ORIN 78
‘Máa Kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’
-
1. Àǹfààní ńlá la ní láti
Kọ́ni lọ́r’Ọlọ́run.
Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí,
Ó máa ń dùn mọ́ni gan-an.
Bí a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn
Lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀r’Ọlọ́run,
À ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa
Sún mọ́ Ọlọ́run wa.
-
2. Àwa náà gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa;
Ká sì jẹ́ kó máa hàn nínú
Ìgbésí ayé wa,
Káwọn ẹlòmíràn lè rí
Ìwà rere wa yìí.
Bí a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn yìí
Là ń kọ́ ara wa náà.
-
3. Jèhófà ti pèsè àwọn
Ohun tá a máa nílò.
Àdúrà ń kópa pàtàkì
Ká lè ṣàṣeyọrí.
A mọ̀ dájú pé Jèhófà
Máa gbọ́ àdúrà wa.
Láìpẹ́, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà
Máa lè kọ́ àwọn mí ì!
(Tún wo Sm. 119:97; 2 Tím. 4:2; Títù 2:7; 1 Jòh. 5:14.)