Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orin 142

À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn

À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn

Wà á jáde:

(1 Tímótì 2:4)

  1. A fẹ́ máa fara wé Ọlọ́run wa,

    Ká jẹ́ ẹni tí kì í ṣojúsàájú.

    Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn rí’gbàlà;

    Gbogbo onírúurú èèyàn ló ń pè.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà;

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

    Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn,

    À ń wàásù níbi gbogbo:

    “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”

  2. Ibi yòówù kí a ti pàdé wọn

    Tàbí irú ẹni tí wọ́n lè jẹ́.

    Ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú ni Jáà rí—

    Ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù sí i.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà;

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

    Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn,

    À ń wàásù níbi gbogbo:

    “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”

  3. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó pinnu

    Láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé.

    A mọ èyí, a sì fẹ́ káyé mọ̀,

    Torí náà à ń wàásù fáwọn èèyàn.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà;

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

    Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn,

    À ń wàásù níbi gbogbo:

    “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”