Ṣé Ó Yẹ Kí Wọ́n Máa Ṣe Ìrìbọmi Fún Àwọn Ọmọ Ọwọ́?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ṣé Ó Yẹ Kí Wọ́n Máa Ṣe Ìrìbọmi Fún Àwọn Ọmọ Ọwọ́?
▪ Obìnrin kan tó ń jẹ́ Victoria sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí pé inú Limbo ni àbúrò mi John ń lọ.” Kí nìdí tí obìnrin yìí fi ń bẹ̀rù? Ó ṣàlàyé pé, “John kò tíì ṣe ìrìbọmi kó tó kú, àlùfáà ìjọ Kátólíìkì kan sì sọ pé fún ìdí yìí, inú Limbo ni John máa wà títí láé.” Kò sí iyè méjì pé irú ẹ̀kọ́ yìí ń dáyà jáni, àmọ́ ṣé ó bá Ìwé Mímọ́ mu? Ǹjẹ́ Bíbélì sọ pé inú Limbo ni àwọn ọmọ tí wọn kò ṣe ìrìbọmi fún ṣáájú kí wọ́n tó kú máa lọ?
Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni ṣe ìrìbọmi. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ . . . máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Ẹ kíyè sí i pé, lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wọ́n máa tó ṣe ìrìbọmi fún un. Ìyẹn ni pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù kó sì ti pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé òun máa tẹ̀ lé Jésù, ó dájú pé àwọn ọmọ ọwọ́ kò lè ṣe irú ìpinnu yìí.
Pẹ̀lú ìyẹn náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń rin kinkin pé àṣẹ tí Jésù pa yẹn kan àwọn ọmọ kéékèèké. Ọ̀gbẹ́ni Richard P. Bucher tó jẹ́ pásítọ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Luther sọ pé, “Gbogbo èèyàn pátá títí kan àwọn ọmọ ọwọ́ ló yẹ kó ṣe ìrìbọmi.” Ó tún sọ pé: “Téèyàn kò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, wọn kò ní rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ wọ iná ọ̀run àpáàdì.” Àmọ́ ṣá o, irú àwọn èrò yìí ta ko ẹ̀kọ́ Jésù, ó kéré tán ní ọ̀nà mẹ́ta.
Ọ̀nà àkọ́kọ́, Jésù kò sọ pé ó yẹ kí wọ́n ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́. Kí nìdí tá a fi mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ẹ kíyè sí i pé, léraléra ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àwọn ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́. Àwọn ìgbà míì tiẹ̀ wà tó tún kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó ti kọ́ wọn tẹ́lẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, ó fẹ́ rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lóye kókó náà. (Mátíù 24:42; 25:13; Máàkù 9:34-37; 10:35-45) Síbẹ̀, kò sí ìgbà kankan tó mẹ́nu kàn án pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́. Ṣé a lè sọ pé Jésù gbàgbé láti mẹ́nu kan kókó yìí ni? Kò lè rí bẹ́ẹ̀! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tó bá jẹ́ pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́ ni, Jésù á ti sọ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀nà kejì, Jésù kò fìgbà kan rí kọ́ àwọn èèyàn pé ẹnì kan máa lọ jìyà lẹ́yìn tó bá ti kú. Jésù gba ohun tó ṣe kedere tí Ìwé Mímọ́ sọ gbọ́, tó ní: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Jésù mọ̀ pé àwọn òkú kì í lọ sí pọ́gátórì, Limbo, inú iná ọ̀run àpáàdì tàbí ibì kan láti lọ jìyà níbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó kọ́ni ni pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń sùn.—Jòhánù 11:1-14.
Ọ̀nà kẹta, Jésù kọ́ni pé “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” yóò jíǹde. (Jòhánù 5:28, 29) Kò sí àní-àní pé, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí kò ṣe ìrìbọmi kí wọ́n tó kú máa wà lára wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jíǹde, wọ́n á ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n á sì ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. *—Sáàmù 37:29.
Ó ṣe kedere pé, Bíbélì kò sọ pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Láti mọ púpọ̀ sí i nípa Párádísè ilẹ̀ ayé àti nípa ìrètí àjíǹde, ka orí 3 àti 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.