Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àwọn Ilé Tó Ń Fògo fún Olùkọ́ Wa Atóbilọ́lá

Àwọn Ilé Tó Ń Fògo fún Olùkọ́ Wa Atóbilọ́lá

JULY 1, 2023

 Jèhófà fẹ́ràn láti máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, ó ti lo ètò rẹ̀ láti ṣètò oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́ kó lè fi dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa láti bójú tó onírúurú iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wọn. Ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí ni Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere (SKE). Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, yàtọ̀ sí pé Ètò Ọlọ́run ń mú kí ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sunwọ̀n sí i, wọ́n tún ń kọ́ àwọn ilé tó rẹwà tó dùn ún wò tí wọ́n lè máa lò fún ilé ẹ̀kọ́ náà. Ìdí tọ́rọ̀ sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn tó ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ní àyíká tó tura láti kẹ́kọ̀ọ́. Báwo lowó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ ṣe ń jẹ́ ká lè kọ́ àwọn ilé yìí?

A Ṣètò Àwọn Ilé Tuntun Ká Lè Pe Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Púpọ̀ Sí I

 Ọ̀pọ̀ ọdún ló ti jẹ́ pé àwọn Ilé Ìpàdé àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ la ti máa ń ṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Kí wá nìdí tí Ètò Ọlọ́run fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ilé tàbí tún àwọn ilé kan ṣe kí wọ́n lè máa lò ó fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí? Ẹ Jẹ́ ká gbé àwọn kókó mẹ́ta yìí yẹ̀ wò.

 Iṣẹ́ wa túbọ̀ ń fẹjú sí i. Christopher Mavor tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé; “Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan sọ fún wa pé àwọn máa nílò àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n lè ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2019, ẹ̀ka ọ́fíìsì Brazil sọ pé àwọn máa nílò àwọn ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (7,600) tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere tó máa lè bójú tó àwọn àìní kan láwọn ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ń bójú tó.” Bákan náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì Amẹ́ríkà sọ pé àwọn máa nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó dáńgájíá tó máa lè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè wàásù lọ́nà àkànṣe níbí táwọn èrò pọ̀ sí, ní ibùdó tí ọkọ̀ òkun máa gúnlẹ̀ sí, àti láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, ètò Ọlọ́run tún nílò àwọn ará tó lè sìn ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ àti Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. A sì rí i pé àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere ló máa lè ṣe àwọn iṣẹ́ yìí.

 Àwọn tó fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ ń pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere, àwọn fọ́ọ̀mù náà pọ̀ débi pé ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì ni ò lè pe gbogbo àwọn tó wù láti lọ sílé ẹ̀kọ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere làwọn ará fọwọ́ sí láàárín ọdún kan péré lórílẹ̀-èdè Brazil. Àmọ́, torí pé àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí ò pọ̀, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé àádọ́ta (950) péré ní wọ́n lè pé sílé ẹ̀kọ́ náà.

 Ilé gbígbé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́. Nígbà táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá lọ sílé ẹ̀kọ́ láwọn Ilé Ìpàdé àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àwọn ará tó wà lágbègbè náà ló máa ń gbà wọ́n sílé. Èyí sì máa ń rọrùn láwọn ilẹ̀ tó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba kíláàsì ni wọ́n máa ń ṣè lọ́dọọdún. Àmọ́ láwọn ibi tá a ti ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí léraléra, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn ará tó máa gbà wọ́n sílé. Ìdí nìyẹn tá a fi dìídì kọ́ ilé tó máa ní kíláàsì àti ilé gbígbé, èyí sì máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti rí ibi dé sí.

 Tá a bá fẹ́ kọ́ ilé tó máa ní kíláàsì kan, àwọn yàrá tó máa gba nǹkan bí ọgbọ̀n àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àwọn olùkọ́ wọn àtàwọn míì tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sòótọ́ ó lè ná wa tó ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Èyí sì sinmi lé ibi tá a fẹ́ kọ́ ọ sí àtàwọn nǹkan míì.

Bí Ilé Ẹ̀kọ́ Náà Á Ṣe Rí

 A máa ń fẹ́ kọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí sáwọn ibi tó pa rọ́rọ́ tó sì rọrùn láti dé láwọn ìlú ńlá. A tún máa ń fẹ́ kí ilé ẹ̀kọ́ yìí wà níbi táwọn ará pọ̀ sí, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti bójú tó àyíká ilé náà àtàwọn ohun èlò tó wà nibẹ̀.

 Àwọn ilé yìí máa ń ní ilé ìkàwé, kọ̀ǹpútà, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àtàwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́ míì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ní ilé ìjẹun níbí tàwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ti lè jọ jẹun. Ó sì tún máa ń ní ibi tó fẹ̀ tó láti ṣeré ìmárale kí wọ́n sì sinmi.

 Ṣe la fara balẹ̀ ṣètò bí àwọn kíláàsì yẹn á ṣe rí. Arákùnrin Troy tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé ní Warwick, New York sọ pé: “A kàn sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run kí wọ́n lè bá wa ṣètò àwọn kíláàsì náà lọ́nà tó máa tu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lára bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n wá ṣàlàyé bí àwọn kíláàsì náà á ṣe tóbi tó, àti bó ṣe máa rí títí kan irú iná mọ̀nàmọ́ná tó máa wà níbẹ̀ àtàwọn ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn àti àwòrán jáde.” Arákùnrin Zoltán tó jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere lórílẹ̀-èdè Hungary sọ pé: Tẹ́ lẹ̀, nígbà tá ò ní makirofóònù, ṣe la máa ń rọ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ pé kí wọ́n gbóhùn sókè. Àmọ́ ní báyìí tá à ti ní makirofóònù, ṣe la máa ń gbọ́ ara wa ketekete!”

“Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ló Gbà Wá Lálejò”

 Àǹfààní wo láwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn olùkọ́ wọn ti rí, bá a ṣe mú kí àwọn ilé tá à ń lò fún ilé ẹ̀kọ́ yìí dáa sí i? Arábìnrin Angela tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere ní Palm Coast, Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àyíká ilé ẹ̀kọ́ náà tura. Bákan náà bí kíláàsì wa àtàwọn yàrá wa ṣe wà létòletò ń jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń kọ́.” Arákùnrin Csaba tó jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere lórílẹ̀-èdè Hungary mọyì àǹfààní tó ní láti máa jẹun pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Torí náà ó sọ pé: “Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà máa ń sọ ìrírí wọn fún wa lásìkò tá a bá ń jẹun, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa. Èyí sì máa ń jẹ́ ká lè fi ohun tá à ń kọ́ wọn bá ipò wọn mu.”

 Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ ‘Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá’ làwọn ilé tá a tún ṣe yìí jẹ́ fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn olùkọ́ wọn. (Àìsáyà 30:20, 21) Lórílẹ̀-èdè Philippines a tún ilé kan ṣe, a sì sọ ọ di ibi tá a ti máa ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere. Arábìnrin kan tó lọ sílé ẹ̀kọ́ níbẹ̀ sọ pé: “Bí àyíká ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe rí jẹ́ ká rí i pé, kì í ṣe pé a kàn jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àmọ́ ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ gbà wá lálejò. Ó fẹ́ ká gbádùn ara wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ fínnífínní.”

 Owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹyìn ló jẹ́ ká lè kọ́ àwọn ilé yìí, ká ṣàtúnṣe sáwọn kan ká sì bójú tó wọ́n. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìtìlẹyìn yìí ló jẹ́ pé orí ìkànnì donate.mr1310.com lẹ ti fi ń ránṣẹ́. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.

Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere ní Palm Coast, Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Àwòrán tẹ́ńpìlì nígbà ayé Jésù wà níbi ìgbàlejò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere ní Palm Coast, Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Àwọn ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere ní Brazil

Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wà ní kíláàsì ní Brazil

Àwọn ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere ní Philippines

Wọ́n ń gbádùn oúnjẹ ọ̀sán pa pọ̀ ní yàrá ìjẹun ní Philippines