Ibo Ni Ọlọ́run Wà?
Ibo Ni Ọlọ́run Wà?
September 11, 2001: Ní aago mẹ́sàn-án ku ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá àárọ̀, ọkọ̀ òfuurufú akérò kan kọ lu ilé gogoro, ìyẹn Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé tó wà ní ìlú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èyí ni àkọ́kọ́ lára ìgbéjàkoni tí àwọn aṣekúpani fi ṣọṣẹ́ níbẹ̀. Lẹ́yìn wákàtí kan ó lé ìṣẹ́jú méjìlélógójì, ẹ̀mí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn ti ṣòfò.
December 26, 2004
Ìsẹ̀lẹ̀ alágbára kan, ìyẹn ilẹ̀ ríri tó wáyé nínú Òkun Íńdíà fa ìgbì omi aṣekúpani, èyí tó mú kí omi ya lu orílẹ̀-èdè mọ́kànlá, tó fi mọ́ ilẹ̀ Áfíríkà tó fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún kìlómítà jìnnà síbẹ̀. Ìsẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ìwọ̀n 9.0 lórí òṣùwọ̀n Richter. Láàárín ọjọ́ kan péré, àròpọ̀ iye àwọn èèyàn tó kú tàbí tí wọ́n sọ nù jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000], tí àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan sì di aláìnílé lórí.
August 1, 2009: Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógójì àti ọmọkùnrin rẹ̀ ọmọ ọdún márùn-ún ń sáré orí yìnyín, ni wọ́n bá lọ ta lu ibi ìgbọ́kọ̀sí kan. Bàbá náà kú. Ọmọ rẹ̀ kò kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ ó kú lọ́jọ́ kejì. Àwọn ẹbí wọn tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò sọ pé: “A rò pé iṣẹ́ ìyanu kan máa ṣẹlẹ̀ ni, tá á sì yè é.”
Nígbà tó o bá kà nípa àwọn aṣekúpani tàbí àwọn àjálù lóríṣiríṣi tàbí kẹ̀, nígbà tí àjálù bá bá ìwọ alára, ǹjẹ́ o máa ń béèrè pé, ṣé Ọlọ́run ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? Ǹjẹ́ o máa ń ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run ti pa wá tì? Bíbélì fúnni ní ìdáhùn tó ń tuni nínú, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
© Àwọn fọ́tò tí Dieter Telemans/Panos yà
Àwọn fọ́tò tí PRAKASH SINGH/AFP/Getty yà
© Àwọn fọ́tò tí Dieter Telemans/Panos yà