ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2017 | Bó O Ṣe Lè Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Látinú Kíka Bíbélì
Kí Lèrò Rẹ?
Ṣé Bíbélì ṣì wúlò láyé ọ̀làjú tá a wà yìí? Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ, ó ní: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.”
Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì àti àwọn ohun tá a lè ṣe láti jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?
Báwo lọ̀pọ̀ èèyàn ti ṣe jàǹfààní látinú kíka Bíbélì?
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ibo Ni Mo Ti Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀?
Àwọn àbá márùn-ún tó máa jẹ́ kó o gbádùn kíka Bíbélì lọ́nà tó rọrùn.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Máa Gbádùn Ẹ̀?
Títúmọ̀ èdè, ẹ̀rọ ìgbàlódé, ohun èlò téèyàn lè fi kẹ́kọ̀ọ́ àti oríṣiríṣi ọ̀nà ló ti wà táá jẹ́ kí kíka Bíbélì túbọ̀ gbádùn mọ́ni.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Tún Ayé Mi Ṣe?
Ìwé tó ti pẹ́ gan-an yìí láwọn ìmọ̀ran tó wúlò fún wa.
BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Mi Ò Fẹ́ Kú O!
Yvonne Quarrie máa ń bi ara rẹ̀ pé, “Kí nìdí tí mo fi wà láyé?” Ìdáhùn ìbéèrè yìí ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN
“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”
Tó o bá ní bùkátà ìdílé tàbí tó o dojú kọ ìṣòro kan tó gba pé kó o ṣe ohun tó o mọ̀ pé ó tọ́, wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Énọ́kù.
Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Ṣi Bíbélì Lóye
Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe pàtàkì gan-an, ó sì yẹ kéèyàn lóye rẹ̀. Kí lo lè ṣe láti lóye Bíbélì?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Kì í ṣe ohun tó fa ìjìyà nìkan ni Bíbélì sọ, ó tún sọ bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí i.
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Ṣé Bíbélì Ta Kora?
Ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ta kora nínú Bíbélì àtàwọn ìlànà tó o lè tẹ̀lé tá á jẹ́ kó o lóye ohun tí wọ́n túmọ̀ sí dáadáa.