Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀
Wà á jáde:
1. Nínú ayé yìí;
Ìfẹ́ ṣọ̀wọ́n púpọ̀,
Àmọ́ ìfẹ́ tiwa jinlẹ̀!
Àwọn olóòótọ́
Èèyàn ló yí wa ká,
A kì í fara wé ayé yìí.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ìfẹ́ kò ní yẹ̀ rárá.
Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé!
Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni
Ìfẹ́ ti ń wá.
Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé
Ó ń mú káyé wa dùn.
Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀,
Kó má ṣe yẹ̀ rárá.
Ìfẹ́ kì í yẹ̀.
2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé
Ìṣòro pọ̀ láyé
Ó sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì,
A máa láyọ̀ gan-an
Tí a bá ń ṣe oore
Tá a sì ń tu àwọn míì nínú.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ìfẹ́ kò ní yẹ̀ rárá.
Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé!
Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni
Ìfẹ́ ti ń wá.
Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé
Ó ń mú káyé wa dùn.
Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀,
Kó má ṣe yẹ̀ rárá.
(ÈGBÈ)
Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé!
Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni
Ìfẹ́ ti ń wá.
Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé
Ó ń mú káyé wa dùn.
Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀,
Kó má ṣe yẹ̀ rá-rá.
Ìfẹ́ kì í yẹ̀,
Ìfẹ́ kì í yẹ̀,
Ìfẹ́ kì í yẹ̀.