4 Kí La Lè Gbàdúrà Nípa Rẹ̀?
4 Kí La Lè Gbàdúrà Nípa Rẹ̀?
ÀDÚRÀ Olúwa ni àdúrà tí wọ́n sọ pé àwọn Kristẹni máa ń gbà jù. Bóyá òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí tàbí irọ́, ohun kan tó dájú ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn kò lóye àdúrà àwòkọ́ṣe náà tí Jésù kọ́ni, èyí tá a tún máa ń pè ní Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti sọ àdúrà yìí di àkọ́sórí tí wọ́n sì máa ń kà á lákàtúnkà lójoojúmọ́ láì tiẹ̀ ronú lórí ìtúmọ̀ rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ohun tí Jésù ní lọ́kàn nípa rẹ̀ nìyẹn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
Ṣáájú kí Jésù tó gba àdúrà náà, ó ní: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mátíù 6:7) Ṣé kì í ṣe pé Jésù ń ta ko ara rẹ̀ nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ téèyàn lè há sórí kéèyàn sì máa sọ lásọtúnsọ? Rárá! Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá a lè gbàdúrà nípa rẹ̀ àtàwọn ohun pàtàkì-pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà ni Jésù kọ́ni. Jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ohun tó sọ yẹ̀ wò. Àdúrà náà wà nínú ìwé Mátíù 6:9-13.
“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”
Jésù fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé, Bàbá, ìyẹn Jèhófà la gbọ́dọ̀ darí gbogbo àdúrà sí. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ ìdí tí orúkọ Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an àti ìdí tó fi yẹ ní yíyà sí mímọ́ tàbí sísọ di mímọ́?
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n ti fi irọ́ ba orúkọ mímọ́ Ọlọ́run jẹ́. Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run sọ pé, Jèhófà jẹ́ òpùrọ́ àti Alákòóso onímọtara-ẹni-nìkan, pé kò sì ní ẹ̀tọ́ láti darí àwọn ohun tó dá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ọ̀pọ̀ ló fara mọ́ èrò Sátánì, wọ́n sì ń kọ́ni pé, Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́, pé ìkà ni àti pé kò lẹ́mìí ìdáríjì, wọ́n tiẹ̀ sọ pé òun kọ́ ni Ẹlẹ́dàá. Àwọn kan ní tiwọn gbéjà ko orúkọ rẹ̀, wọ́n yọ orúkọ náà Jèhófà kúrò nínú ìtumọ̀ àwọn Bíbélì, wọ́n sì sọ pé kò yẹ láti máa lò ó.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ẹ̀gàn yìí kúrò. (Ìsíkíẹ́lì 39:7) Nípa báyìí, ó máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò, á sì mú ìṣòro wa kúrò. Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ tó kàn nínú àdúrà Jésù dáhùn ìbéèrè yẹn.
“Kí ìjọba rẹ dé.”
Lóde òní, èdèkòyédè tí kì í ṣe kékeré ló wà láàárín àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Àmọ́ àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé, ó ti pẹ́ táwọn wòlíì Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà náà, ìyẹn Olùgbàlà tí Ọlọ́run yàn máa ṣàkóso Ìjọba kan tó máa ṣàtúnṣe Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yìí máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nípa títú àṣírí irọ́ Sátánì, á fòpin sí ìṣàkóso Sátánì àti iṣẹ́ rẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ogun, àìsàn, ìyàn, kódà ikú kò ní sí mọ́. (Sáàmù 46:9; 72:12-16; Aísáyà 25:8; 33:24) Tó o bá ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ńṣe lò ń gbàdúrà pé kí gbogbo ìlérí yẹn ṣẹ.
ayé. (“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣẹ láyé bí wọ́n ṣe ṣẹ ní ọ̀run níbi tí Ọlọ́run ń gbé. Kò sí ẹni tó lè dá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dúró ní ọ̀run, níbẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run bá Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ jagun, ó fi wọ́n sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:9-12) Bíi tí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ méjì tó ṣáájú nínú àdúrà àwòkọ́ṣe, ìkẹta yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ kì í ṣe ìfẹ́ tara wa. Gbogbo ìgbà ni ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń mú ohun tó dára jù lọ wá fún gbogbo ìṣẹ̀dá. Àní Jésù tó jẹ́ ẹni pípé pàápàá sọ fún Bàbá rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”—Lúùkù 22:42.
“Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.”
Jésù tún fi hàn pé a lè gbàdúrà nípa ohun tá a nílò. Kò sí ohun tó burú tá a bá béèrè fún ohun tá a nílò lóòjọ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Kódà, ìyẹn ń rán wa létí pé Jèhófà ló ń “fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:25) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé òbí onífẹ̀ẹ́ ni, ó sì ṣe tán láti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ohun tí wọ́n nílò. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí òbí rere, kò ní fún wọn ní nǹkan èyíkéyìí tó lè ṣe ìpalára fún wọn.
“Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.”
Ǹjẹ́ òótọ́ ni pé a jẹ Ọlọ́run ní gbèsè? Ǹjẹ́ a nílò pé kó dárí jì wá? Ọ̀pọ̀ lónìí ni kò mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, wọn ò sì kà á sí nǹkan kan. Àmọ́ Bíbélì kọ́ wa pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fa gbogbo ìdààmú tó ń bá wa lónìí, òun ló ń fa ikú ẹ̀dá èèyàn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, á máa ń dẹ́ṣẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, ìdáríjì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan ló sì lè mú ká ní ìyè ayérayé. (Róòmù 3:23; 5:12; 6:23) Ó fọkàn ẹni balẹ̀ láti mọ̀ pé Bíbélì sọ pé: ‘Jèhófà ṣe tán láti dárí jini.’—Sáàmù 86:5.
“Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”
Ǹjẹ́ o kò rí i pé o nílò ààbò Ọlọ́run lójú méjèèjì! Ọ̀pọ̀ ni kò gbà pé Sátánì tó jẹ́ “ẹni burúkú náà” wà. Àmọ́ Jésù kọ́ni pé Sátánì wà, ó tiẹ̀ pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 16:11) Sátánì ti ba èrò àwọn èèyàn tó wà nínú ayé tó ń ṣàkóso lé lórí jẹ́, ó sì ń sapá láti ba èrò ìwọ náà jẹ́, kò fẹ́ kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, Bàbá rẹ. (1 Pétérù 5:8) Àmọ́, Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ fíìfíì, ó sì ṣe tán láti dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.
Kò túmọ̀ sí pé àwọn kókó tó wà nínú àdúrà àwòkọ́ṣe Jésù tá a ṣe àkópọ̀ rẹ̀ yìí nìkan lèèyàn lè gbàdúrà nípa rẹ̀. Rántí pé, 1 Jòhánù 5:14 sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” Nítorí náà, má ṣe rò pé ohun tó ń dà ẹ́ láàmú ti kéré jù láti sọ fún Ọlọ́run.—1 Pétérù 5:7.
Àmọ́, ọ̀rọ̀ nípa àkókò àti ibi tá a ti máa gbàdúrà ńkọ́? Ǹjẹ́ ó pọn dandan pé ká ní àkókò kan àti ibì kan pàtó tá a ti máa gbàdúrà?