ORIN 50
Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi
-
1. Màá sìn ọ́ tọkàntọkàn.
Fún mi lọ́gbọ́n àtòye.
Màá fi ohùn mi yìn ọ́;
Màá fi kọrin ìyìn rẹ.
-
2. Gba ọwọ́ àtẹsẹ̀ mi;
Kí wọ́n máa pàṣẹ rẹ mọ́.
Gba gbogbo ìṣúra mi;
Mo fún ọ pátápátá.
-
3. Mo fi ayé mi fún ọ.
Màá ṣohun tó o bá ti fẹ́.
Jẹ́ kí n máa múnú rẹ dùn
Jálẹ̀ ọjọ́ ayé mi.
(Tún wo Sm. 40:8; Jòh. 8:29; 2 Kọ́r. 10:5.)