Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: BÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ ṢE LÈ LÁDÙN

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Wa Lè Ládùn Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Wa Lè Ládùn Lóòótọ́?

“Adọrin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wa; bi o si ṣe pe nipa ti agbara, bi wọn bá to ọgọrin ọdún, agbara wọn làálàá pẹlu ibanujẹ ni.”—Sáàmù 90:10, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

ÒKODORO òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí! Ìgbé ayé àwa èèyàn lónìí kún fún ‘làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́.’ Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ṣe kàyéfì rí pé, ‘Ǹjẹ́ ìgbésí ayé èèyàn tiẹ̀ lè ládùn?’

Wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Maria. Nígbà kan, koko ni ara rẹ̀ le, tó sì máa ń lọ sókè sódò fúnra rẹ̀, àmọ́ ní báyìí tó ti di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84], kò lè lọ sókè sódò bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, kò tiẹ̀ lè dá jáde nílé mọ́. Òótọ́ ni pé ọpọlọ rẹ̀ ṣì jí pépé, àmọ́ ó jọ pé ara rẹ̀ ti ń daṣẹ́ sílẹ̀. Ǹjẹ́ ẹni tó wà nínú irú ipò yìí lè gbà pé ìgbésí ayé òun ládùn?

Ìwọ ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kó o ti ṣe kàyéfì rí nípa bóyá ìgbé ayé rẹ ládùn. Iṣẹ́ tó ò ń ṣe lè gba pé kí o máa ṣe ohun kan náà léraléra, ó lè jẹ́ iṣẹ́ àṣekúdórógbó, ó sì lè máa tán ẹ lókun. Àwọn èèyàn tiẹ̀ lè má mọyì gbogbo bó o ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́. Kódà ká tiẹ̀ sọ pé o ń rí ṣe nídìí iṣẹ́ ọ̀hún, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ torí o kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la. Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó ń rí tìẹ rò tàbí kó o ní ìdààmú ọkàn. Gbọ́nmi-si-omi-ò-to àti ìjà lè máa ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ lọ́pọ̀ ìgbà. Ó sì lè jẹ́ pé ẹnì kan tó o fẹ́ràn ló kú. Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ André, òun àti bàbá rẹ̀ mọwọ́ ara wọn dáadáa, àmọ́ ṣàdédé ni bàbá rẹ̀ ṣàìsàn tó sì gbabẹ̀ kú. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gbo André gan-an, ó sì ń wò ó pé bóyá ni òun lè láyọ̀ mọ́.

Bí ó ti wù kí wàhálà tí a ń kojú le tó, ìbéèrè pàtàkì kan wà tí a gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sí, ìyẹn ni pé: Ǹjẹ́ ìgbésí ayé wa lè ládùn lóòótọ́? A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tí a bá ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé ọkùnrin kan tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn. Jésù Kristi ni ọkùnrin náà. Láìkà gbogbo àtakò tí wọ́n ṣe sí Jésù sí, ìgbésí ayé rẹ̀ ládùn. Ìgbésí ayé tiwa náà lè ládùn tí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.