ÀKÀNṢE ÌWÀÁSÙ
Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àìsàn
“Torí pé àrùn Kòrónà kì í ṣe ọ̀rọ̀ pàjáwìrì mọ́ kárí ayé kò túmọ̀ sí pé àrùn yìí ti kásẹ̀ nílẹ̀.. . . Àfi ká múra sílẹ̀ báyìí torí ó dájú pé àjàkálẹ̀ àrùn míì ṣì máa jà.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Tedros Adhanom Ghebreyesus, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Ìlera Àgbáyé, May 22, 2023.
Ràbọ̀ràbọ̀ àrùn Kòrónà ṣì ń fa ìdààmú ọkàn fún ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì ṣì ń jìyà ẹ̀ títí dòní. Ṣé àwọn ìjọba àtàwọn elétò ìlera lè yanjú ìṣòro àìsàn tó ń bá aráyé fínra lásìkò yìí, ká má tíì sọ pé kí wọ́n múra sílẹ̀ de àjàkálẹ̀ àrùn míì tó máa jà lọ́jọ́ iwájú?
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tó máa jẹ́ ká ní ìlera tó dáa. Ó ní: “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ ìjọba náà, ‘kò ní sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.” ’ (Àìsáyà 33:24) Gbogbo èèyàn ló máa ní ìlera tó dáa, wọ́n sì máa lágbára bí ìgbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́.—Jóòbù 33:25.