Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Bi Ọlọ́run Ní Ìbéèrè?
ÀWỌN kan sọ pé kò tọ́ kéèyàn máa bi Ọlọ́run ní ìbéèrè. Wọ́n máa ń rò pé ìwà àrífín ni téèyàn bá ń béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tàbí ìdí tí kò fi jẹ́ kí àwọn nǹkan míì ṣẹlẹ̀. Ṣé èrò tìrẹ náà nìyẹn?
Tó o bá ní irú èrò bẹ́ẹ̀, ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn rere ló ti bi Ọlọ́run ní ìbéèrè nípa ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan. Wo díẹ̀ nínú irú àwọn ìbéèrè tí wọ́n bi í:
Ọkùnrin olódodo kan tó ń jẹ́ Jóòbù béèrè pé: “Èé ṣe tí àwọn ẹni burúkú fi ń wà láàyè nìṣó, tí wọ́n darúgbó, tí wọ́n sì di ẹni tí ó pọ̀ ní ọlà pẹ̀lú?”—Jóòbù 21:7.
Hábákúkù tó jẹ́ wòlíì olóòótọ́ sọ pé: “Èé ṣe tí o fi ń wo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè, tí o fi dákẹ́ nígbà tí ẹni burúkú gbé ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo jù ú mì?”—Hábákúkù 1:13.
Jésù Kristi náà sọ pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?”—Mátíù 27:46.
Tó o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú àti àwọn tó tẹ̀ lé àwọn ẹsẹ tá a fà yọ sókè yìí, wàá rí i pé ìbéèrè tí àwọn wọ̀nyẹn béèrè tọkàntọkàn kò bí Jèhófà * Ọlọ́run nínú. Ṣùgbọ́n o, kò yani lẹ́nu bí Ọlọ́run kò ṣe bínú sí wọn. Torí kì í kà á sí ìwọ̀sí tí a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún wa kí ara wa lè le dáadáa. Inú Ọlọ́run máa ń dùn láti pèsè àwọn nǹkan wọ̀nyẹn fún wa. (Mátíù 6:11, 33) Bákan náà, tinútinú ni Ọlọ́run fi sọ àwọn ohun tó máa jẹ́ ká ní èrò tó dáa kí ọkàn wa sì balẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Kódà Jésù tiẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” (Mátíù 7:7) Àlàyé tí Jésù ń ṣe bọ̀ kó tó mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé kì í ṣe nǹkan tara nìkan ló ń ṣèlérí pé a máa rí gbà, ó tún kan rírí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì tá a bá béèrè.
Ká ní o láǹfààní láti béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, èwo nínú àwọn ìbéèrè yìí lo máa fẹ́ béèrè?
Ìwọ Ọlọ́run, kí nìdí tó o fi dá mi sáyé?
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà tí mo bá kú?
Kí nìdí tó o fi jẹ́ kí ìyà máa jẹ mí?
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” wàá rí ìdáhùn Ọlọ́run sí ìbéèrè rẹ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Jẹ́ ká wo ìdí tí àwọn kan fi béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ àti bí Bíbélì ṣe dáhùn wọn.
^ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.