Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òdodo

Òdodo

Ta lẹni kan ṣoṣo tó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́?

Di 32:4; Isk 33:17-20

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 18:23-33—Jèhófà jẹ́ kí Ábúráhámù mọ̀ pé Onídàájọ́ òdodo lòun

    • Sm 72:1-4, 12-14—Ọlọ́run mí sí onísáàmù yìí láti yin Mèsáyà Ọba, ẹni tó jẹ́ olódodo bíi ti Ọlọ́run

Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, àǹfààní wo la máa rí?

Sm 37:25, 29; Jem 5:16; 1Pe 3:12

Tún wo Sm 35:24; Ais 26:9; Ro 1:17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 37:22-24—Élíhù yin Jèhófà torí pé ó jẹ́ olódodo, títóbi rẹ̀ sì máa ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un látọkàn wá

    • Sm 89:13-17—Onísáàmù yìí yin Jèhófà torí pé òdodo ló fi ń ṣàkóso

Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn wá òdodo Ọlọ́run?

Isk 18:25-31; Mt 6:33; Ro 12:1, 2; Ef 4:23, 24

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 6:9, 22; 7:1—Nóà ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, ìyẹn sì fi hàn pé ó jẹ́ olódodo

    • Ro 4:1-3, 9—Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, torí náà Jèhófà kà á sí olódodo

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú ká máa hùwà tó dáa, kì í ṣe torí pé a fẹ́ gbayì lójú àwọn èèyàn?

Mt 6:1; 23:27, 28; Lk 16:14, 15; Ro 10:10

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 5:20; 15:7-9—Jésù sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n jẹ́ olódodo, àmọ́ kì í ṣe bíi tàwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí torí pé alágàbàgebè ni wọ́n

    • Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ káwọn tó máa ń ṣe òdodo àṣelékè, tí wọ́n sì máa ń wo àwọn míì bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan rí i pé ó yẹ kí wọ́n ṣàtúnṣe

Kí nìdí tó fi dáa kéèyàn níwà rere ju kó jẹ́ olódodo?

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe òdodo àṣelékè tàbí ká máa ṣe bíi pé òdodo wa ju tàwọn míì lọ?