Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Lo Lè Fi Dá Ẹ̀sìn Tòótọ́ Mọ̀?

Kí Lo Lè Fi Dá Ẹ̀sìn Tòótọ́ Mọ̀?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Lo Lè Fi Dá Ẹ̀sìn Tòótọ́ Mọ̀?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Ṣé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà?

Ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ó wà, ìyẹn ẹ̀sìn tòótọ́. Ńṣe ló dà bí ọ̀nà tí èèyàn lè tọ̀ lọ sí ìyè. Nígbà tí Jésù ń sọ nípa ọ̀nà náà, ó ní: “Díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:14) Ìjọsìn tó bá òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu nìkan ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ìgbàgbọ́ kan náà làwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ ní.—Ka Jòhánù 4:23, 24; 14:6; Éfésù 4:4, 5.

2. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi pe ara wọn ní Kristẹni?

Àwọn wòlíì èké ti sọ ẹ̀sìn Kristẹni dìdàkudà, wọ́n sì ti fi ẹ̀sìn yìí bojú kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ ara wọn. Bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ, wọ́n máa ń sọ pé àwọn jẹ́ “àgùntàn” Jésù, àmọ́ ìwà wọn kò yàtọ̀ sí ti ìkookò tí ebi ń pa. (Mátíù 7:13-15, 21, 23) Ẹ̀yìn ìgbà tí gbogbo àwọn àpọ́sítélì Jésù ti kú làwọn Kristẹni èké wá pọ̀ jù lọ.—Ka Ìṣe 20:29, 30.

3. Àwọn nǹkan wo ló mú kí ẹ̀sìn tòótọ́ yàtọ̀?

Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, wọ́n kà á sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ń sapá láti máa fi àwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò ní ìgbésí ayé wọn. Nítorí náà, ẹ̀sìn tòótọ́ yàtọ̀ gan-an sáwọn ẹ̀sìn tí wọ́n fi èrò èèyàn gbé kalẹ̀. (Mátíù 15:7-9) Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ kì í wàásù ohun kan kí wọ́n wá máa ṣe ohun míì.—Ka Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17.

Ẹ̀sìn tòótọ́ ń bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Jésù sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Ó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run, ó sì kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Mátíù 6:9) Níbi tí ò ń gbé, àwọn wo ló ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa lo orúkọ Ọlọ́run?—Ka Jòhánù 17:26; Róòmù 10:13, 14.

4. Kí lo lè fi dá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ mọ̀?

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ọlọ́run rán Jésù pé kó wàásù nípa Ìjọba náà. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé. Jésù sì wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run títí ó fi kú. (Lúùkù 4:43; 8:1; 23:42, 43) Ó ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bí àwọn kan bá ní àwọn fẹ́ wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún ẹ, ẹlẹ́sìn wo nírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́?—Ka Mátíù 10:7; 24:14.

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kì í ṣe apá kan ayé búburú yìí. Wọn kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú, wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìjà. (Jòhánù 17:16) Bákan náà, wọn kì í hu ìwà burúkú tó kúnnú ayé.—Ka Jákọ́bù 1:27; 4:4.

5. Kí ni olórí àmì tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀?

Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní ìfẹ́ ara wọn dénú. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé èèyàn ní láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn tó wá látinú gbogbo ẹ̀yà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsìn èké sábà máa ń ṣàtìlẹ́yìn fún ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń jà, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ kì í ṣe bẹ́ẹ̀. (Míkà 4:1-4) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ máa ń lo àkókò àti ohun ìní wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, wọ́n sì ń fún àwọn èèyàn níṣìírí.—Ka Jòhánù 13:34, 35; 1  Jòhánù 4:20, 21.

Ẹ̀sìn wo ló ń kọ́ni ní ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó ń bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, tó sì ń wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú ìṣòro aráyé? Àwọn ẹlẹ́sìn wo ni wọ́n ní ìfẹ́ ara wọn tí wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ogun? Gbogbo àwọn nǹkan tá a sọ yìí tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—1 Jòhánù 3:10-12.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 15 ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

“Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.”—Títù 1:16