Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run?
Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run?
Kò sí àní-àní pé àpọ́nlé ńlá ló jẹ́ tó o bá láǹfààní láti fi orúkọ tí ẹni pàtàkì kan ń jẹ́ pè é nígbà tó nawọ́ sí ẹ pé kí o kí òun. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé orúkọ oyè bí “Ààrẹ,” “Kábíyèsí,” tàbí “Olóyè” la máa fi ń ṣáájú orúkọ àwọn ẹni pàtàkì. Torí náà, bí ẹnì kan tó wà ní ipò ọlá bá dìídì sọ fún ọ pé kó o máa fi orúkọ tóun ń jẹ́ gan-an pe òun tó o bá fẹ́ bá òun sọ̀rọ̀, wàá mọyì àǹfààní yìí gan-an.
ỌLỌ́RUN tòótọ́ sọ fún wa nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tún ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, irú bí “Ẹlẹ́dàá,” “Olódùmarè” àti “Olúwa Ọba Aláṣẹ,” síbẹ̀, ó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láǹfààní láti máa fi orúkọ tó ń jẹ́ gan-an pè é.
Bí àpẹẹrẹ, lákòókò kan tí wòlíì Mósè ń bẹ Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Dákun, Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 4:10) Nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, Sólómọ́nì Ọba bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ pé: “Ìwọ Jèhófà.” (1 Àwọn Ọba 8:22, 23) Nígbà tí wòlíì Aísáyà ń gbàdúrà nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Ìwọ, Jèhófà, ni Baba wa.” (Aísáyà 63:16) Kò sí iyè méjì pé, Bàbá wa ọ̀run ń fẹ́ ká máa fi orúkọ òun pe òun.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti máa pe orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, ìyẹn Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló rọ̀ mọ́ mímọ orúkọ yẹn. Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.” (Sáàmù 91:14) Ó ṣe kedere pé àwọn nǹkan kan wà tó rọ̀ mọ́ mímọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ rí ààbò Ọlọ́run. Kí ló wá yẹ kó o ṣe kó o tó lè mọ ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà?