BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
Àwọn Orin Tó Ń Jẹ́ Ká Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
NOVEMBER 1, 2021
Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni orin jẹ́, torí pé ó máa ń mára tù wá ó sì máa ń gbé wa ró tá a bá kárí sọ. Bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú àwọn orin wa náà nìyẹn. Yàtọ̀ sí pé àwọn orin yìí máa ń mára tù wá, ó tún lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Látọdún 2014, àwọn orin wa tó ń jáde nínú ètò oṣooṣù ti lé ní àádọ́rin (70), ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn orin yìí sì ti wà ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lọ! Àmọ́ o lè ti máa ronú pé, ‘Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn orin yìí, báwo sì ni wọ́n ṣe ń gbé e jáde?’
Bá A Ṣe Ń Ṣe Àwọn Orin Wa
Ẹgbẹ́ akọrin tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Gbohùn Sílẹ̀ ló ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn orin wa, wọn sì máa ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin mẹ́tàlá (13) tó wà nínú ẹgbẹ́ akọrin yìí ló máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà, wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ pò ó pọ̀, wọ́n á ṣètò ìgbà tí wọ́n máa kọ ọ́ àtàwọn iṣẹ́ míì tó pọn dandan. Yàtọ̀ síyẹn, Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tún fọwọ́ sí i pé káwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ń ṣiṣẹ́ látilé tó wà kárí ayé máa ṣèrànwọ́, àwọn kan nínú wọn máa ń kọ ọ̀rọ̀ orin àwọn míì sì jẹ́ akọrin. Tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí fi ń lo ẹ̀bùn wọn lẹ́nu iṣẹ́ yìí, wọn kì í sì í wá bí wọ́n á ṣe gbayì.
Àwọn nǹkan wo la máa ń ṣe tá a bá fẹ́ ṣe orin kan? Lákọ̀ọ́kọ́, Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ máa pinnu ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n fẹ́ kí orin náà dá lé àti ìmọ̀lára tí wọ́n fẹ́ káwọn tó bá gbọ́ ọ ní. Ẹgbẹ́ akọrin náà á wá yan àwọn tó máa kọ ọ̀rọ̀ orin náà àtàwọn tó máa ṣiṣẹ́ lórí ìlù táá bá orin náà mu. Lẹ́yìn tí wọ́n bá kọ orin náà, Ìgbìmọ̀ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ á yẹ̀ ẹ́ wò, wọ́n á sì fún wọn láwọn àbá lórí ibi tí wọ́n ti lè ṣàtúnṣe. Ẹgbẹ́ akọrin á wá ṣiṣẹ́ lórí àwọn àbá náà, wọ́n á sì tún orin náà kọ. Wọ́n lè kọ àwọn orin yìí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tàbí nílé àwọn ará tó ní ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀.
Onírúurú ètò ìṣiṣẹ́ orí kọ̀ǹpútà làwọn ará wa máa ń lò láti kọ ọ̀rọ̀ orin àti láti gba ohùn orin náà sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń lo àwọn nǹkan bíi gìtá àtàwọn ẹ̀rọ míì títí kan èyí tó ń gbohùn sílẹ̀ àtèyí tó ń gbóhùn jáde. Àwọn ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ yìí máa ń ná wa ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan (100) owó dọ́là sí ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1000) owó dọ́là. Lọ́dún 2020 nìkan, a ná 116,000 owó dọ́là lórí àwọn ẹ̀rọ tá a fi ń kọrin.
Àwọn nǹkan wo là ń ṣe ká lè ṣọ́ owó ná? Dípò táa fi máa ní ẹgbẹ́ akọrin ńlá kan ní Bẹ́tẹ́lì, a máa ń lo ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn látilé. Bákan náà, dípò tá a fi máa kó ọ̀pọ̀ èèyàn jọ láti kọ ọ̀rọ̀ orin àti láti gbohùn orin náà sílẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà ṣe làwọn ará wa máa ń lo onírúurú ètò ìṣiṣẹ́ orí kọ̀ǹpútà láti fi dárà sí orin náà.
‘Wọ́n Ń Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Mi Túbọ̀ Lágbára’
Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń gbádùn àwọn orin tó ń jáde nínú ètò oṣooṣù. Tara tó ń gbé ní Jámánì sọ pé: “Tí àníyàn bá gbà mí lọ́kàn, àwọn orin yẹn máa ń tù mí lára. Tí n bá ń gbọ́ wọn ní èdè ìbílẹ̀ mi, ṣe ló máa ń dà bí ìgbà tí Jèhófà gbá mi mọ́ra.” Arákùnrin Dmitry tó ń gbé ní Kazakhstan náà sọ pé: “Tí mo bá ń gbọ́ àwọn orin yìí, ọkàn mi máa ń balẹ̀ torí mo mọ̀ pé kò sí àwọn ọ̀rọ̀kọrọ̀ àti àṣàkaṣà táyé ń gbé lárugẹ nínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orin yẹn máa ń jẹ́ kí n pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí.”
Delia tó ń gbé ní South Africa sọ bí àwọn orin náà ṣe rí lára òun, ó ní: “Wọ́n ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára. Tí inú mi ò bá dùn tàbí tí mò ń kojú ìṣòro kan, mo máa ń rí orin tó máa bá ipò mi mu gẹ́lẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohùn orin yẹn nìkan ti tó láti mára tù mí!”
Àwọn orin ètò oṣooṣù yìí ti di ààyò fáwọn kan. Lerato tóun náà ń gbé ní South Africa sọ pé: “Àwọn orin náà ‘Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán’ àti ‘Ayé Tuntun’ máa ń jẹ́ kí n fojú sọ́nà sígbà tí màá kí ìyá mi ọ̀wọ́n tó ti kú káàbọ̀ pa dà. Ìgbàkigbà tí mo bá ń gbọ́ àwọn orin yẹn, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé mò ń rí ìyá mi tó ń bọ̀ láti wá gbá mi mọ́ra.”
Ọ̀kan lára àwọn orin ètò oṣooṣù wa ṣe ọ̀dọ́bìnrin kan ní Sri Lanka láǹfààní gan-an. Ó sọ pé: “Olùkọ́ mi sọ̀rọ̀ burúkú sí mi níṣojú gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì mi, torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ẹ̀rù bà mí gan-an, mi ò sì mọ ohun tí mo lè sọ. Nígbà tí mo délé, màámi gbà mí níyànjú pé kí n lọ gbọ́ orin náà ‘Ìkẹ́kọ̀ọ́ Dára.’ Orin yẹn jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n ṣèwádìí kí n sì múra ohun tí màá sọ sílẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, mo ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ fún olùkọ́ mi. Wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, wọ́n sì sọ fún mi pé, àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ lóye ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ni. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ètò Ọlọ́run fáwọn orin tó ń gbéni ró yìí.”
Ibo la ti ń rí owó tá a fi ń ṣe àwọn orin yìí? Ìtìlẹyìn táwọn ará wa ń ṣe kárí ayé ló ń jẹ́ ká rí owó yìí. Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ ló jẹ́ pé orí ìkànnì donate.mr1310.com ní wọ́n ti fi ránṣẹ́. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yìn.