Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá fẹ́ pa wọ́n?
Ìwé Ìhìn Rére ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ pa Jésù àti àwọn ọ̀daràn méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lórí òpó igi oró. Bíbélì sọ pé: “Àwọn Júù béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kí ó jẹ́ kí a ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn, kí a sì gbé àwọn òkú náà lọ.”— Jòhánù 19:31.
Òfin àwọn Júù ni pé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé òkú ọ̀daràn kọ́ sórí òpó igi, wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘kí òkú rẹ̀ wà lórí òpó igi ní gbogbo òru.’ (Diutarónómì 21:22, 23) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òfin yìí náà ni àwọn Júù ń tẹ̀lé tó bá di ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀daràn táwọn ará Róòmù bá gbé kọ́ sórí òpó igi oró. Ìyẹn ni pé, ikú àwọn ọ̀daràn náà á tètè yá kánkán tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn, á sì jẹ́ kí wọ́n lè sin òkú wọn kó tó di ọjọ́ Sábáàtì, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.
Tí wọ́n bá fẹ́ pa ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún lọ́nà yìí, ńṣe ni wọ́n máa ń gbá ìṣó mọ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀. Tí wọ́n bá wá gbé igi náà nàró, gbogbo ara rẹ̀ á wá rọ̀ sórí àwọn ìṣó náà, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í joró ikú lọ́nà tó lékenkà. Tó bá fẹ́ mí, ó gbọ́dọ̀ máa fi ẹsẹ̀ ti ara rẹ̀ sókè lára ìṣó tó wà níbi ẹsẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá ṣẹ́ egungun ẹsẹ̀ rẹ̀, kò ní ṣeé ṣe fún un láti mí. Èyí á sì mú kí ikú rẹ yá kíákíá.
Báwo ni wọ́n ṣe máa ń fi kànnàkànnà jagun láyé àtijọ́?
Kànnàkànnà ni ohun ìjà tí Dáfídì fi pa Gòláyátì òmìrán náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé látìgbà tí Dáfídì ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn ní kékeré ló ti mọ bí wọ́n ṣe ń lo kànnàkànnà.—1 Sámúẹ́lì 17:40-50.
Wọ́n ṣàwárí àwọn àwòrán kan tó fi hàn pé àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ará Asíríà máa ń lo kànnàkànnà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Kànnàkànnà máa ń ní awọ kan tó yi tàbí aṣọ kan tí wọ́n fi okùn dè ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Tí wọ́n bá fẹ́ ta á, ẹni tó ń lo kànnàkànnà náà á fi òkúta kan sáàárín awọ yẹn. Wọ́n sábà máa ń lo akọ òkúta tára ẹ̀ jọ̀lọ̀ tàbí tó rí róbótó tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó ọsàn òroǹbó. Á bẹ̀rẹ̀ sí í fi kànnàkànnà náà lókè, lójijì, á yọwọ́ kúrò lára ọ̀kan nínú okùn tó di kànnàkànnà náà mú, á sì fi agbára ta òkúta tó wà nínú rẹ̀ jáde, tààràtà ni òkúta náà á lọ sí ọ̀gangan ibi tí wọ́n bá ta á sí.
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn òkúta kànnàkànnà tí wọ́n fi jagun ní ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti wú jáde nínú ilẹ̀ tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Àwọn akọni tó mọṣẹ́ ogun dáadáa lè fi kànnàkànnà pẹ̀lú agbára débi pé òkúta inú rẹ̀ máa ń ta dé ọgọ́rùn-ún sí àádọ́jọ [160 sí 240] ibùsọ̀ láàárín wákàtí kan. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan kò gbà pé òkúta kànnàkànnà lè rìn jìnnà tó ọfà, síbẹ̀ ọṣẹ́ tí kànnàkànnà máa ń ṣe burú jáì.—Àwọn Onídàájọ́ 20:16.