Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ìgbésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run Mérè Wá

Ìgbésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run Mérè Wá

Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni àwọn èèyàn ti máa ń ṣe ẹ̀tanú sí mi nítorí ẹ̀yà tí mo ti wá. Mo tún jẹ́ ẹni tí kì í fẹ́ ṣàṣìṣe, mo sì máa ń tijú gan-an. Mo ronú pé Bíbélì máa tù mí nínú, ni mo bá gbọ̀nà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó wà ní àgbègbè wa lọ kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Nígbà tí mo rí i pé ohun tó wà nínú Bíbélì ò yé àwọn fúnra wọn débi tí wọ́n á lè ṣàlàyé fún ẹlòmíì, mo yáa gbájú mọ́ eré ìdárayá kí n lè máa tu ara mi nínú.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe eré ìfarapitú àti eré ìmárale tó ń mú kí igẹ̀ yọ, kí iṣan ara sì ki. Nígbà tó yá, mo ṣí ṣọ́ọ̀bù kan sí San Leandro, nílùú California, lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Àwọn tó bá fẹ́ kí igẹ̀ wọn yọ, kí iṣan ara wọn sì ki máa ń wá síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn eléré ìmárale yìí ni mo bá ṣiṣẹ́, ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ gba oyè ẹni tí iṣan ara rẹ̀ ki jù lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Síbẹ̀ gbogbo èyí kò fún mi ní ìtùnú tí mò ń fẹ́.

MO RÍ OHUN TÍ MÒ Ń WÁ

Ọ̀rẹ́ mi kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀bù rí i pé ó wù mí gan-an láti lóye Bíbélì, nítorí náà, ó sọ pé òun máa fi mí mọ ẹnì kan. Nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ kejì, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sí ilé mi, wákàtí mẹ́rin gbáko ló fi dáhùn ìbéèrè mi láti inú Bíbélì, mo sì sọ fún un pé kó pa dà wá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Nígbà tó dé, a jọ jíròrò nípa Bíbélì títí di òru. Ohun tí mo kọ́ dùn mọ́ mi gan-an débi pé mo bi í bóyá mo lè tẹ̀ lé e lọ jẹ́rìí ní ọjọ́ kejì kí èmi náà lè mọ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni. Ńṣe ló ń yà mí lẹ́nu bó ṣe ń fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè tí wọ́n bá bi í. Mo wá pinnu pé, èmi náà fẹ́ mọ bí mo ṣe lè máa fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè àwọn èèyàn.

Mo fi iṣẹ́ tí mò ń ṣe sílẹ̀, mo sì ń tẹ̀ lé aṣáájú-ọ̀nà yìí lọ wàásù. Aṣáájú-ọ̀nà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pe àwọn òjíṣẹ́ tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù. Nígbà tó di oṣù May ọdún 1948, mo ṣèrìbọmi ní àpéjọ kan tá a ṣe ní Cow Palace Arena ní ìlú San Francisco, ní ìpínlẹ̀ California. Ọdún yẹn kan náà ni mo di aṣáájú-ọ̀nà.

Àkókò yẹn náà ni mo sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé kí wọ́n lọ wàásù fún ìyá mi. Ìyá mi nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó kọ́, òun náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìyá mi fi dúró ṣinṣin ti Jèhófà láìka bí àwọn mọ̀lẹ́bí ṣe ṣàtakò sí i tó. Ó sì jẹ́ olóòótọ́ títí tó fi kú. Yàtọ̀ sí ìyá mi, kò sí ẹlòmíì nínú ìdílé wa tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

MO PÀDÉ OLÓLÙFẸ́ MI

Ní ọdún 1950, mo kó lọ sí ìlú Grand Junction, ní ìpínlẹ̀ Colorado, ibẹ̀ ni mo ti pàdé Billie. Ọdún 1928 ni wọ́n bí i, ìyẹn àkókò tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní gbogbo ayé. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Minnie, alaalẹ́ ló máa ń fi iná àtùpà ka Bíbélì fún Billie. Nígbà tí Billie máa fi pé ọmọ ọdún mẹ́rin, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé, ó sì mọ ọ̀pọ̀ ìtàn inú Bíbélì lórí. Ní nǹkan bí ọdún 1946 sí 1949, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé fún ìyá Billie láti inú Bíbélì pé ọ̀run àpáàdì kì í ṣe ibi ìdálóró, bí kò ṣe sàréè gbogbo aráyé. (Oníwàásù 9:5, 10) Èyí ló mú kí ìyà Bíllie àti bàbá rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nígbà tí Billie ṣe tán ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tó wà ní ìlú Boston lọ́dún 1949, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì. Dípò kó máa wá iṣẹ́ olùkọ́ kiri, ó pinnu láti fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Ọlọ́run. Billie ṣèrìbọmi ní ìpàdé àgbáyé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Yankee Stadium ní  ìlú New York lọ́dún 1950. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn la pàdé, a sì ṣègbéyàwó. A wá jọ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àkókò púpọ̀ wàásù káàkiri.

Ìlú Eugene, ní ìpínlẹ̀ Oregon, ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí i wàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn la pàdé tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ wa títí dòní. Ní ọdún 1953, a kó lọ sí àgbègbè Grants Pass ní Oregon ká lè ran ìjọ kékeré tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́. Ọdún yẹn náà ni wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹtàlélógún Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò níbi tá a ti ń dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́. Ìlú South Lansing ní New York ló wà, ó sì jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin kìlómítà sí apá àríwá ìwọ̀ oòrùn ìlú New York City.

MO ṢIṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ BRAZIL

Ní oṣù December ọdún 1954, ìyẹn oṣù márùn-ún lẹ́yìn tí a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, èmi àti ìyàwó mi wọ ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan lọ sí orílẹ̀-èdè Brazil. Lẹ́yìn tá a ti lo nǹkan bíi wákàtí kan nínú ọkọ̀ òfuurufú náà, ọ̀kan nínú àwọn ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà bà jẹ́. Àmọ́, a dúpẹ́ pé a sọ̀ láyọ̀ sí ìpínlẹ̀ Bermuda. Ọkọ̀ òfuurufú náà tún yọnu, a sì tún fi balẹ̀ ní pàjáwìrì sí orílẹ̀-èdè Cuba. Síbẹ̀, a dé ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rio de Janeiro lórílẹ̀-èdè Brazil. Gbogbo ohun tá a fi rin ìrìn-àjò yẹn jẹ́ wákàtí mẹ́rìndínlógójì. A dúpẹ́ pé a dé ọ̀hún láyọ̀.

Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àkọ́kọ́ tá a rẹ́ǹtì ní Bauru lọ́dún 1955 rèé, èmi ni mo kọ ọ̀rọ̀ tó wà lára pátákó yẹn sí i

Lẹ́yìn tá a ti ṣe díẹ̀ níbẹ̀, èmi, ìyàwó mi àtàwọn míṣọ́nnárì méjì míì kó lọ sí àgbègbè Bauru, ní São Paulo, gbogbo wa sì jọ ń gbé inú ilé kan náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ló ń gbé ní àgbègbè náà, àwa ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ wá sí ìlú yẹn.

A bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún àwọn èèyàn ní ilé wọn, àmọ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó wà ní àdúgbò yẹn tako iṣẹ́ wa. Ńṣe ló máa ń tẹ̀ lé wa kiri, tó sì máa ń sọ fún àwọn tá a fẹ́ wàásù fún pé wọn ò gbọ́dọ̀ fetí sí wa. Àmọ́, ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan tá a débẹ̀, odindi ìdílé kan tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìrìbọmi. Àwọn míì náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìdílé tó ṣèrìbọmi yẹn ní ìbátan kan tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ kan tó gbajúmọ̀ níbẹ̀. Ẹgbẹ́ náà ní gbọ̀ngàn kan, mo sì ṣètò láti rẹ́ǹtì gbọ̀ngàn yìí fún àpéjọ wa. Ni àlùfáà yẹn bá sọ pé láéláé wọn ò gbọ́dọ̀ fi gbọ̀ngàn náà rẹ́ǹtì fún wa. Ni olórí ẹgbẹ́ yìí bá pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà jọ, ó wá sọ fún wọn pé: “Tí ẹ ò bá fi gbọ̀ngàn náà rẹ́ǹtì fún wọn, màá fi ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀!” Bó ṣe di pé wọ́n rẹ́ǹtì gbọ̀ngàn náà fún wa nìyẹn.

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn lọ́dún 1956, wọ́n pè wá sí àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe ní Santos, São Paulo. Àwọn tó wọ ọkọ̀ ojú irin láti ìjọ wa lọ sí àpèjọ àgbègbè yẹn tó ogójì. Nígbà tá a dé láti àpéjọ yẹn, mo rí lẹ́tà kan gbà, wọ́n sọ nínú lẹ́tà yẹn pé ká lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, ìyẹn àwọn òjíṣẹ́ tó máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ káàkiri. Iṣẹ́ arìnrìn-àjò yìí la ṣe fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ní orílẹ̀-èdè Brazil. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ibi tá ò dé ní orílẹ̀-èdè yẹn.

Ní ọdún kan ṣoṣo péré, a ti ní àwùjọ àwọn akéde tó nítara ní ìlú Bauru

ÌRÍRÍ TÁ A NÍ

Láyé ìgbà yẹn, kì í rọrùn láti rin ìrìn-àjò. Bọ́ọ̀sì, kẹ̀kẹ́, ọkọ̀ ojú irin, kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹsẹ̀ la fi rin gbogbo ìlú yẹn. Lára ìlú tá a kọ́kọ́ lọ ni Jaú, ní ìpínlẹ̀ São Paulo. Àlùfáà tó wà níbẹ̀ takò wá. Ó sọ pé:

“Ẹ ò lè wàásù fún ‘àwọn àgùntàn mi!’”

La bá dá a lóhùn pé: “Wọn kì í ṣe tìẹ, Ọlọ́run ló ni wọ́n.”

A ṣètò láti fi fíìmù kan tó dá lórí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé han àwọn aráàlú yẹn. Àkòrí fíìmù náà ni The New World Society in Action. Ni àlùfáà yẹn bá rán àwọn jàǹdùkú pé kí wọ́n wá gbéjà kò wá. Lójú ẹsẹ̀ la lọ sọ fún àwọn ọlọ́pàá. Nígbà tí àlùfáà yẹn àti àwọn jàǹdùkú tó pè ní ọmọ ìjọ rẹ̀ dé ibi tí a ti ń fi fíìmù náà han àwọn èèyàn, ṣe ni wọ́n bá àwọn ọlọ́pàá rẹpẹtẹ tí  wọ́n dúró wámúwámú pẹ̀lú ìbọn wọn lọ́wọ́. Èyí mú kí gbogbo àwùjọ náà gbádùn fíìmù náà dáadáa.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ibi tá a ti ṣiṣẹ́ ìsìn ni wọ́n ti kórìíra wa tí wọ́n sì tako ìsìn wa. Bí àpẹẹrẹ, ní Brusque tó wà nítòsí ìlú Blumenau ní ìpínlẹ̀ Santa Catarina, a bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì kan pàdé táwọn aráàlú ibẹ̀ ń ṣàtakò sí gan-an. Àmọ́ Jèhófà bù kún ìfaradà tí wọ́n ní. Torí pé lẹ́yìn ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún, ìjọ tó wà níbẹ̀ báyìí ti lé ní ọgọ́ta, ìyẹn nìkan kọ́, Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan tó rẹwà tún wà ní ìlú Itajaí tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ìlú Blumenau!

Lára àwọn ìrírí tá a gbádùn nígbà tá à ń sìn gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò ni bá a ṣe ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa láti múra àwọn àpéjọ ńlá sílẹ̀. Ní ọdún 1970, mo láǹfààní láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àpéjọ ní pápá ìṣeré ńlá Morumbi. Wọ́n fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ bí ọgọ́rùn-ún tó wà nítòsí ibẹ̀ pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan yọ̀ǹda ẹni mẹ́wàá kí wọ́n lè tún pápá ìṣeré náà ṣe ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú àpéjọ náà.

Bí àwọn agbábọ́ọ̀lù yẹn ṣe ń fi pápá ìṣeré náà sílẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ńṣe ni wọ́n ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ẹ máa wo àwọn obìnrin yìí pẹ̀lú ìgbálẹ̀ àti ìnulẹ̀ wọn.” Àmọ́ nígbà tó fi máa di aago méjìlá òru, pápá ìṣeré yẹn ti mọ́ nigínnigín! Ọ̀gá tó ń bójú tó pápá ìṣeré náà sọ pé: “Ká sọ pé àwọn tó ń bá mi ṣiṣẹ́ ló fẹ́ ṣe é ni, ó máa gbà wọ́n tó ọ̀sẹ̀ kan gbáko láti ṣe àtúnṣe tí ẹ̀yin fi wákàtí mélòó kan ṣe yìí.”

A PA DÀ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ní ọdún 1980 bàbá mi kú, a wá pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ tọ́jú màmá mi ní Fremont tó wà ní ìpínlẹ̀ California. A máa ń ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó ní onírúurú ilé, ká lè ráyè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa nìṣó. A sì láǹfààní láti ran àwọn tó ń sọ èdè Potogí lágbègbè yẹn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà tó yá, a kó lọ sí ìtòsí San Joaquin Valley, ká lè wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè Potogí níbẹ̀. Àgbègbè ọ̀hún fẹ̀ láti ìlú Sacramento lọ sí ìlú Bakersfield. Ní báyìí, ìjọ tó ń sọ èdè Potogí ní California ti tó mẹ́wàá.

Lẹ́yìn tí ìyá mi kú ní ọdún 1995, a kó lọ sí ìlú Florida ká lè lọ tọ́jú bàbá ìyàwó mi. A wà pẹ̀lú wọn títí tí wọ́n fi kú. Ìyà ìyàwó mi ti kú láti ọdún 1975. Nígbà tó wá di ọdún 2000 a kó lọ sí aṣálẹ̀ tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Colorado, à ń wàásù fún àwọn Amẹríńdíà tó wà ní àdádó Navajo àti àdádó Ute ní àgbègbè yẹn. Àmọ́ ó dùn mí gan-an pé Billie kú ní February 2014.

Mo láyọ̀ pé ní ọdún márùndínláàádọ́rin [65] sẹ́yìn, mo rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó lo Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè mi! Inú mi tún dùn pé mo ṣàyẹ̀wò ohun tó sọ, mo sì rí i pé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni lóòótọ́. Èyí ti mú kí ìgbésí ayé mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run mérè wá.