Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kó Má Bàa Sí Wàhálà Láàárín Èmi àti Olùkọ́ Mi?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kó Má Bàa Sí Wàhálà Láàárín Èmi àti Olùkọ́ Mi?

ORÍ 20

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kó Má Bàa Sí Wàhálà Láàárín Èmi àti Olùkọ́ Mi?

Kọ orúkọ olùkọ́ rẹ tó o fẹ́ràn jù. ․․․․․

Kí ló jẹ́ kó o fẹ́ràn rẹ̀? ․․․․․

Kọ orúkọ olùkọ́ tí o kò fẹ́ràn rárá. ․․․․․

O LÈ fúnra rẹ yan àwọn tó o máa bá ṣọ̀rẹ́, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìwọ kọ́ lo máa yan ẹni tó máa jẹ́ olùkọ́ rẹ, pàápàá nígbà tó o bá ṣì wà lọ́mọdé. Síbẹ̀, ó lè jẹ́ pé gbogbo olùkọ́ rẹ lo máa ń fẹ́ràn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ David sọ pé: “Kì í sí wàhálà kankan láàárín èmi àtàwọn olùkọ́ mi. Mo máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn, àwọn náà sì máa ń fẹ́ràn mi.”

Ó sì lè jẹ́ pé irú olùkọ́ tí ọmọ ọdún mọ́kànlá kan tó ń jẹ́ Sarah ní ni olùkọ́ tìrẹ. Ó sọ pé: “Olùkọ́ wa yẹn burú gan-an. Ohun tó ń kọ́ wa kì í yé mi. Nígbà míì, ó lè má ṣàlàyé tó nípa ohun tó ń kọ́ wa, nígbà míì, àlàyé ẹ̀ á tún wá pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.” Tó o bá ní irú olùkọ́ bẹ́ẹ̀, ohun tí wàá ṣe kó má bàa sí wàhálà láàárín ìwọ àti olùkọ́ yẹn ni pé kó o kọ́kọ́ mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ. Tó o bá ti wá mọ ìṣòro náà, wàá lè borí rẹ̀. Fi àmì ✔ sínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tó bá jẹ́ ìṣòro rẹ nínú àwọn ohun tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o kọ tìrẹ síbẹ̀.

□ Ohun tí olùkọ́ yẹn ń kọ́ wa kì í yé mi

□ Mo rò pé ó yẹ kí n gbà ju iye máàkì tó fún mi

□ Ó jọ pé olùkọ́ yẹn fẹ́ràn àwọn ọmọ yòókù jù mí lọ

□ Nǹkan tí mo ṣe kò tó ìyà tó fi jẹ mí

□ Ó jọ pé olùkọ́ yẹn kàn ṣèkà fún mi ni

□ Nǹkan míì ․․․․․

Kí lo wá lè ṣe sí i? Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù. Ó sọ pé: “Ki gbogbo yin jẹ́ oninu kan, ẹ maa bá ara yin kẹ́dùn.” (1 Pétérù 3:8, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kí ló lè jẹ́ kó o máa bá olùkọ́ tó o rò pé ó burú gan-an kẹ́dùn? Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan kan tó yẹ kó o mọ̀ nípa àwọn olùkọ́, èyí tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Àwọn olùkọ́ náà lè ṣe àṣìṣe. Àwọn olùkọ́ náà ní àwọn ìwà kan tó ti mọ́ wọn lára, wọ́n ní àwọn ìṣòro tiwọn, wọ́n tiẹ̀ tún lè ṣe ojúsàájú pàápàá. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2) Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Brianna sọ pé: “Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní ìṣirò kò ní sùúrù rárá, ṣe ló máa ń jágbe mọ́ wa. Nígbà tó yá, a ò tiẹ̀ bẹ̀rù ẹ̀ mọ́.” Kí ló fà á tí olùkọ́ yẹn fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Brianna sọ pé: “Àwọn ọmọ kíláàsì wa máa ń pariwo gan-an, wọ́n tún máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan kínú lè bí olùkọ́ yẹn.”

Ó dájú pé inú ẹ máa ń dùn tí olùkọ́ kan bá gbójú fo àwọn àṣìṣe rẹ, àtàwọn nǹkan míì tí o kò ṣe dáadáa, pàápàá láwọn ìgbà tó o bá ti ṣe wàhálà púpọ̀ jù. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún olùkọ́ rẹ? Kọ ohun kan tí olùkọ́ rẹ ṣe ní ilé ìwé yín láìpẹ́ yìí síbí, kó o sì kọ ohun tó o rò pé ó fà á tí olùkọ́ yẹn fi ṣe ohun tó ṣe yẹn.

․․․․․

Àwọn olùkọ́ máa ń fẹ́ràn ọmọ kan ju ọmọ míì lọ. Wo àwọn ìṣòro kan tí àwọn olùkọ́ rẹ lè ní: Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ ilé ìwé ló máa ń dìídì fẹ́ wá sí ilé ìwé. Kì í sì í ṣe gbogbo àwọn tó tiẹ̀ fẹ́ wá yẹn gan-an ló máa ń fẹ́ jókòó fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ lórí kókó kan péré. Gbogbo wọn sì kọ́ ló lè fọkàn sí ẹ̀kọ́ yẹn pẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ míì sì máa ń kanra mọ́ àwọn olùkọ́ ní ilé ìwé nítorí ìbínú ohun táwọn ẹlòmíì ṣe sí wọn. Jẹ́ ká wá sọ pé wọ́n ní kó o kọ́ ogún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lẹ́kọ̀ọ́ lórí kókó kan, àmọ́ tó jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ lára wọn ló nífẹ̀ẹ́ sí i. Ṣé o kò ní fẹ́ràn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ yẹn ju àwọn yòókù lọ?

Lóòótọ́, inú lè máa bí ẹ tó bá dà bíi pé olùkọ́ yín ń ṣe ojúsàájú, tó fẹ́ràn àwọn ọmọ kan ju àwọn míì lọ. Ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Natasha sọ nípa ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni pé: “Tó bá ti sọ ìgbà tí gbogbo wa gbọ́dọ̀ parí iṣẹ́ tó fún wa, ó máa ń gbà kí àwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù mú tiwọn wá lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn nìkan ló sì máa ń gbà láyè kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí tó sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé òun ni igbákejì olùkọ́ tó ń kọ́ wọn ní eré bọ́ọ̀lù.” Tí olùkọ́ yín bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ kó o bi ara rẹ ni pé, ‘Ṣé ó ṣáà ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ tèmi bó ṣe yẹ?’ Tó bá ti ń kọ́ ẹ bó ṣe yẹ, ǹjẹ́ o rò pé ó wá yẹ kó o bínú tàbí kó o máa jowú ohun tí olùkọ́ yẹn ń ṣe sí àwọn ọmọ míì?

Kọ ohun tó o lè ṣe síbí tí olùkọ́ yín á fi lè rí i kedere pé o nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ yín.

․․․․․

Àwọn olùkọ́ lè ṣi àwọn ọmọ ilé ìwé lóye. Nígbà míì, tí ìwà ìwọ àti olùkọ́ yín kò bá bára mu, tàbí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀yin méjèèjì kò yé ara yín, ìyẹn lè dá wàhálà sílẹ̀ láàárín yín. Bí àpẹẹrẹ tó o bá jẹ́ ọmọ tó máa ń béèrè ìbéèrè gan-an, olùkọ́ míì lè kà ẹ́ sí ọmọ tó ń yájú, tàbí tó o bá kàn fọ̀rọ̀ kan ṣàwàdà, ó lè kà á sí ìwà àrífín tàbí pé o bà jẹ́.

Kí lo lè ṣe tí olùkọ́ rẹ bá ṣì ẹ́ lóye? Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:17, 18) Gbìyànjú láti rí i pé o kò sọ olùkọ́ rẹ di ọ̀tá. Má ṣe máa ta kò ó. Má sì ṣe ohun tó lè jẹ́ kí olùkọ́ rẹ rí ẹ̀sùn kà sí ẹ lọ́rùn. Ṣe ni kó o máa hùwà dáadáa sí i. O lè máa rò ó pé ‘Kí n máa hùwà dáadáa sí i kẹ̀? Báwo ni mo ṣe lè máa hùwà dáadáa sí irú olùkọ́ bẹ́ẹ̀?’ Ohun tó yẹ kó o ṣe nìyẹn. Máa kí olùkọ́ náà bí ọmọ dáadáa ṣe ń ṣe. Tó o bá ń hùwà dáadáa sí i, tí o kì í fajú ro nígbà tó o bá rí i, ìyẹn lè jẹ́ kó máa fi ojú tó dáa wò ẹ́.​—Róòmù 12:20, 21.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára àwọn olùkọ́ ọmọ kan tó ń jẹ́ Ken kò mọ ìwà rẹ̀ dáadáa. Ken sọ pé: “Ojú máa ń tì mí gan-an, mi kì í lè sọ̀rọ̀ táwọn olùkọ́ mi bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi.” Kí ni Ken wá ṣe sí ìṣòro yẹn? Ó sọ pé: “Nígbà tó yá mo wá rí i pé, ṣe làwọn olùkọ́ mi máa ń fẹ́ ràn mí lọ́wọ́. Torí náà mo pinnu láti rí i pé mo túbọ̀ mọ ìwà àwọn olùkọ́ mi ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí mo wá ṣe bẹ́ẹ̀, mo rí i pé mo túbọ̀ ń ṣe dáadáa gan-an nínú ẹ̀kọ́ mi.”

Lóòótọ́, tó o bá ń hùwà tó dáa sí olùkọ́ kan, tó o sì ń sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó lè má torí ìyẹn yí ìwà rẹ̀ pa dà sí ẹ. Àmọ́ ṣe ni kó o ní sùúrù. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ [tàbí olùkọ́] lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.” (Òwe 25:15) Ní sùúrù kó o sì fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ tó o bá rí i pé olùkọ́ kan ṣe ohun tí kò dáa sí ẹ. Ìyẹn lè mú kó yí èrò rẹ̀ nípa rẹ pa dà.​—Òwe 15:1.

Tí olùkọ́ rẹ bá ṣì ẹ́ lóye tàbí tó ṣe ohun tí kò dáa sí ẹ, kí lo sábà máa ń kọ́kọ́ ṣe?

․․․․․

Kí lo rò pé ì bá dáa kó o ṣe?

․․․․․

Bó O Ṣe Lè Yanjú Àwọn Ìṣòro Kan

Tó o bá ti wá mọ ìwà tí olùkọ́ rẹ ń hù tí o kò fẹ́, ó tún yẹ kó o mọ bí wàá ṣe yanjú ìṣòro tó bá wà láàárín ìwọ àti olùkọ́ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, kí lo lè ṣe tó o bá ní irú àwọn ìṣòro tó tẹ̀ lé e yìí?

Ó yẹ kí iye máàkì mi jù báyìí lọ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Katrina sọ pé: “Mo sábà máa ń ṣe dáadáa gan-an nínú gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe nílé ìwé. Àmọ́ lọ́dún kan báyìí, iye máàkì tí olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì fún mi kéré gan-an, ó ní mo fìdí rẹmi. Ó yẹ kí n gba máàkì tó pọ̀ gan-an jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òbí mi wá lọ bá ọ̀gá àgbà ilé ìwé wa sọ̀rọ̀. Àmọ́ ṣe ni olùkọ́ yẹn kàn fi máàkì tí ò tó nǹkan kún un, nítorí náà, inú ṣì ń bí mi gan-an.” Tí irú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, má kàn bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú ẹ̀sùn kan olùkọ́ rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe bíi ti ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nátánì nínú Bíbélì. Ọlọ́run gbé iṣẹ́ kan tó le fún un pé kó lọ tú àṣírí ìwà tí kò dáa kan tí Dáfídì Ọba hù ní ìkọ̀kọ̀. Nátánì kò já wọ ààfin Dáfídì, kó wá máa pariwo lé e lórí, kó máa ka àwọn ẹ̀sùn rẹ̀ fún un, ṣe ló rọra fi ọgbọ́n bá Dáfídì sọ̀rọ̀.​—2 Sámúẹ́lì 12:1-7.

Ìwọ náà lè lọ bá olùkọ́ rẹ, kó o fi sùúrù ṣàlàyé ara rẹ fún un tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Tó o bá fìbínú sọ̀rọ̀ tàbí ò ń fẹ̀sùn kan olùkọ́ rẹ pé kò mọṣẹ́ tàbí ò ń ka àwọn ẹ̀sùn míì sí i lọ́rùn, ọ̀rọ̀ rẹ kò ní tà létí rẹ̀. Ṣe ni kó o lo ọgbọ́n, kó o fara balẹ̀ bá a sọ̀rọ̀. O lè ní kó ṣàlàyé ohun tó o lè ṣe tí wàá fi túbọ̀ máa ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ rẹ̀. Fetí sílẹ̀ dáadáa kó o tó fèsì, torí Sólómọ́nì sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” (Òwe 18:13) Tó o bá ti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti sọ ibi tó o rò pé àṣìṣe ti wáyé. Kódà bí olùkọ́ náà kò bá tiẹ̀ yí máàkì tó fún ẹ pa dà, bó o ṣe fi ọgbọ́n bá a sọ̀rọ̀ yẹn lè jẹ́ kó máa fojú ọmọ dáadáa wò ẹ́.

Ó jọ pé olùkọ́ yẹn kàn ṣèkà fún mi ni. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel. Ó mọ̀wé gan-an, ó sì máa ń ṣe dáadáa nínú gbogbo ìdánwò tó ti ń ṣe ní ilé ìwé. Àmọ́ lọ́dún àkọ́kọ́ tó wọ ilé ẹ̀kọ́ girama, ó dédé rí i pé nǹkan yàtọ̀. Rachel sọ pé: “Kò sí ohun tí olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní kíláàsì yẹn kò ṣe tán kó ṣáà lè rí i pé mi ò ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ tó ń kọ́ wa.” Kí nìdí tí olùkọ́ yẹn fi ṣe bẹ́ẹ̀? Olùkọ́ yẹn jẹ́ kí Rachel àti màmá rẹ̀ mọ̀ pé òun kórìíra ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe.

Rachel ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́, ó ní: “Tá a bá ti ṣèdánwò tó sì jọ pé olùkọ́ yẹn kò fẹ́ fún mi ní máàkì dáadáa láti fi ṣèkà fún mi torí ẹ̀sìn tí mò ń ṣe, mọ́mì mi sábà máa ń lọ bá a láti bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tó wá yá, kò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.” Tí irú nǹkan báyìí bá ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, má bẹ̀rù láti sọ fún àwọn òbí rẹ. Ó dájú pé wọ́n á fẹ́ láti bá olùkọ́ yẹn sọ̀rọ̀, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ fún ọ̀gá àgbà ilé ìwé yín kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí i.

Ronú Nípa Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Rẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú

Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ló máa ń tètè yanjú. Nígbà míì, ṣe ni wàá máa fara dà á. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tanya sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mi máa ń hùwà tí kò dáa sáwọn ọmọ tó bá ń kọ́. Ó sábà máa ń bú wa pé ọ̀dẹ̀ ni wá. Lákọ̀ọ́kọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń dùn mí gan-an, àmọ́ nígbà tó yá, mi kì í jẹ́ kó dùn mí mọ́. Mo gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ mi, mo sì máa ń jára mọ́ṣẹ́ lásìkò tó bá ń kọ́ wa. Torí náà, kì í fi bẹ́ẹ̀ yọ mí lẹ́nu, mo sì wà lára àwọn tó ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ tó kọ́ wa. Lẹ́yìn ọdún méjì, wọ́n lé olùkọ́ yẹn lọ.”

Tó o bá mọ ohun tó o lè máa ṣe sí ọ̀rọ̀ olùkọ́ tó bá ń fún ẹ níṣòro, nǹkan pàtàkì lo ti mọ̀ yẹn, ó sì máa wúlò fún ẹ lọ́jọ́ iwájú tó o bá ní ọ̀gá tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu níbi iṣẹ́. Wàá sì tún lè mọyì àwọn olùkọ́ dáadáa tó o bá ní.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ǹjẹ́ ó máa ń dà bíi pé àkókò tó o ní lójúmọ́ kì í tó ẹ? Kà nípa bí wàá ṣe lè máa lo àkókò rẹ dáadáa táá sì máa tó ẹ.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”​—Mátíù 7:12.

ÌMỌ̀RÀN

Tó o bá rò pé bí olùkọ́ yín ṣe ń kọ́ni máa ń sú ẹ, ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni kó o fọkàn sí, má wo irú ẹni tó jẹ́. Máa kọ kókó ohun tó ń kọ́ yín sílẹ̀, tí ohun kan kò bá yé ẹ, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ní kó ṣàlàyé sí i. Jẹ́ kínú rẹ máa dùn láti kọ́ ẹ̀kọ́ yẹn. Tínú ẹnì kan bá ń dùn, ó lè ran ẹlòmíì náà.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ  . . . ?

Ó lè ti pẹ́ gan-an tí olùkọ́ yín ti ń fi ẹ̀kọ́ kan náà tó ń kọ́ yín yìí kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé. Tórí náà, ó ṣeé ṣe kó má lè fi ìtara kan náà tó fi kọ́ àwọn ti ìṣáájú kọ́ ẹ̀yin mọ́.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí ẹ̀kọ́ kan tá à ń kọ́ bá sú mi, ohun tí màá ṣe kó lè wù mí ni ․․․․․

Tó bá ń ṣe mí bíi pé olùkọ́ mi ń ṣe ohun tí kò dáa sí mi, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o fọkàn sí ẹ̀kọ́ tí olùkọ́ ń kọ́ yín dípò tí wàá fi máa ronú nípa irú ẹni tí olùkọ́ yẹn jẹ́?

● Báwo ni ọwọ́ tó o fi mú ẹ̀kọ́ tí olùkọ́ ń kọ́ yín ṣe máa nípa lórí irú ìwà tí olùkọ́ náà máa hù sí ẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 146]

“Mo rí i dájú pé mò ń hùwà dáadáa sí gbogbo àwọn olùkọ́ mi. Mo mọ orúkọ wọn, tí mo bá sì rí wọn níta, mo máa ń kí wọn dáadáa.”​—Carmen

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 145]

Àwọn olùkọ́ dà bí àwọn òkúta tó o lè gba orí rẹ̀ sọdá láti inú ipò àìmọ̀kan sí ẹni tó jẹ́ olóye èèyàn, àmọ́ ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ fọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ bí ìgbà tó ò ń gbé ẹsẹ̀ lé àwọn òkúta yẹn lọ́kọ̀ọ̀kan láti sọdá