Àìtó Ẹ̀jẹ̀—Ohun Tó Ń Fà Á, Bó Ṣe Máa Ń Ṣe Àwọn Tó Ní In àti Ìtọ́jú Rẹ̀
Beth rántí ìgbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó ní, “Àìtó ẹ̀jẹ̀ yọ mí lẹ́nu nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. Mi ò kì í lókun, ó máa ń tètè rẹ̀ mí, egungun á máa ro mí, mi ò sì ń lè pọkàn pọ̀. Dókítà mi wá sọ fún mi pé kí n máa lo oríṣi èròjà aṣaralóore kan tí wọ́n ń pè ní iron. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó, mo sì túbọ̀ ń jẹ àwọn oúnjẹ tó máa ṣe ara mi lóore. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í ríyàtọ̀.”
Ìṣòro tí Beth ní yẹn ò ṣàjèjì, ó wọ́pọ̀ gan-an. Àjọ Ìlera Àgbáyé (ìyẹn WHO), sọ pé bílíọ̀nù méjì èèyàn ló ní ìṣòro àìtó ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá gbogbo èèyàn tó wà láyé. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, nǹkan bí ìdajì àwọn obìnrin tó lóyún àti ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn ọmọ kéékèèké tí ò tíì bẹ̀rẹ̀ iléèwé ni àìtó ẹ̀jẹ̀ ń yọ lẹ́nu.
Tí ẹ̀jẹ̀ ò bá tó lára, ó lè yọrí síbi tí ò dáa rárá. Tí àìtó ẹ̀jẹ̀ bá dójú ẹ̀ tán, ó lè yọrí sí ìṣòro ọkàn, kódà ọkàn èèyàn lè daṣẹ́ sílẹ̀. Àjọ WHO sọ pé láwọn ilẹ̀ kan, àìtó ẹ̀jẹ̀ “ló ń fa ikú ìdá márùn-ún àwọn ìyá ọlọ́mọ.” Ohun tó máa ń fa àìtó ẹ̀jẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ni tí èròjà iron ò bá tó lára. Tí obìnrin kan bá nírú ìṣòro yìí, tó sì bímọ, oṣù ọmọ náà lè má pé, ọmọ náà sì lè fúyẹ́ lọ́wọ́. Àwọn ọmọ tí ẹ̀jẹ̀ ò tó lára wọn lè má tètè dàgbà, kòkòrò àrùn sì lè tètè wọ ara wọn. Àmọ́, èèyàn lè dènà àìtó ẹ̀jẹ̀ yìí, tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀jẹ̀ ò tó lára ẹnì kan torí pé kò ní èròjà iron tó pọ̀ tó, ọ̀nà àbáyọ wà. a
Kí Ni Àìtó Ẹ̀jẹ̀?
Ìṣòro àìlera ni àìtó ẹ̀jẹ̀. Ní kúkúrú, tí wọ́n bá sọ pé ẹ̀jẹ̀ ò tó lára ẹnì kan, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa tí onítọ̀hún ní kò tó. Oríṣiríṣi nǹkan ló sì lè fà á. Kódà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) tó ń fa àìtó ẹ̀jẹ̀! Àìsàn náà lè má pẹ́ lára ẹni tó ní in, nígbà míì, ó sì lè jẹ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ le lára àwọn kan, àmọ́ ó máa ń gbo àwọn míì gan-an.
Kí Ló Ń Fa Àìtó Ẹ̀jẹ̀?
Ohun mẹ́ta ló sábà máa ń fà á:
Tí ẹ̀jẹ̀ bá ṣòfò lára ẹnì kan, ó máa ń dín iye sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ kù.
Tí ara fúnra ẹ̀ ò bá ṣe sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa tó pọ̀ tó.
Tí ara bá ń ba àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ jẹ́.
Ọ̀pọ̀ gbà pé àìní èròjà iron tó pọ̀ tó lára ló ń fa ìṣòro àìtó ẹ̀jẹ̀ tó wọ́pọ̀ jù láyé. Tí èròjà iron ò bá pọ̀ tó lára, ara ò ní lè ṣe èròjà hemoglobin tó dáa, tó sì pọ̀ tó. Inú àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ni èròjà hemoglobin yìí wà, òun ló máa ń jẹ́ kí àwọn sẹ́ẹ̀lì náà lè gbé afẹ́fẹ́ ọ́síjìn káàkiri inú ara.
Báwo Ló Ṣe Máa Ń Ṣe Àwọn Tí Ẹ̀jẹ̀ Ò Tó Lára Wọn Torí Àìtó Èròjà Iron?
Tí ẹ̀jẹ̀ bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù lára, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ yọni lẹ́nu, kódà èèyàn lè má mọ̀. Lóòótọ́, bó ṣe máa ń ṣe àwọn tó ní in yàtọ̀ síra, àmọ́ bó ṣe sábà máa ń ṣe ẹni tí ẹ̀jẹ̀ ò tó lára ẹ̀ torí àìtó èròjà iron nìyí:
Á máa rẹ̀ ẹ́ gan-an
Ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ lè tutù
Kò ní lókun nínú
Àwọ̀ ẹ̀ á ṣì
Orí fífọ́ àti òòyì
Àyà á máa dùn ún, ọkàn ẹ̀ á máa lù kì-kì-kì, kò ní lè mí délẹ̀
Èékánná ẹ̀ á máa tètè kán
Oúnjẹ ò ní wù ú jẹ, pàápàá tó bá jẹ́ ọmọ ọwọ́ tàbí ọmọdé
Omi dídì tàbí oúnjẹ afáralókun á máa wù ú jẹ, yẹ̀pẹ̀ pàápàá lè máa wù ú jẹ
Àwọn Wo Ló Máa Ń Sábà Mú?
Àwọn obìnrin lè ní àìtó ẹ̀jẹ̀ torí àìtó èròjà iron. Ìdí ni pé ẹ̀jẹ̀ máa ń ṣòfò lára wọn tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù. Ó lè mú àwọn olóyún náà tí wọn ò bá jẹ oúnjẹ tó ní èròjà folate dáadáa tàbí èròjà folic acid, tó jẹ́ oríṣi èròjà Vitamin B.
Àwọn ọmọ ọwọ́ tí oṣù wọn ò pé lè ní in tàbí àwọn ọmọ ọwọ́ tó fúyẹ́, tí ọmú ìyá wọn tàbí oúnjẹ ọmọ ọwọ́ tí wọ́n ń mu ò ní èròjà iron tó pọ̀ tó.
Àwọn ọmọdé tí kì í jẹ oríṣiríṣi oúnjẹ aṣaralóore lè ní in.
Àwọn tó ń jẹ ewébẹ̀ nìkan lè ní in, tí wọn kì í bá fi bẹ́ẹ̀ jẹ oúnjẹ tó ní ọ̀pọ̀ èròjà iron.
Àwọn tó ní àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́, bí àwọn tó ní àrùn tó jẹ mọ́ ẹ̀jẹ̀, àrùn jẹjẹrẹ, kíndìnrín tó daṣẹ́ sílẹ̀, egbò inú tó ń rọra ṣẹ̀jẹ̀ tàbí àwọn tí oríṣi kòkòrò àrùn kan wà lára wọn.
Ohun Téèyàn Lè Ṣe sí Àìtó Ẹ̀jẹ̀
Kì í ṣe gbogbo àìtó ẹ̀jẹ̀ ló ṣeé dènà, kì í sì í ṣe gbogbo ẹ̀ ló ṣeé wò sàn. Àmọ́ tó bá jẹ́ èyí tí àìtó èròjà iron tàbí vitamin fà, èèyàn lè dènà ẹ̀ tàbí kó wò ó sàn tó bá ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore tó ní àwọn nǹkan yìí:
Èròjà iron. Ó máa ń wà nínú ẹran, ẹ̀wà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì àtàwọn ewébẹ̀ tí ewé wọn dúdú dáadáa. b Tó o bá tún ń lo pọ́ọ̀tì onírin, ó lè ṣèrànwọ́ torí àwọn kan tó ṣèwádìí sọ pé téèyàn bá ń lò ó, ó lè jẹ́ kí èròjà iron pọ̀ sí i nínú oúnjẹ téèyàn fi sè.
Èròjà folate. Ó máa ń wà nínú èso, àwọn ewébẹ̀ tí ewé wọn dúdú dáadáa, ẹ̀wà aláwọ̀ ewé, ẹ̀wà pàkálà, wàrà, ẹyin, ẹja, álímọ́ńdì àti ẹ̀pà. Ó tún máa ń wà nínú àwọn oúnjẹ tó ní èròjà vitamin dáadáa, bíi búrẹ́dì, oúnjẹ tí wọ́n fi ìyẹ̀fun ṣe àti ìrẹsì. Àtọwọ́dá èròjà folate ni wọ́n ń pè ní folic acid.
Èròjà vitamin B-12. Ó máa ń wà nínú ẹran, àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi ọmú màlúù ṣe àtàwọn oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀wà sóyà ṣe.
Èròjà vitamin C. Ó máa ń wà nínú ọsàn àtàwọn èso míì tó rí bí ọsàn, àwọn ohun mímu olómi ọsàn, ata, ewébẹ̀ tí wọ́n ń pè ní broccoli, tòmátò, àwọn bàrà olómi àtàwọn èso strawberry. Àwọn oúnjẹ tó bá ní èròjà vitamin C máa ń jẹ́ kí ara lo èròjà iron dáadáa dípò kó ṣòfò.
Oúnjẹ ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Torí náà, mọ àwọn oúnjẹ tó wà ládùúgbò rẹ tó ní àwọn èròjà tó ṣe pàtàkì. Ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì fáwọn obìnrin, pàápàá tí wọ́n bá wà nínú oyún tàbí tí wọ́n ń gbèrò láti lóyún. Tí ìwọ tó o jẹ́ obìnrin bá ń bójú tó ìlera ẹ, á ṣòro kó tó di pé ẹ̀jẹ̀ ò ní tó lára ọmọ tó o bá bí. c
a Ilé ìwòsàn Mayo Clinic àti inú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Gale Encyclopedia of Nursing and Allied Health la ti rí èyí tó pọ̀ jù nínú àlàyé nípa ohun téèyàn lè máa jẹ àtàwọn ohun míì tó jọ ọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Tó o bá fura pé ẹ̀jẹ̀ ò tó lára ẹ, lọ rí dókítà.
b Má lo èròjà iron tàbí kó o fún ọmọ rẹ láìkọ́kọ́ rí dókítà. Tí èròjà iron bá ti pọ̀ jù, ó lè ba kíndìnrín jẹ́ tàbí kó fa àwọn ìṣòro míì.
c Nígbà míì táwọn dókítà bá fẹ́ tọ́jú àwọn tí ẹ̀jẹ̀ ò tó lára wọn, ṣe ni wọ́n máa ń fa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára.—Ìṣe 15:28, 29.