KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Tún Ayé Mi Ṣe?
Bíbélì kì í ṣe ìwé kan lásán. Àwọn ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa ló wà nínú rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé rẹ. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Ó lágbára láti tún ìgbé ayé wa ṣe láwọn ọ̀nà méjì yìí: Ó ń tọ́ wa sọ́nà nínú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́ báyìí, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀.
Bí ayé rẹ ṣe lè dára báyìí. Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé rẹ. Ó fúnni láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò lórí àwọn nǹkan yìí.
- Àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.
-
Bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti ìlera wa.
—Sáàmù 37:8; Òwe 17:22. -
Ìwà rere.
—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10. -
Ọ̀rọ̀ ìnáwó.
—Òwe 10:4; 28:19; Éfésù 4:28. *
Tọkọtaya kan nílẹ̀ Éṣíà mọyì àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì gan-an. Nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, kò tètè rọrùn fún wọn láti mọwọ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Àmọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì sílò. Kí ló wá yọrí sí? Vicent tó jẹ́ ọkọ sọ pé: “Ohun tí mo kà nínú Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti máa fi ìfẹ́ bá ìyàwó mi lò, èyí sì mú ká borí àwọn ìṣòro wa. Bá a ṣe ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò ti jẹ́ ká túbọ̀ ṣera wa lọ́kan, a sì ń láyọ̀.” Ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Annalou, fara mọ́ ohun tí ọkọ rẹ̀ sọ, ó ní: “Bá a ṣe ń ka àwọn àpẹẹrẹ látinú Bíbélì ti ràn wá lọ́wọ́. Ní báyìí, mò ń láyọ̀ mo sì ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ọkọ mi, a sì ń sapá láti lé àwọn àfojúsùn wa bá.”
Wàá mọ Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí ohun tí Vicent sọ nípa ìgbéyàwó rẹ̀, ó tún sọ pé: “Bí mo ṣe ń ka Bíbélì ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Àkíyèsí Vicent dá lórí ohun pàtàkì kan, ìyẹn ni pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá jàǹfààní nínú àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀, wàá sì tún di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Èyí máa jẹ́ kó o rí i pé Ọlọ́run ti sọ àwọn nǹkan rere tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún wa, nígbà tí wàá gbádùn “ìyè tòótọ́” títí láé fáàbàdà. (1 Tímótì 6:19) Kò sí ìwé míì tó lè sọ irú ìlérí bẹ́ẹ̀ fún wa.
Tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, tí o kò sì dáwọ́ dúró, ìwọ́ náà á nírú àǹfààní yìí, ìyẹn ni pé ìgbésí ayé rẹ á dára báyìí, wàá sì tún sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, bó o ṣe ń ka Bíbélì, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ìbéèrè máa wá sí ẹ lọ́kàn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ìtàn òṣìṣẹ́ ọba kan ní Etiópíà tó gbáyé ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀ nípa Bíbélì. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó lóye ohun tó ń kà, ó dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” * Kíá ló gbà kí Fílípì ran òun lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni Fílípì, ó mọ Bíbélì dáadáa, ó sì tún máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ìṣe 8:30, 31, 34) Bíi ti ọkùnrin yẹn, tí ìwọ náà bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì, a rọ̀ ẹ́ pé kó o béèrè látorí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó sún mọ́ ẹ nínú èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí. O tún lè bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ. A rọ̀ ẹ́ pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lónìí, kó o sì jẹ́ kó darí rẹ sí ìgbésí ayé tó dára jù lọ.
Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò lè fọkàn tán ohun tí Bíbélì sọ, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wo fídíò kékeré kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? O lè rí i tó o bá lo àmì ìlujá yìí, tàbí kó o lọ sí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo
^ ìpínrọ̀ 8 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tó wà nínú Bíbélì, lọ sí ìkànnì wa, jw.org/yo. Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ.
^ ìpínrọ̀ 11 O tún lè wo àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Ṣi Bíbélì Lóye?”