KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ÒPIN TI SÚN MỌ́LÉ
Ki Ni “Opin” Tumo si?
Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ pé “Òpin ti sún mọ́lé?” Ṣé kì í ṣe oníwàásù kan tó ń sọ̀rọ̀ fatafata látorí àga ìwàásù pẹ̀lú Bíbélì rẹ̀ lọ́wọ́, tó sì ń fara ṣàpèjúwe ló máa wá sí ẹ lọ́kàn? Àbí bàbá àgbàlagbà onírùngbọ̀n yẹ́bútú kan tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, tó wọṣọ gbàgẹ̀rẹ̀ tó wá gbé àmì kan tó kọ ọ̀rọ̀ nípa òpin ayé sí tàbí tí àmùrè wà ní ìgbáròkó rẹ̀, tó wá ń kéde pé: “Ẹ yí pa dà, ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀!” Ká sòótọ́, irú èyí lè dáyà já àwọn kan tàbí kó mú àwọn míì máa ṣiyèméjì tàbí kó tiẹ̀ dẹ́rìn-ín pa wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Bíbélì sọ pé: “Òpin yóò sì dè.” (Mátíù 24:14) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan náà là ń pè ní “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run” àti “Amágẹ́dọ́nì.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Lóòótọ́, ẹ̀kọ́ ìsìn ti mú kí ọ̀rọ̀ náà ta kora, torí kò yé àwọn fúnra wọn, wọ́n sì ń gbin ọ̀pọ̀ èrò tó ń bani lẹ́rù sọ́kàn àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé Bíbélì ò fi wá sínú òkùnkùn, ó tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí ká lè mọ ohun tó jóòótọ́ nípa òpin. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ bóyá òpin ti sún mọ́lé. Paríparí rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè làájá! Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo èrò òdì tí àwọ́n èèyàn ní nípa òpin àti ohun tó túmọ̀ sí. Kí tiẹ̀ ni Bíbélì pè ní “òpin”?
ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́ NÍPA ÒPIN
-
ÒPIN KÌ Í ṢE PÉ ỌLỌ́RUN FẸ́ FI INÁ PA AYÉ RUN.
Bíbélì sọ pé: “Ó [Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí àtàwọn míì ti jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ò ní pa ayé rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kò ní fàyè gba àwọn èèyàn pé kí wọ́n pa á run.—Oníwàásù 1:4; Aísáyà 45:18.
-
ÒPIN KÒ NÍ ṢÀDÉDÉ WÁYÉ.
Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run ti dá ọjọ́ tí òpin máa dé, ó sì ti ṣètò àkókò tí yóò jẹ́. Ó ní: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba. Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” (Máàkù 13:32, 33) Torí náà, Ọlọ́run, ìyẹn “Baba” ti dá ọjọ́ tàbí ṣètò “àkókò tí ó yàn kalẹ̀” tí òpin máa dé.
-
. ÒPIN KÌ Í ṢE LÁTỌWỌ́ ÈÈYÀN TÀBÍ NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÒKÚTA INÁ TÓ Ń JÁBỌ́ LÁTỌ̀RUN.
Kí ló máa mú òpin wá? Ìṣípayá 19:11 sọ pé: “Mo sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó! ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a ń pè ní Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́.” Ẹsẹ 19 wá sọ pé: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà náà àti àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn tí wọ́n kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.” (Ìṣípayá 19:11-21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ èdè ìṣàpẹẹrẹ, ohun tí ó fẹ́ ká lóye ni pé: Ọlọ́run máa rán agbo ọmọ ogun àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run.
ÈRÒ TÓ TỌ́ NÍPA ÒPIN
-
ÒPIN MÁA DÉ BÁ ÌJỌBA ÈÈYÀN.
Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tá à ń jíròrò kókó kẹta, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa pa “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” wọn run torí wọ́n “kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.”—Ìṣípayá 19:19.
wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” ( -
OGUN, ÌWÀ IPÁ ÀTI ÌRẸ́JẸ MÁA DÓPIN.
“[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) “Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” (Òwe 2:21, 22) “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.
-
ÒPIN Á DÉ BÁ ÌSÌN TÍ KÒ ṢÈFẸ́ ỌLỌ́RUN TÓ SÌ Ń MÚ ÀWỌN ÈÈYÀN ṢÌNÀ.
‘Àwọn wòlíì pàápàá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní ti gidi; àti ní ti àwọn àlùfáà, wọ́n ń tẹni lórí ba ní ìbámu pẹ̀lú agbára wọn . . . kí sì ni ẹ ó ṣe ní òpin rẹ̀?’ (Jeremáyà 5:31) “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: ‘Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin!’”—Mátíù 7:21-23.
-
ÒPIN MÁA DÉ BÁ ÀWỌN TÓ Ń DA AYÉ RÚ.
Jésù Kristi sọ pé: “Wàyí o, èyí ni ìpìlẹ̀ fún ìdájọ́, pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, nítorí pé àwọn iṣẹ́ wọn burú.” (Jòhánù 3:19) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìparun tó wáyé nígbà kan tó sì kárí ayé, ìyẹn jẹ́ nígbà ayé ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Nóà. “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:5-7.
Kíyè sí pé Bíbélì fi “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun” wé ìparun “ayé” ìgbà Nóà. Ayé wo ló pa run nígbà yẹn? Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ló “jìyà ìparun,” ìyẹn “àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Kì í ṣe ilẹ̀ ayé yìí ló pa run. Bákan náà, bí “ọjọ́ ìdájọ́” bá dé, àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run máa pa run. Àmọ́ Ọlọ́run máa dá àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ nídè bíi ti ọjọ́ Nóà.—Mátíù 24:37-42.
Wo bí ilẹ̀ ayé yìí ṣe máa rí nígbà tí gbogbo àwọn ẹni ibi bá pa run! Ẹ ò rí i pé ìròyìn ayọ̀ lohun tí Bíbélì sọ nípa òpin kì í ṣe ìròyìn búburú. Síbẹ̀, o lè máa ronú pé: ‘Ǹjẹ́ Bíbélì sọ ìgbà tí òpin máa dé? Báwo ló ṣe sún mọ́lé tó? Báwo ni mo ṣe lè làájá?’