Ìrìn Àjò Tó Gbé Wa Pa Dà Sí Ìgbà Àtijọ́
Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Ìrìn Àjò Tó Gbé Wa Pa Dà Sí Ìgbà Àtijọ́
FOJÚ inú wo bí ayọ̀ rẹ á ṣe pọ̀ tó láti rìnrìn àjò lọ wo bí àwọn baba ńlá rẹ ṣe gbé ìgbésí ayé wọn nígbà àtijọ́. Bí ìrìn àjò tá a rìn ṣe rí gan-an nìyẹn. Láti orílẹ̀-èdè Switzerland la ti lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé gbogbo ọ̀nà ni ọ̀làjú ti gbà dé bá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àmọ́ ìrìn àjò wa gbé wa pa dà sí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì [200] sẹ́yìn. Ẹ gbọ́ bó ṣe rí bẹ́ẹ̀.
Torí pé à ń sọ èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Swiss German, wọ́n ké sí wa pé ká wá lo oṣù mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Indiana. Ohun tó wà lọ́kàn wa ni pé, a máa wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìdílé Amish, èdè àwọn baba ńlá wọn ni àwọn èèyàn yìí ṣì ń sọ. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìdílé yìí ló ń gbé ní ìpínlẹ̀ Indiana.
Ìdílé Amish jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn Ánábatíìsì tó wà ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún. Látinú orúkọ Jacob Amman tó jẹ́ aṣáájú wọn tó gbé lórílẹ̀-èdè Switzerland ni wọ́n ti mú orúkọ wọn. Ohun tí àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí kọ́ nínú Bíbélì nígbà yẹn mú kí wọ́n gbà pé kò tọ̀nà láti máa ṣèrìbọmi fún ọmọ ọwọ́, kò sì yẹ kí àwọn èèyàn máa ṣiṣẹ́ ológun. Ìjọba ṣe inúnibíni sí wọn nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Wọ́n tiẹ̀ pa àwọn kan lára wọn torí ìgbàgbọ́ wọn. Nígbà tó yá, inúnibíni náà ń pọ̀ sí i, èyí sì mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn sá lọ sí apá ibòmíì ní orílẹ̀-èdè Switzerland àti orílẹ̀-èdè Faransé. Nígbà tó sì fi máa di ìdajì ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú wọn ló ti sá lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Síbẹ̀ náà, wọn kò gbàgbé àṣà àti èdè ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn èdè ìbílẹ̀ Swiss German.
Nígbà tá a dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn oníwà jẹ́jẹ́ yìí, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wọn láti rí i pé à ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn! Fọkàn yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀.
Wọ́n fi èdè ìbílẹ̀ wọn bi wá pé, “Báwo ló ṣe jẹ́ tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ bíi tiwa?”
A dá wọn lóhùn pé, “Torí pé orílẹ̀-èdè Switzerland la ti wá?”
Ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé, “Àmọ́ ẹ kì í ṣe ara ìdílé Amish!”
Ọ̀pọ̀ wọn ló gbà wá sílé, èyí sì fún wa láǹfààní láti rí irú ìgbésí ayé tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn ti gbé láyé àtijọ́. Dípò iná ìjọba, àtùpà elépo ni wọ́n ń lò, dípò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ tí wọ́n máa ń so mọ́ ẹṣin ni wọ́n ń gùn, dípò omi ẹ̀rọ, kànga àti ẹ̀rọ tí wọ́n ń fi ẹ̀fúùfù yí ni wọ́n ń lò, dípò rédíò, orin ni wọ́n máa ń kọ.
Ohun tó jọ wá lójú jù lọ nípa àwọn tá a lọ kí yìí ni pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn. Ọ̀pọ̀ ìdílé Amish ló máa ń rí i pé àwọn ka Bíbélì lójoojúmọ́, wọ́n sì fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Èyí sì jẹ́ ká lè bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọ́run fún ẹ̀dá èèyàn àti fún ilẹ̀ ayé.
Kò pẹ́ tí òkìkí fi kàn káàkiri àgbègbè náà pé àwọn àlejò kan láti orílẹ̀-èdè Switzerland wà láàárín wọn. Ọ̀pọ̀ ló sọ pé kí a wá kí àwọn ìbátan
wọn, a sì ṣe bẹ́ẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Inú wa dùn gan-an, ojú wa sì wà lọ́nà nígbà tí wọ́n sọ pé kí á wá sí iléèwé àwọn Amish. Ó sì ń ṣe wá bíi pé ká ti débẹ̀.Nígbà tá a dé iléèwé náà, a kan ilẹ̀kùn. Lójú ẹsẹ̀, olùkọ́ náà ṣí ilẹ̀kùn, ó sì sọ pé ká wọnú kíláàsì níbi ti èèyàn méjìdínlógójì [38] ti tẹjú mọ́ àwa mẹ́rin, tí wọ́n sì ń retí ohun tá a máa sọ. Ibi kan náà ni wọ́n kó àwọn ọmọ kíláàsì mẹ́jọ sí, ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà sì jẹ́ ọdún méje sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Aṣọ búlúù ni àwọn obìnrin wọn wọ̀, wọ́n sì dé fìlà funfun, àwọn ọkùnrin wọn wọ ṣòkòtò dúdú àti ṣẹ́ẹ̀tì búlúù. Òrùlé ilé náà ga gan-an. Ọ̀dà búlúù ni wọ́n fi kun ògiri kíláàsì náà ní ìhà mẹ́ta, ara ògiri tó wà níwájú ni wọ́n ń kọ̀wé sí. Àwòrán-ilẹ̀ àgbáyé tí wọ́n yà sára bọ́ọ̀lù àtèyí tó wà lórí ìwé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú kíláàsì náà. Sítóòfù onírin ńlá kan sì tún wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.
Bá a ṣe jókòó síwájú kíláàsì náà, ńṣe ni àwọn ọmọ náà ń wò wá tí wọ́n sì ń hára gàgà láti gbọ́ ohun tá a fẹ́ sọ. Nígbà tó yá, olùkọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn tó wà nínú kíláàsì kọ̀ọ̀kan wá sí ibi tó jókòó sí, ó sì ń béèrè ìbéèrè lórí iṣẹ́ àmúrelé wọn. Ẹnú yà wá, nígbà tí olùkọ́ náà béèrè ìbéèrè nípa Swiss Alps, ìyẹn òkè kan tó ga gan-an lórílẹ̀-èdè Switzerland, lọ́wọ́ àwọn ọmọ náà. Àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ náà ti gbó gan-an, olùkọ́ náà bi wá pé ṣé orílẹ̀-èdè Switzerland ṣì wà bí ìwé tó sọ nípa rẹ̀ ṣe ṣàlàyé rẹ̀. Ṣé àwọn màlúù ṣì máa ń lọ sórí òkè tí koríko wà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn láti lọ jẹko? Àbí yìnyín ṣì máa ń wà lórí àwọn òkè yìí? Olùkọ́ náà bú sí ẹ̀rín nígbà tá a fi fọ́tò òkè tí yìnyín bò mọ́lẹ̀ tó jẹ́ aláwọ̀ mèremère tá a yà hàn án láti ti àwòrán yìnyín aláwọ̀ dúdú àti funfun tó wà lórí ìwé náà lẹ́yìn.
Ìyàwó olùkọ́ yìí máa ń ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ ní iléèwé náà, obìnrin yìí béèrè ìbéèrè gan-an, ó ní, “Ṣé ẹ lè fi ohùn dárà?” A dáhùn pé rárá. A mọ̀ pé àwọn Amish mọ orin kọ dáadáa, wọ́n sì mọ bí èèyàn ṣe máa ń fi ohùn dárà, torí náà, a ní kí wọ́n kọrin fún wa. Wọ́n gbà, àwọn ogójì ló kọrin fún wa, a sì ń wò wọ́n tìyanutìyanu. Lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà ní kí àwọn ọmọ náà lọ ṣeré.
Lẹ́yìn èyí, ìyàwó olùkọ́ náà ní ká ṣáà kọ orin kan fún àwọn. Tóò, a gbà láti kọrin torí pé àwa náà mọ ọ̀pọ̀ orin ìbílẹ̀ lédè Swiss German. Ó ti dé etí ìgbọ́ àwọn ọmọ tó ń ṣeré lórí pápá pé à ń kọrin, ká sì tó ṣẹ́jú pẹ́ wọ́n ti pa dà dé sínú kíláàsì. A dúró níwájú kíláàsì náà, a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé a kọrin fún wọn.
Lẹ́yìn náà, ìdílé Amish kan tó jẹ́ ẹlẹ́ni méjìlá ní ká wá jẹun ọ̀sán lọ́dọ̀ àwọn. Lórí tábìlì onígi gígùn kan ni wọ́n kó oúnjẹ aṣaralóore sí, irú bí ànàmọ́ gígún, itan ẹlẹ́dẹ̀, àgbàdo, búrẹ́dì, wàràkàṣì, ewébẹ̀, oúnjẹ yíyan àti àwọn nǹkan tí èèyàn máa ń jẹ lé oúnjẹ. Ká tó jẹun, ẹnì kọ̀ọ̀kan gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Bá a ṣe ń bu oúnjẹ, à ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè Switzerland tó jẹ́ ilẹ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa bí ìgbésí ayé wọn ṣe rí nínú oko tí wọ́n ń gbé yìí. Ńṣe ni àwọn ọmọ wọn ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ tí wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín kèékèé títí tá a fi jẹun tán. Nígbà tí gbogbo wa ti jẹun tán, a tún gbàdúrà lẹ́ẹ̀kejì, ohun tí èyí sì túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ wọn ni pé wọ́n lè dìde, àmọ́ kì í ṣe láti lọ ṣeré. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ohun tó yẹ kó ṣe láti lè mú kí tábìlì àti àwọn àwo wà ní mímọ́, ìyẹn sì gba pé kí wọ́n pọn omi, kí wọ́n sì gbé e ka iná.
Àwọn òbí wọn ní ká máa bọ̀ nínú pálọ̀ nígbà tí àwọn ọmọ náà ń fọ àwo lọ́wọ́. Kò sí àga ìnàyìn, àmọ́ a jókòó sórí àga tí wọ́n figi ṣe. Wọ́n gbé ògbólógbòó Bíbélì kan jáde látinú kọ́bọ́ọ̀dù, èdè Jámánì ni wọ́n fi kọ ọ́, bó sì ṣe máa ń rí nínú ìdílé àwọn Amish, a bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ni Jèhófà Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé àti ẹ̀dá èèyàn? Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn ọlọ́kàn tútù ló máa jogún ayé? Ṣé Ọlọ́run ní i lọ́kàn láti fi iná jẹ èèyàn níyà títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì? Àwọn wo ló ń pa àṣẹ Jésù pé ká wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé mọ́? Bá a ṣe jíròrò àwọn ìbéèrè yìí àti àwọn míì pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ní Bíbélì lọ́wọ́ yìí múnú wa dùn gan-an ni.
Tayọ̀tayọ̀ la fi máa ń rántí ìrìn àjò tó gbé wa pa dà sí ìgbà àtijọ́ yìí, torí ó kún fún oríṣiríṣi ìrírí tó yani lẹ́nu. A nírètí, a sì gbà á ládùúrà pé kí àwọn èèyàn yìí ṣe ju gbígbọ́ ọ̀rọ̀ tá a bá wọn sọ lédè ìbílẹ̀ Swiss German lọ, àmọ́ kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.