú ọkọ tàbí aya rẹ tó ní àìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀, má ṣe c Àwọn kan ti kíyè sí pé ìlera àwọn túbọ̀ máa ń dáa sí i tí àwọn bá sọ ohun tó jẹ́ àníyàn àwọn lóòrèkóòrè fún ọ̀rẹ́ kan tó ṣeé fọkàn tán, tó sì jẹ ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn.
gbàgbé àwọn ohun tí ìwọ náà nílò. Máa wá àyè láti sinmi déédéé.GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kọ àwọn ìṣòro tó ò ń ní bó o ṣe ń bójú tó ọkọ tàbí aya rẹ. Lẹ́yìn náà, kọ àwọn ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà tàbí àwọn ohun tó lè túbọ̀ jẹ́ kó o máa fara dà á. Dípò kó o máa ronú ju bó ṣe yẹ lọ nípa àwọn ìṣòro náà, bi ara rẹ pé, ‘Kí ni ohun tó rọrùn jù lọ tó sì dájú pé mo lè ṣe láti mú kí nǹkan sàn sí i?’
Ẹ Máa Ní Èrò Tó Dára
Bíbélì kìlọ̀ pé: “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’” (Oníwàásù 7:10) Torí náà, má ṣe máa ronú lórí bí nǹkan ì bá ṣe rí ká sọ pé kò sí àìsàn. Má gbàgbé pé kò sí ayọ̀ tí kò níbi tó mọ nínú ayé yìí. Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí, kó o sì máa fara dà á.
Kí ló lè ran ìwọ àti ẹnì kejì rẹ lọ́wọ́ nírú ipò yìí? Ẹ jọ máa jíròrò àwọn ìbùkún tẹ́ ẹ ti rí gbà. Jẹ́ kí inú rẹ dùn nígbàkigbà tí ìlera rẹ bá sunwọ̀n sí i, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé kò tó nǹkan. Tún ronú nípa àwọn ohun míì tó o lè máa retí, kó o sì ní àfojúsùn tí ọwọ́ yín á lè tẹ̀.
Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Shoji àti Akiko ti fi ìmọ̀ràn tá a sọ yìí sílò, wọ́n sì ti ṣe àṣeyọrí sí rere. Nígbà tí àyẹ̀wò fi hàn pé Akiko ní àìsàn tó máa ń mú kí iṣan àti ẹran ara roni, wọ́n ní láti fi àǹfààní pàtàkì kan tí wọ́n ní sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tó ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti wàásù. Ṣé èyí bà wọ́n nínú jẹ́? Kò lè ṣàìrí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara. Síbẹ̀ Shoji gba ẹnikẹ́ni tó bá wà nírú ipò yìí níyànjú pé: “Má ṣe kó ìbànújẹ́ bá ara rẹ nípa ríronú lórí àwọn ohun tí o kò lè ṣe mọ́. Máa ní èrò tó dára. Kódà tẹ́ ẹ bá ní ìrètí pé, lọ́jọ́ kan, ẹ ṣì máa pa dà sídìí ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe tẹ́lẹ̀, ẹ pọkàn pọ̀ sórí bí nǹkan ṣe rí fún yín lọ́wọ́lọ́wọ́. Ohun tí ìyẹn sì túmọ̀ sí fún mi ni pé kí n máa fún ìyàwó mi ní àfiyèsí, kí n sì máa ràn án lọ́wọ́.” Irú ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ yìí lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ bá nílò àbójútó àrà ọ̀tọ̀.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
b Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò àwọn ipò tó lè jẹ yọ tí ọkọ tàbí aya ẹni bá ń ṣàìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀. Àmọ́ àwọn tọkọtaya tí ọ̀kan nínú wọn bá ń ṣàìsàn torí jàǹbá tàbí tí wọ́n ní ìdààmú ọ̀kan irú bí ìrẹ̀wẹ̀sì, náà lè jàǹfààní tí wọ́n bá fi àwọn ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí sílò.
c Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó sinmi lórí bí ipò rẹ bá ṣe rí, ì bá dára ní ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó o bá lè máa lọ rí àwọn oníṣègùn tó mọṣẹ́ dunjú tàbí àwọn tó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìlera, tí wọ́n bá wà ní àdúgbò rẹ.
BI ARA RẸ PÉ . . .
Kí ni nǹkan tó yẹ kí èmi àti ọkọ tàbí aya mi máa ṣe nísinsìnyí?
▪ Ká máa fìgbà gbogbo sọ̀rọ̀ nípa àìlera náà
▪ Ká má ṣe máa sọ̀rọ̀ nípa àìlera náà nígbà gbogbo
▪ Ká má ṣe máa dààmú ara wa púpọ̀ jù
▪ Ká túbọ̀ máa gba ti ara wa rò
▪ Ká má ṣe jẹ́ kí àìsàn gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ, ká sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnì kejì wa máa jẹ wá lógún
▪ Ká túbọ̀ máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn
▪ Ká ní àfojúsùn kan náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kẹ́ ẹ lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ṣé ẹ lè jọ máa ṣe eré ìdárayá?