Bó O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọ̀rẹ́ Rẹ Kan Tó Ń Ṣàìsàn
Bó O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọ̀rẹ́ Rẹ Kan Tó Ń Ṣàìsàn
ǸJẸ́ ó ti ṣe ẹ́ rí pé o kò mọ ohun tó o fẹ́ sọ nígbà tó ò ń bá ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń ṣàìsàn sọ̀rọ̀? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè borí ìṣòro yìí. Lọ́nà wo? Èèyàn lè ṣe é ní onírúurú ọ̀nà. Àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra lè mú kí ohun tẹ́nì kan máa ṣe yàtọ̀. Ìwà àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, èyí tún lè mú kí ọ̀nà tá a máa gbà ṣe é yàtọ̀ gan-an. Tórí náà, ohun tó máa mú kí ara tu aláìsàn kan lè máà wúlò fún aláìsàn míì. Àti pé bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹni tó ń ṣàìsàn lè máà dúró sójú kan.
Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o gbìyànjú láti fi ara rẹ sípò ẹni náà, kó o sì ronú lórí ohun tí ẹni náà fẹ́ àti ohun tó fẹ́ kó o ṣe fún òun. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Àwọn àbá díẹ̀ rèé látinú ìlànà Bíbélì.
Máa fetí sílẹ̀ dáadáa
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:
“Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—JÁKỌ́BÙ 1:19.
“Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.”—ONÍWÀÁSÙ 3:1, 7.
◼ Tó o bá lọ wo ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn, fetí sílẹ̀ dáadáa, kó o sì bá a kẹ́dùn. Má ṣe yára láti gbà á níyànjú tàbí kó o rò pé gbogbo ohun tó bá sọ lo máa wá ojútùú sí. Torí bó o ṣe ń kánjú sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ, o lè sọ ohun tó máa bí ọ̀rẹ́ rẹ nínú láìmọ̀. Ẹni tó ń ṣàìsàn kò fi dandan retí ìdáhùn lọ́dọ̀ ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀, ẹni tó máa fetí sí i tọkàntọkàn ló ń fẹ́.
Jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fàlàlà. Má ṣe já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ ọn lẹ́nu, má sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa fi hàn pé ohun tó ń ṣe é kò le tó bó ṣe rò. Emílio sọ pé, “Mo ní àrùn yírùnyírùn, kò sì jẹ́ kí ojú mi ríran. a Nígbà míì, ìbànújẹ́ máa ń dorí mi kodò, àwọn ọ̀rẹ́ mi sì máa ń tù mí nínú pé: ‘Ìwọ nìkan kọ́ nírú rẹ̀ ń ṣe. Àwọn míì wà tí tiwọn burú ju tìẹ lọ.’ Àmọ́, wọn kò mọ̀ pé bí àwọn ṣe fojú kéré ìṣòro mi yìí kò ràn mí lọ́wọ́ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbànújẹ́ tó lékenkà ló ń kó bá mi.”
Jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fàlàlà láì bẹ̀rù pé wàá rí nǹkan wí sí òun. Tó bá sọ fún ẹ pé ẹ̀rù ń ba òun, dípò tí wàá fi sọ pé kó má bẹ̀rù, ńṣe ni kó o gbà pẹ̀lú rẹ̀. Eliana tó ní àrùn jẹjẹrẹ sọ pé: “Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí, tí mo sì ń sunkún gan-an nítorí ipò tí mo wà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé mi ò gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run mọ́.” Gbìyànjú láti fojú tí ọ̀rẹ́ rẹ fi ń wo ara rẹ̀ wò ó, kì í ṣe ojú tí ìwọ fi ń wò ó. Má gbàgbé pé ohun tó o bá sọ lè tètè múnú bí i ní báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Ní sùúrù. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ nǹkan kan náà ló ń sọ ṣáá, ìwọ sáà tẹ́tí gbọ́ tiẹ̀. (1 Àwọn Ọba 19:9, 10, 13, 14) Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló fẹ́ láti sọ ohun tó ń ṣe é fún ẹ.
Máa fọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:
“Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.”—RÓÒMÙ 12:15.
“Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—MÁTÍÙ 7:12.
◼ Fi ara rẹ sípò ọ̀rẹ́ rẹ. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ, tó bá ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ tàbí tó bá ń retí èsì àyẹ̀wò, ó lè máa ṣàníyàn, kí ìyẹn sì kó ìdààmú bá a. Gbìyànjú láti mọ̀ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn, kó o sì fara mọ́ bí ìmọ̀lára rẹ̀ ṣe yí pa dà. Kì í ṣe àkókò nìyí láti béèrè ìbéèrè tó pọ̀, àgàgà nípa ọ̀ràn tó kà sí àṣírí tirẹ̀.
Onímọ̀ nípa ìrònú àti ìhùwàsí ẹ̀dá, Ana Katalifós, tó ń ṣiṣẹ́ nílè ìwòsàn kan sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn aláìsàn sọ nípa àìsàn wọn nígbà tó bá wù wọ́n àti lọ́nà tó wù wọ́n. Nígbà tó bá wù wọ́n láti sọ̀rọ̀, bá wọn sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tí wọ́n bá dánu lé. Àmọ́ tí wọn ò bá fẹ́ láti sọ̀rọ̀, o lè rọra jókòó, kó o má sì sọ̀rọ̀, dídi ẹni náà mú lọ́nà tó fìfẹ́ hàn lè ṣe é láǹfààní gan-an. Tàbí kó jẹ́ pé ohun tí wọ́n nílò ni pé kéèyàn bá wọn kẹ́dùn.”
Tí ọ̀rẹ́ rẹ bá pe ọ̀ràn kan ní àṣírí, bá a mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀. Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Rosanne Kalick, tó ti ní àrùn jẹjẹrẹ nígbà méjì, tó sì ti rí ìwòsàn, sọ pé: “Gbà pé ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn sọ fún ẹ jẹ́ àṣírí. Àyàfi tí wọ́n bá sọ fún ẹ pé kó o gbẹnu sọ fún ìdílé aláìsàn náà nìkan ni kó o sọ̀rọ̀. Béèrè ohun tí aláìsàn náà fẹ́ kó o sọ fún àwọn èèyàn.” Edson, tó ní àrùn jẹjẹrẹ, tó sì ti rí ìwòsàn sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi kan tàn án kálẹ̀ pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ àti pé mi ò ní pẹ́ kú. Òótọ́ ni pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe iṣẹ́ abẹ ni. Mo mọ̀ pé mo lárùn jẹjẹrẹ, àmọ́ èsì àyẹ̀wò ni mò ń dúró dè láti mọ ohun tó fa àìlera náà. Nígbà tí èsì jáde, àrùn jẹjẹrẹ náà kò tíì ràn lọ sí apá ibòmíì. Àmọ́ ohun tí kì í ṣe òótọ́ tí ọ̀rẹ́ mi tàn kálẹ̀ ti ba nǹkan jẹ. Inú ìyàwó mi bà jẹ́ gan-an nítorí ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ àtàwọn ìbéèrè tí wọ́n ń bi wá láì ro bí ipò náà ṣe rí lára wa.”
Bí ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ronú lórí irú ìtọ́jú tó fẹ́ gbà, má ṣe tètè sọ ohun tí ìwọ máa ṣe fún un tó bá jẹ́ pé ìwọ lo wà ní ipò rẹ̀. Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Lori Hope, tó ní àrùn jẹjẹrẹ, tó sì ti rí ìwòsàn sọ pé: “Kó o tó fi àpilẹ̀kọ tàbí ìròyìn èyíkéyìí nípa àrùn jẹjẹrẹ ránṣẹ́ sí ẹnì kan tó ń gba ìtọ́jú àrùn náà tàbí ẹni tó ti rí ìwòsàn àrùn náà gbà, á dára kó o kọ́kọ́ béèrè láti mọ̀ bóyá onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ sí i. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, aájò tí ìwọ rò pé ò ń ṣe yẹn lè bí ọ̀rẹ́ rẹ nínú, o sì lè má mọ̀.” Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń fẹ́ ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa oríṣiríṣi ìtọ́jú ìṣègùn.
Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni ìwọ àti aláìsàn náà, o kò gbọ́dọ̀ pẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ̀ tó o bá lọ kí i. Ó dára gan-an bó o ṣe lọ kí i, àmọ́ ó lè má ṣe ọ̀rẹ́ rẹ bíi kó bá ẹ sọ̀rọ̀. Ó lè ti rẹ̀ ẹ́, kó má sì lágbára tó pọ̀ tó láti sọ̀rọ̀ tàbí gbọ́ ohun tí ẹnì kan ń bá a sọ fún àkókò gígùn. Lẹ́sẹ̀ kan náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ ronú pé ńṣe ni ò ń kánjú tó o bá ti wá sọ́dọ̀ òun. Ó yẹ kó o jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn mọ̀ pé o bìkítà nípa òun.
Bá a bá ń gba tẹni rò, ó tún yẹ ká máa lo ọgbọ́n àti làákàyè. Bí àpẹẹrẹ, kó o tó se oúnjẹ lọ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń ṣàìsàn tàbí kó o tiẹ̀ tó mú òdòdó lọ fún un, o lè béèrè àwọn nǹkan tí kò bá a lára mu. Bí ara rẹ kò bá yá, bóyá tí òtútù bá ń mú ẹ tàbí tí ọ̀fìnkìn ń ṣe ẹ́, á dára kó o jẹ́ kí ara rẹ yá kó o tó lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn.
Máa gbéni ró
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:
“Ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.”—ÒWE 12:18.
“Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—KÓLÓSÈ 4:6.
◼ Tó o bá ní èrò tó dára nípa ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn, àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ máa fi èyí hàn. Máa ronú pé ọ̀rẹ́ rẹ ṣì jẹ́ irú ẹni tó jẹ́ àti pé àwọn ànímọ́ tó mú kó o sún mọ́ ọn ṣì wà lára rẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí àìlera ọ̀rẹ́ rẹ mú kó o yẹra láti máa báa ṣe nǹkan pọ̀ bẹ́ ẹ ṣe jọ ń ṣe tẹ́lẹ̀. Tó o bá ń bá ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ bíi pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti kọjá àtúnṣe, òun náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Roberta, tó ní àrùn egungun tó légbá kan sọ pé: “Ẹ bá mi lò bí èèyàn gidi. Aláàbọ̀ ara ni mí lóòótọ́, àmọ́ mo ní èrò tèmi àtohun tí mo fẹ́. Ẹ má fojú ẹni tá à ń káàánú fún wò mí. Ẹ má sọ̀rọ̀ sí mi bíi pé arìndìn ni mí.”
Rántí pé kì í ṣe ohun tó o sọ nìkan ló ṣe pàtàkì, ọ̀nà tó o gbà sọ ọ́ tún ṣe pàtàkì. Ohùn tó o fi sọ ọ́ ń kó ipa pàtàkì kan pẹ̀lú. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí àyẹ̀wò fi hàn pé Ernesto ní àrùn jẹjẹrẹ, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan pè é láti orílẹ̀-èdè míì, ó sọ pé: “O ní àrùn jẹjẹrẹ kẹ̀!” Ernesto rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Bí ọ̀rẹ́ mi ṣe tẹnu mọ́ ‘o’ àti ‘àrùn jẹjẹrẹ’ yẹn kó ìbànújẹ́ bá mi gan-an.”
Òǹkọ̀wé náà, Lori Hope tún sọ àpẹẹrẹ míì pé: “Bíbéèrè pé ‘Báwo ni?’ lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi nǹkan lọ́dọ̀ aláìsàn. Ìyẹn sì sinmi lórí ohùn ẹni tó béèrè, bó ṣe ṣe nígbà tó béèrè, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú aláìsàn náà, ibi tó mọ̀ ọ́n dé àti àkókò tó béèrè ìbéèrè náà, ìbéèrè yìí lè mú kí ara tu aláìsàn náà, ó lè dá kún ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ tàbí kó mú kí ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà á.”
Ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń ṣàìsàn lè fẹ́ káwọn èèyàn fi hàn pé wọ́n bìkítà nípa òun, pé wọ́n lóye òun àti pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún òun. Torí náà, jẹ́ kó dá a lójú pé o kò fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeré àti pé wàá dúró tì í. Rosemary, tí kókó ọlọ́yún wà nínú ọpọlọ rẹ̀ sọ pé: “Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi àti pé ohunkóhun tíì báà ṣẹlẹ̀, àwọn kò ní fi mí sílẹ̀.”—Òwe 15:23; 25:11.
Máa ranni lọ́wọ́
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:
“Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 JÒHÁNÙ 3:18.
◼ Ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn nílò á máa yàtọ̀ síra látìgbà tí àyẹ̀wò bá ti fi hàn pé ó ní àrùn kan àti nígbà tó bá ń gba ìtọ́jú. Àmọ́ ní gbogbo àkókò yìí, ó lè nílò ìrànlọ́wọ́. Dípò tí wàá fi sọ pé, “tó o bá nílò ohunkóhun, jẹ́ kí n mọ̀,” béèrè ohun tó o lè bá a ṣe. Sọ fún un pé o lè bá a dáná, o lè bá a tún ilé ṣe, o lè bá a fọṣọ, o lè bá a lọṣọ, o lè jẹ́ iṣẹ́ tó bá fẹ́ rán, o lè bá a lọ sọ́jà àti pé o lè fi ọkọ̀ gbé e lọ sí ilé ìwòsàn láti lọ gba ìtọ́jú, wàá sì gbé e bọ̀, ọ̀nà díẹ̀ rèé láti fi hàn pé o bìkítà. Jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, kó o sì máa ṣe nǹkan lákòókò tó yẹ. Má yẹ àdéhùn, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o ṣèlérí pé wàá ṣe.—Mátíù 5:37.
Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Rosanne Kalick sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ ńlá ni ohun yòówù tí a ṣe, bó ti wù kó kéré mọ́ láti jẹ́ kí ara aláìsàn kan yá pa dà.” Sílvia tí àrùn jẹjẹrẹ ṣe nígbà méjì tó sì ti rí ìwòsàn sọ pé: “Bí àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe máa ń wá fi mọ́tò gbé mi lọ sí ìlú mìíràn lójoojúmọ́ fún ìtọ́jú máa ń mú ara tù mí, ó sì ń tù mí nínú! Lójú ọ̀nà, a máa ń sọ̀rọ̀ nípa onírúurú nǹkan, tí mo bá sì ti gba ìtọ́jú tán, gbogbo ìgbà la máa ń yà ní ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n ti ń ta kọfí. Èyí sì máa ń jẹ́ kí ara mi yá gágá.”
Àmọ́, má ṣe rò pé o mọ ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ nílò. Kalick dábàá pé: “Ńṣe ni kó o máa béèrè ìbéèrè.”
Ó tún sọ pé: “Má tìtorí pé o fẹ́ ṣèrànwọ́, kó o wá máa darí gbogbo nǹkan. Ìyẹn lè ba gbogbo nǹkan jẹ́. Tí o kò bá jẹ́ kí n ṣe nǹkan kan, òun tó ò ń sọ ni pé mi ò lè dá nǹkan kan ṣe. Ó yẹ kí n mọ̀ pé mo ṣì lè ṣe nǹkan fúnra mi. Ó yẹ kó dá mi lójú pè àìsàn náà kò tíì sọ mi di aláìwúlò. Tì mí lẹ́yìn kí n lè ṣe ohun tí mo lè ṣe.”Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn fẹ́ láti máa dá nǹkan ṣe fúnra rẹ̀. Adilson, tó ní àrùn éèdì, sọ pé: “Nígbà tí àìsàn bá ṣeni, èèyàn kì í fẹ́ kí wọ́n pa òun tì bíi pé òun kò wúlò mọ́. Ó máa ń wu èèyàn pé kó ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíì, ì báà tiẹ̀ máà tó nǹkan. Ó dára gan-an láti mọ̀ pé o ṣì lè ṣe nǹkan kan! Ó máa fún ẹ níṣìírí láti máa bá ìgbésí ayé rẹ nìṣó. Mo fẹ́ káwọn èèyàn fi mí sílẹ̀ láti ṣe ìpinnu tó wù mí, kí wọ́n má sì yọ mí lẹ́nu lórí rẹ̀. Pé ara ẹnì kan kò yá kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi bàbá tàbí ìyá mọ́ tàbí pé kò lè bójú tó àwọn ojúṣe rẹ̀ mọ́.”
Má jìnnà sí ẹni náà
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:
“Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—ÒWE 17:17.
◼ Tí o kò bá lè lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ bóyá torí pé ọ̀nà jìn tàbí nítorí nǹkan míì, o lè fi fóònù pè é, o lè kọ lẹ́tà sí i tàbí kó o fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ránṣẹ́ sí i. Kí lo lè kọ sínú lẹ́tà rẹ? Alan D. Wolfelt, tó máa ń gba àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nímọ̀ràn dábàá pé: “Kọ nípa àwọn nǹkan tó gbádùn mọ́ni tẹ́ ẹ ti jọ ṣe. Ṣèlérí fún un pé wàá tún kọ̀wé sí i láìpẹ́, kó o sì rí i pé o ṣe bẹ́ẹ̀.”
Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù pé o lè sọ ohun tí kò yẹ tàbí ṣàṣìṣe mú kó o yẹra láti máa fún ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn ní ìṣírí. Lọ́pọ̀ ìgbà, wíwà tó o wà níbẹ̀ gan-an ló ṣe pàtàkì jù. Nínú ìwé kan tí Lori Hope kọ, ó sọ pé: “Gbogbo wa la máa ń sọ̀rọ̀, tí a sì máa ń ṣe nǹkan táwọn èèyàn lè ṣì lóye tàbí èyí tó lè dùn wọ́n. Ìyẹn kì í ṣe ìṣòro. Àmọ́ ìṣòro ni téèyàn bá ń bẹ̀rù pé òun kò fẹ́ ṣàṣìṣe, téèyàn sì torí ìyẹn pa ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ tì.”
Ó lè jẹ́ àkókò yìí gan-an ni ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn nílò rẹ jù lọ. Jẹ́ kó dá a lójú pé “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́” lo jẹ́. Òótọ́ ni pé ìsapá tó ò ń ṣe láti ràn án lọ́wọ́ lè ṣàì mú ìrora rẹ̀ kúrò, àmọ́ o lè mú kí ipò tó nira náà túbọ̀ rọrùn sí i.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.