Ẹ̀KỌ́ 3
Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?
1. Ta ni Òǹṣèwé Bíbélì?
Inú Bíbélì la ti rí ìròyìn ayọ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29) Ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ló para pọ̀ di Bíbélì. Nǹkan bí ogójì (40) olóòótọ́ ọkùnrin ni Ọlọ́run lò láti kọ àwọn ìwé yìí. Mósè ló kọ àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn. Àpọ́sítélì Jòhánù ló kọ ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá (1,900) ọdún sẹ́yìn. Èrò ta ni àwọn tó kọ Bíbélì kọ sílẹ̀? Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ bá àwọn tó kọ Bíbélì sọ̀rọ̀. (2 Sámúẹ́lì 23:2) Èrò Ọlọ́run ni wọ́n kọ sílẹ̀ kì í ṣe tiwọn. Torí náà Jèhófà ni Òǹṣèwé Bíbélì.—Ka 2 Tímótì 3:16; 2 Pétérù 1:20, 21.
Wo Fídíò náà Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?
2. Báwo la ṣe mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?
A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá torí pé ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Kò sí èèyàn tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóṣúà 23:14) Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé tó sì máa rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.—Ka Àìsáyà 42:9; 46:10.
A retí pé kí ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìwé tí kò láfiwé, bí Bíbélì sì ṣe rí nìyẹn. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ Bíbélì ni wọ́n ti tẹ̀ jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Òótọ́ ni pé ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti wà, àmọ́ ó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Bákan náà, nǹkan bí ogójì (40) èèyàn tó kọ ìwé náà ò ta ko ara wọn. * Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní, Bíbélì sì tún lágbára láti yí ìgbésí ayé ẹni pa dà sí rere. Àwọn ẹ̀rí yìí mú kó dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.—Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.
Wo Fídíò náà Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?
3. Kí ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Ìròyìn ayọ̀ nípa ohun rere tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé ló wà nínú Bíbélì. Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé bí àwa èèyàn ṣe pàdánù àǹfààní tá a ní níbẹ̀rẹ̀ láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, ó sì tún sọ bí ayé ṣe máa pa dà di Párádísè.—Ka Ìfihàn 21:4, 5.
Àwọn òfin, ìlànà àti ìmọ̀ràn tún wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ìtàn nípa bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn lò wà nínú Bíbélì, ìtàn yìí sì jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Torí náà, Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 19:7, 11; Jémíìsì 2:23; 4:8.
4. Báwo lo ṣe lè lóye ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?
Ìwé yìí máa jẹ́ kó o lóye ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́nà tí Jésù máa ń gbà mú kí àwọn èèyàn lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù máa ń tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì kan tẹ̀ lé òmíràn, ó sì máa ń ṣàlàyé “ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́.”—Ka Lúùkù 24:27, 45.
Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra bí ìròyìn ayọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn kan wà tí kì í fẹ́ gbọ́ ìròyìn ayọ̀ yìí, ó tiẹ̀ máa ń bí àwọn míì nínú. Má torí ìyẹn sọ pé o ò ní kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ Ọlọ́run tó o bá máa ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Jòhánù 17:3.
^ ìpínrọ̀ 3 Wo ìwé pẹlẹbẹ tá a pè ní, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn.