Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Dà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa
“Ojú ọjọ́ tí ò dáa mọ́ ti jẹ́ kí ayé nira láti gbé.”—Ìwé ìròyìn The Guardian.
Ìṣòro kan wà táwa èèyàn ti fọwọ́ ara wa fà. Ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ńsì ló gbà pé àwọn ohun táwa èèyàn ń ṣe ló ń fa ojú ọjọ́ tó ń móoru. Bí ojú ọjọ́ ṣe gbóná yìí ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù irú bíi:
Ìgbì oru gbígbóná, ọ̀dá àti ìjì, èyí sì máa ń fa omíyalé àti iná ńlá.
Òkìtì yìnyín tó ń yọ́.
Òkun tó ń kún àkúnya.
Àbájáde ojú ọjọ́ tí ò dáa ti nípa lórí gbogbo ayé. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe rí lórílẹ̀-èdè igba-ó-dín-méje (193), ìwé ìròyìn New York Times sọ pé: “Ayé wa yìí nílò ìrànlọ́wọ́.” Nítorí ìyà àti ikú tí ojú ọjọ́ tí kò dáa ti fà, Àjọ Ìlera Àgbáyé pè é ní ohun tó léwu jù lọ fún ìlera àwa èèyàn.”
Láìka ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí sí, ó dá wa lójú pé ọ̀la ṣì máa dáa. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí, ó sì tún sọ ìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa yanjú àwọn ìṣòro náà àtàwọn ohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.
Ṣé bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà yìí ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ?
Bẹ́ẹ̀ nì. Àwọn àjálù tí ojú ọjọ́ tí ò dáa ti fà wà lára ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé á máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí.
Àsọtẹ́lẹ̀: Ọlọ́run máa “run àwọn tó ń run ayé.”—Ìfihàn 11:18.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á fẹ́rẹ̀ẹ́ ba ayé yìí jẹ́. Ní báyìí, àwọn èèyàn túbọ̀ ń ṣe àwọn ohun tó máa ba ojú ọjọ́ jẹ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ.
Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti jẹ́ ká rí ìdí tá ò fi lè retí pé àwọn èèyàn máa tún ayé yìí ṣe. Kíyè sí pé Ọlọ́run máa dá sí i nígbà tí àwọn èèyàn bá ń “run ayé.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń sapá láti tún ojú ọjọ́ tó ti bà jẹ́ ṣe, àmọ́ àtúnṣe yẹn ti kọjá agbára wọn.
Àsọtẹ́lẹ̀: “Ẹ máa rí àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù.”—Lúùkù 21:11.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn “ohun tó ń bani lẹ́rù” máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí. Ìyípadà tó ń bá ojú ọjọ́ ti fa onírúurú jàǹbá kárí ayé. Lónìí, ọkàn àwọn kan ò balẹ̀ torí wọn ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn.
Àsọtẹ́lẹ̀: “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ . . . aláìṣòótọ́, . . . kìígbọ́-kìígbà, . . . ọ̀dàlẹ̀, alágídí.” 2 Tímótì 3:1-4.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwà táwọn èèyàn á máa hù, àwọn ìwà yìí á mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó máa ba ojú ọjọ́ jẹ́. Ohun tó jẹ ìjọba àtàwọn oníṣòwò lógún ni bí wọ́n ṣe máa rí owó púpọ̀ sí i, láìka ìpalára tó máa ṣe fáwọn èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Tí wọ́n bá ti ẹ̀ fẹ́ pawọ́ pọ̀ láti fòpin sí ìṣòro ojú ọjọ́, wọn kì í fohùn ṣọ̀kan lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe é.
Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé kò yẹ ká máa retí pé àwọn èèyàn máa yí ìwà wọn pa dà kí wọ́n sì tún ayé ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ “á máa burú sí i.”—2 Tímótì 3:13.
Ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa yanjú ìṣòro yìí
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà a Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa bìkítà nípa ayé yìí àtàwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Wo àwọn ẹsẹ Bíbélì mẹ́ta tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa yanjú ìṣòro yìí.
1. Ọlọ́run ò ‘kàn dá ayé yìí lásán, àmọ́ ó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.’—Àìsáyà 45:18.
Ọlọ́run máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún ayé (Àìsáyà 55:11) Kò ní jẹ́ kí wọ́n bà á jẹ́ débi pé kò ní ṣeé gbé mọ́.
2. “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—Sáàmù 37:11, 29.
Ọlọ́run ṣèlérí pé àwa èèyàn máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé, àlàáfíà sì máa wà.
3. “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a ó pa wọ́n run kúrò ní ayé.”—Òwe 2:22.
Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa mú àwọn tí kò jáwọ́ nínú ìwà burúkú kúrò títí kan àwọn tó ń ba ayé jẹ́.
Ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú àwọn ìlérí tó ṣe nípa ayé yìí ṣẹ? Ó máa lo ìjọba kan tó máa kárí ayé tí Bíbélì pè ní Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 6:10) Ọ̀run ni Ìjọba yìí ti máa ṣàkóso. Kò ní pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọba èèyàn rárá láti yanjú ìṣòro ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò àwọn ìjọba èèyàn.—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ kí àwọn ohun rere ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn àti sí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 96:10-13) Wo àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀.
Ó máa sọ ayé dọ̀tun
Ohun tí Bíbélì sọ: “Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.”—Àìsáyà 35:1.
Ohun tí ìlérí yìí túmọ̀ sí: Jèhófà máa tún ilẹ̀ ayé ṣe, kódà ó máa ṣàtúnṣe sí gbogbo ibi táwọn èèyàn ti bà jẹ́ gan-an.
Ó máa tún ojú ọjọ́ tí kò dáa ṣe
Ohun tí Bíbélì sọ: “[Jèhófà] mú kí ìjì náà rọlẹ̀, ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́.”—Sáàmù 107:29
Ohun tí ìlérí yìí túmọ̀ sí: Jèhófà lágbára láti darí ojú ọjọ́. Ojú ọjọ́ tí ò dáa kò ní fa ìpalára fáwa èèyàn mọ́.
Ó máa kọ́ àwọn èèyàn láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n bójú tó ilẹ̀ ayé
Ohun tí Bíbélì sọ: “Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.”—Sáàmù 32:8.
Ohun tí ìlérí yìí túmọ̀ sí: Àwa èèyàn ni Jèhófà ní ká máa bójú tó ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15) Ó máa kọ́ wa bó ṣe yẹ ká bójú tó àwọn nǹkan tó dá àti ohun tá a lè ṣe ká má bàa ba àyíká jẹ́.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”