Àwọn Tí Kò Lọ́kọ Tàbí Láya
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀bùn ni kéèyàn wà láìlọ́kọ tàbí láìláya?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fipá mú Kristẹni kan láti lọ́kọ tàbí láya?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ro 14:10-12—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tí kò fi yẹ ká máa dá Kristẹni bíi tiwa lẹ́jọ́
-
1Kọ 9:3-5—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lẹ́tọ̀ọ́ láti gbéyàwó, àmọ́ bí kò ṣe níyàwó jẹ́ kó lè lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà
-
Ṣó yẹ káwọn tí kò tíì gbéyàwó máa rò pé ó dìgbà táwọn bá lọ́kọ tàbí láya káyé àwọn tó nítumọ̀?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ond 11:30-40—Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ò lọ́kọ, àmọ́ ìgbésí ayé ẹ̀ nítumọ̀
-
Iṣe 20:35—Ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ jẹ́ ká rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò láya, ó láyọ̀ torí pé ó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́
-
1Tẹ 1:2-9; 2:12—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò gbéyàwó, àmọ́ ó sọ bí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe fún òun láyọ̀
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya máa yẹra fún ìṣekúṣe bíi ti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó kù?
1Kọ 6:18; Ga 5:19-21; Ef 5:3, 4
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Owe 7:7-23—Ọba Sólómọ́nì sọ̀rọ̀ nípa ohun burúkú tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò kíyè sára, tó lọ kó sọ́wọ́ obìnrin oníṣekúṣe kan
-
Sol 4:12; 8:8-10—Wọ́n gbóríyìn fún ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì torí pé kì í ṣe oníṣekúṣe
-
Kí ló lè mú kí Kristẹni kan pinnu pé òun máa lọ́kọ tàbí láya?
Tún wo 1Tẹ 4:4, 5