Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí ni Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Kí ni Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí ni Gbọ̀ngàn Ìjọba?

▪ Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ilé ìjọsìn kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò fún ìjọsìn wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba ló wà káàkiri ayé. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [105,000] lọ máa ń pàdé nínú irú àwọn gbọ̀ngàn bẹ́ẹ̀.

Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan máa ń ní yàrá àpéjọ kan tí wọ́n ti máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ti máa ń sọ àsọyé Bíbélì. Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ yàrá àpéjọ náà, ibi tó gá sókè díẹ̀ ni wọ́n fi máa ń ṣe pèpéle, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ń darí ìpàdé. Iye ìjókòó tó wà nínú yàrá àpéjọ náà sábà máa ń gba ọgọ́rùn-ún sí ọ̀ọ́dúnrún [100 sí 300] èèyàn. Gbọ̀ngàn Ìjọba tún lè ní kíláàsì kan tàbí méjì, ọ́fíìsì kan àti yàrá ìkàwé kékeré kan tó ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé míì tí ọmọ ìjọ lè lò láti fi ṣèwádìí.

Àmọ́ ṣá o, nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, èèyàn kò lè rí àwọn ère àti pẹpẹ èyí táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa ń lò. Kò sí pẹpẹ, ère tàbí àgbélébùú kankan níbẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé lílo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ta ko àṣẹ tí Bíbélì pa fún wa pé ká “sá fún ìbọ̀rìṣà.” (1 Kọ́ríńtì 10:14; Jòhánù 4:24) Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì àti tẹ́ńpìlì ni wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì. Àmọ́, ti Gbọ̀ngàn Ìjọba yàtọ̀ o, a kọ́ ọ lọ́nà tó mọ níwọ̀n tó sì wúlò. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a fẹ́ máa kọ́ nínú ilé náà ló ṣe pàtàkì kì í ṣe bí ọ̀ṣọ́ tó wà lára ilé náà ṣe pọ̀ tó.

Kí nìdí tá a fi ń pè é ní Gbọ̀ngàn Ìjọba? Ìdí ni pé ẹ̀kọ́ tó dá lórí Bíbélì àti ohun pàtàkì tó wà nínú rẹ̀, ìyẹn ọ̀rọ̀ nípa “ìjọba Ọlọ́run,” èyí tí ẹ̀kọ́ Jésù dá lé ni àwọn tó ń péjọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wá ń kọ́ níbẹ̀. (Lúùkù 4:43) Nítorí náà, orúkọ náà, Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí tí wọ́n mú jáde lẹ́yìn ọdún 1930, ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi kọ́ àwọn ilé náà, èyí tó jẹ́ láti gbé ìjọsìn mímọ́ ga àti láti jẹ́ ibi tá à ń péjọ sí ká tó lọ wàásù “ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 24:14) Nítorí ìdí yìí, a kì í lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún nǹkan tí kò jẹ mọ́ ti ìjọsìn, bẹ́ẹ̀ ni a kì í lò ó fún ìṣòwò. Owó ọrẹ la fi ń kọ́ ọ, òun náà la sì fi ń tọ́jú rẹ̀. Àmọ́, a kì í gbégbá ọrẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpótí tí a gbé síbì kan wà fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fi ọrẹ owó sínú rẹ̀.

Ohun kan náà là ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún káàkiri ayé, àmọ́, ọ̀nà tó yàtọ̀ là ń gbà kọ́ wọn, wọn kò sì tóbi bákan náà. Ohun tó mú kí ìrísí wọn yàtọ̀ síra ni ohun èlò ìkọ́lé tó wà ní àdúgbò kan, ojú ọjọ́ àti bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè kan bá ṣe lówó lọ́wọ́ tó. Bíríkì, igi àti òkúta ni wọ́n fi kọ́ àwọn kan. Àwọ́n míì sì rèé, ọparun ni wọ́n fi kọ́ wọn, ìmọ̀ ọ̀pẹ ni wọ́n sì fi bò wọ́n lórí.

A máa ń fìdùnnú gba àwọn àlejò tí wọ́n wá sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Hébérù 10:25) Kódà, a máa ń ṣe ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, gbogbo èèyàn ló sì wà fún. Ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ máa ń dá lórí Bíbélì, ẹ̀kọ́ náà sì wà fún àwọn ọmọ ìjọ àtàwọn àlejò tó bá wá. O ò ṣe lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní àdúgbò rẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Màláwì, Áfíríkà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

England, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì