Ìdílé Kan Ni Wá
Wà á jáde:
1. Ọkọ̀ òfúúrufú balẹ̀
Lẹ́yìn ìrìn àjò tó jìn
A filé sílẹ̀,
A ń rí ọwọ́ Jèhófà
Lẹ́nu iṣẹ́ yìí
Lóòótọ́, iṣẹ́ náà kò rọrùn rárá,
Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn.
Ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ara wa pọ̀ gan-an,
Torí náà à ń sọ pé:
(ÈGBÈ)
Ọmọ Jèhófà ni wá
À ń fayọ̀ sìn ní ìṣọ̀kan.
Bí ìlú wa tilẹ̀ jìnnà,
Ìdílé
Kan ni gbogbo wa.
2. Ẹ ti ń dúró dè wá kí ẹ
Lè fi ìfẹ́ kí wa káàbọ̀.
Ohùn orin ń dún, ìpàdé bẹ̀rẹ̀,
Ṣe ninú wa ń dùn ṣìnkìn.
A mọ̀ pé Jèhófà Baba wa ni
Ó mú kí èyí ṣeé ṣe.
Torí náà, a fọpẹ́ a fìyìn fún Jèhófà
Jọ̀ọ́ tẹ́wọ́ gbọpẹ́ wa.
(ÈGBÈ)
Ọmọ Jèhófà ni wá
À ń fayọ̀ sìn ní ìṣọ̀kan.
Bí ìlú wa tilẹ̀ jìnnà,
Ìdílé
Kan ni gbogbo wa.
3. Ọkọ̀ òfuurufú gbéra
A lọ síbi tá a kò dé rí.
À wàásù fún àwọn tó wà níbẹ̀
Wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ sí wa.
Àwọn ará fìfẹ́ tọ́jú wa gan-an
Wọ́n jẹ́ kí ara tù wá.
Ibi yòówù ká wà, bó ti wù kó jìn tó,
Ìfẹ́ wa jinlẹ̀ gan-an!
(ÀSOPỌ̀)
Ó yẹ ká mọ̀
Páwọn ọmọ ìyá wa wà káàkiri,
Ní Mali sí Mẹ́síkò,
Ní Japan sí Jàmáíkà.
(ÈGBÈ)
Ọmọ Jèhófà ni wá
À ń fayọ̀ sìn ní ìṣọ̀kan.
Bí ìlú wa tilẹ̀ jìnnà,
Ìdílé
Kan ni gbogbo wa.
Ní gbogbo orílẹ̀-èdè,
A mọ̀ pé ìdílé ni wa.
Ìfẹ́ wa hàn sí aráyé
Torí Jèhófà ló so wá pọ̀!
Kóńgò, Màláwì àti Amẹ́ríkà
Nàìjíríà, Kánádà, Káńbodíà
Dòmíníkà, Estonia àti Kúbà
Ìdílé kan ni gbogbo wa.