A Nílò Ìgbàgbọ́
Wà á jáde:
1. Ìrònú gbọkàn mi, ó máyé sú mi.
Mo gbádùn ọ̀rọ̀ yín, mo fẹ́ gbọ́ sí i;
Ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ sọ, mo fẹ́ gbọ́ sí i.
Ọ̀pọ̀ ìbéèrè mi lẹ dáhùn lọ́jọ́ yẹn.
Ìrònú tó gbọkàn mi tẹ́lẹ̀ pòórá;
Gbogbo ‘dààmú mi ti fò lọ.
(ÈGBÈ)
Bá a tiẹ̀ lọ́pọ̀ ìdíwọ́,
A nílò ìgbàgbọ́.
Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,
A nílò ìgbàgbọ́;
Ká nígbàgbọ́.
2. Mo fẹ́ láti wàásù ohun tí mo kọ́.
Mo ṣe tán, iṣẹ́ yá. Ó yá, ká lọ.
Mo ti ṣe tán
Láti lọ wàásù.
Ìgbàgbọ́ mi dà bí iná tó ń jó lọ́kàn.
Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa jó, kó má ṣe kú;
Kó lè máa jó ní ọkàn mi.
(ÈGBÈ)
Bá a tiẹ̀ lọ́pọ̀ ìdíwọ́,
Àmọ́ mo rántí pé:
Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,
A nílò ìgbàgbọ́;
Ká nígbàgbọ́.
(ÀSOPỌ̀)
Ó máa ń súni tá a bá kojú ìṣòro.
Ṣáà máa gbàdúrà sí Jáà kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Ó ní, “Tó o bá lè gbẹ́kẹ̀ lé mi,
Màá fún ẹ lókun, wàá sì rí i
Pé tíṣòro bá dé,
Màá dúró tì ẹ́.”
(ÈGBÈ)
Bá a tiẹ̀ lọ́pọ̀ ìdíwọ́,
Àmọ́ mo rántí pé:
Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,
A nílò ìgbàgbọ́.
(ÈGBÈ)
Ó ti wá dá mi lójú,
A nílò ìgbàgbọ́.
Báwọn ‘ṣòro wa tilẹ̀ pọ̀,
A nílò ìgbàgbọ́;
Ká nígbàgbọ́.