Àjíǹde Jésù Máa Jẹ́ Ká Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun!
ÀJÍǸDE Jésù kì í ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan lásán tó ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́ àmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe wá láǹfààní kankan lónìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú. Nítorí níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan, àjíǹde òkú pẹ̀lú wá nípasẹ̀ ènìyàn kan. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 15:20-22.
Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Nísàn ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jésù jíǹde, ìyẹn ní ọjọ́ tí àwọn Júù sábà máa ń mú àkọ́so ọkà báálì wọn wá síwájú Jèhófà Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe Jésù ní àkọ́so, ṣe ló ń fi hàn pé àwọn míì ṣì wà tí Ọlọ́run máa jí dìde.
Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e ṣàlàyé ohun tí àjíǹde Jésù mú kó ṣeé ṣe. Ó ní: “Níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan, àjíǹde òkú pẹ̀lú wá nípasẹ̀ ènìyàn kan.” Ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tí a jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù ló sọ gbogbo wa di ẹni kíkú. Ṣùgbọ́n bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ tó jẹ́ pípé rà wá pa dà, ṣe ló mú kí àwọn tó bá kú lè ní àjíǹde kí wọ́n sì bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Lákòótán, Pọ́ọ̀lù wá sọ nínú Róòmù 6:23 pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”
Jésù tiẹ̀ sọ àǹfààní tí ikú rẹ̀ àti àjíǹde rẹ̀ máa ṣe fún wa. Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “A óò gbé Ọmọ ènìyàn sókè, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbà gbọ́ nínú rẹ̀ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:14-16.
Ìwọ rò ó wò ná, kéèyàn wà láàyè títí láé láìsí ìrora, ìyà àti ọ̀fọ̀ kankan! (Ìṣípayá 21:3, 4) Nǹkan ayọ̀ gbáà ló máa jẹ́ o! Ọ̀mọ̀wé kan ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí pé: “Bí sàréè ṣe máa ń rán èèyàn létí pé bíńtín layé, bẹ́ẹ̀ náà ni àjíǹde ṣe sọ ikú di ohun tó kàn wà fúngbà kúkúrú.” Dájúdájú, ṣe ni àjíǹde Jésù máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun!