Sún Mọ́ Ọlọ́run
‘Kí Ni Ohun Tí Jèhófà Ń Béèrè Láti Ọ̀dọ̀ Rẹ?’
KÍ NI Jèhófà retí pé kí àwọn tó bá fẹ́ sin òun lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà ṣe? Ǹjẹ́ ó sọ pé dandan ni ká máa ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà pípé, débi pé àwa ẹ̀dá aláìpé kò ní lè ṣe ohun tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn láéláé? Àbí kìkì ohun tí agbára wa ká ló ń retí pé ká ṣe? Tí a bá fẹ́ máa láyọ̀ bí a ti ń sin Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé kí a mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Ẹ jẹ́ ká wo bí wòlíì Míkà ṣe ṣàkópọ̀ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe.—Ka Míkà 6:8.
“Ó ti sọ fún ọ . . . ohun tí ó dára.” Kò sídìí fún wa láti ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣiyè méjì, láìmọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe gan-an. Gbogbo ohun tó fẹ́ ká ṣe ló ti sọ kedere fún wa nínú Bíbélì. Ohun “tí ó dára” ni Ọlọ́run sì ní ká ṣe. Kò lè sọ pé ká ṣe ohun tó burú láéláé. “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” torí náà ohun tó dáa ló ní lọ́kàn fún wa. (1 Jòhánù 4:8; 5:3) Tí a bá ń ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, kì í ṣe pé a máa mú inú Ọlọ́run dùn nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ fún àǹfààní wa.—Diutarónómì 10:12, 13.
“Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ?” Ṣé Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ká ṣe nǹkan kan fún òun? Bẹ́ẹ̀ ni! A gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run torí pé òun ni orísun ẹ̀mí wa, òun ló sì ń dá ẹ̀mí wa sí. (Sáàmù 36:9) Kí ni ohun tó ń fẹ́ ká máa ṣe? Gbólóhùn mẹ́ta ni Míkà fi ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe. Gbólóhùn méjì àkọ́kọ́ dá lórí bó ṣe yẹ kí a máa ṣe sí àwọn èèyàn bíi tiwa, ìkẹta sì dá lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
“Ṣe ìdájọ́ òdodo.” Ìwé kan tí a ṣe ìwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a tú sí “ìdájọ́ òdodo” níbí yìí “wé mọ́ kéèyàn máa ṣe ohun tí ó tọ́ àti èyí tó yẹ sí àwọn tí wọ́n jọ wà láwùjọ.” Ọlọ́run fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn ohun tí òun sọ pé ó tọ́ àti èyí tó yẹ ni ká máa fi hùwà sí àwọn ẹlòmíì. Bí a ṣe lè ṣe ìdájọ́ òdodo ni pé ká jẹ́ adúróṣinṣin, olóòótọ́ àti ẹni tí kì í ṣe ojúṣàájú nínú bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn lò. (Léfítíkù 19:15; Aísáyà 1:17; Hébérù 13:18) Tí a bá ń ṣe ohun tó tọ́ sí àwọn èèyàn, ó lè jẹ́ kó yá àwọn náà lára láti máa ṣe bákan náà sí wa.—Mátíù 7:12.
“Nífẹ̀ẹ́ inú rere.” Ọlọ́run kò kàn sọ pé ká máa ṣe inú rere sí àwọn èèyàn, ohun tó sọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ inú rere. Ọ̀rọ̀ Hébérù (cheʹsedh) tí a tú sí “inú rere” níhìn-ín tún lè túmọ̀ sí “inú rere onífẹ̀ẹ́” tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.” Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ bí ìfẹ́, àánú àti inú rere kò gbé gbogbo ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà [cheʹsedh] yọ; kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó gbé ìtúmọ̀ rẹ̀ tán, àpapọ̀ gbogbo wọn ló jẹ́.” Tí a bá nífẹ̀ẹ́ inú rere, tọkàntọkàn ni a ó fi máa ṣe é, inú wa yóò sì máa dùn láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa ní ayọ̀ tó wà nínú fífúnni.—Ìṣe 20:35.
“Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.” Nínú Bíbélì, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “rìn” lọ́nà tó lè túmọ̀ sí “bíbá a lọ láti máa ṣe ohun kan pàtó.” Bí a ṣe lè bá Ọlọ́run rìn ni pé, ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ohun tó sọ nínú Bíbélì mu. A ní láti jẹ́ ẹni tó “mẹ̀tọ́mọ̀wà,” ìyẹn ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, tí a bá fẹ́ máa bá Ọlọ́run rìn. Kí nìdí? Tí a bá jẹ́ ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ bí a ṣe ń bá Ọlọ́run rìn, a ó máa fi tinútinú yẹ ara wa wò láti mọ ipò tí a wà níwájú rẹ̀, a ó sì mọ̀ pé ó níbi tí agbára wa mọ. Nítorí náà, ohun tó túmọ̀ sí láti fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà bá Ọlọ́run rìn ni pé kéèyàn máa ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe àti ohun tí agbára wa ká láti ṣe.
Ó ṣe tán, Jèhófà kì í retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. Tó bá ti jẹ́ pé gbogbo ohun tí agbára wa gbé la ṣe, ó máa ń tẹ́ ẹ lọ́rùn. (Kólósè 3:23) Ó mọ ibi tí agbára wa mọ. (Sáàmù 103:14) Tí àwa náà bá fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ó ní ibi tí agbára wa mọ lóòótọ́, a ó máa láyọ̀ bí a ti ń bá Ọlọ́run rìn. Nítorí náà, ó máa dáa kí o kọ́ bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ọlọ́run rìn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ wàá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.—Òwe 10:22.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún November: